A2
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Tí A Tún Ṣe Yìí
Ọdún 1950 ni Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tó fi máa di 1961, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi. Látìgbà yẹn, àìmọye èèyàn ló ti jàǹfààní rẹ̀ lédè tó lé ní igba ó lé mẹ́wàá (210), torí pé ìtumọ̀ rẹ̀ péye, ó sì dùn-ún kà.
Àmọ́, nígbà tó fi máa di àádọ́ta (50) ọdún lẹ́yìn náà, èdè ti yí pa dà. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun ní báyìí rí i pé ó yẹ kí àwọn ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè wọ àwọn tó ń kàwé lóde òní lọ́kàn. Torí náà, àtúnṣe ti dé bá ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, ìdí tí wọ́n sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ rèé:
-
Ọ̀rọ̀ òde òní tó rọrùn lóye. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè ṣi ọ̀rọ̀ náà “ìpamọ́ra” lóye, ó lè mú kó dà bíi pé “ẹni tó ti ń jìyà tipẹ́tipẹ́” ló túmọ̀ sí. Àmọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ni pé kí èèyàn pinnu láti fara da ipò kan, torí náà, ó máa dáa ká sọ pé “sùúrù.” (Gálátíà 5:22) Àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ lo ọ̀rọ̀ náà “odi” mọ́, torí náà a ti fi ẹni “tí kò lè sọ̀rọ̀” rọ́pò rẹ̀. (Mátíù 9:32, 33) A tún ti fi ọ̀rọ̀ náà “aṣẹ́wó” rọ́pò “kárùwà.” (Jẹ́nẹ́sísì 34:31) Nínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí, “ìṣekúṣe” la fi rọ́pò “àgbèrè” lọ́pọ̀ ibi tó wà tẹ́lẹ̀; “ìwà àìnítìjú” sì rọ́pò “ìwà àìníjàánu.” (Gálátíà 5:19-21) A tún ti fi àwọn ọ̀rọ̀ míì rọ́pò “àkókò tí ó lọ kánrin,” àwọn ọ̀rọ̀ bíi “títí láé,” “títí lọ,” “ayérayé” tàbí ‘tipẹ́tipẹ́,’ èyí tó bá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ mu la lò.—Jẹ́nẹ́sísì 3:22; Ẹ́kísódù 31:16; Sáàmù 90:2; Oníwàásù 1:4; Míkà 5:2.
Ọ̀rọ̀ náà “èso” nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì àtijọ́ lè túmọ̀ sí kóró èso, ọmọ téèyàn bí tàbí àtọmọdọ́mọ, ó sì lè túmọ̀ sí àtọ̀. Torí pé lédè Yorùbá, a kì í sábà lo ọ̀rọ̀ náà “èso” tí a bá ń tọ́ka sí èèyàn, a ti fi ọ̀rọ̀ míì tó bá ohun tí wọ́n ń sọ mu rọ́pò rẹ̀ láwọn ibi tó ti fara hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:11; 22:17; 48:4; Mátíù 22:24; Jòhánù 8:37) Ní báyìí, “ọmọ” la lò ní ọ̀pọ̀ ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ọgbà Édẹ́nì, èyí tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
-
Àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí a mú kó ṣe kedere. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti tẹ́lẹ̀ lédè Yorùbá tó jẹ́ pé tí wọn ò bá ṣàlàyé rẹ̀, kò lè yé èèyàn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù” àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “Hédíìsì” láti tọ́ka sí ibojì aráyé. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kò mọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, yàtọ̀ síyẹn, nínú ìtàn àròsọ àwọn Gíríìkì, “Hédíìsì” ní ìtumọ̀ míì tó yàtọ̀. Torí náà, a ti fi “Isà Òkú” rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì, torí ohun tí àwọn tó kọ Bíbélì ní lọ́kàn nìyẹn. Inú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ni “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” wà báyìí.—
Nínú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà psy·kheʹ la túmọ̀ sí “ọkàn” ní gbogbo ibi tó ti fara hàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣi ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lóye, torí náà, bí a ṣe fi ọ̀rọ̀ kan túmọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí àwọn tó ń ka Bíbélì mọ ohun tí àwọn tó kọ ọ́ lábẹ́ ìmísí ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ yẹn. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ló máa jẹ́ ká mọ̀, torí ó lè túmọ̀ sí (1) èèyàn kan, (2) ẹ̀mí ẹnì kan, (3) ohun tó lẹ́mìí, (4) ohun tó wu ẹnì kan tàbí ohun tó fẹ́, láwọn ìgbà míì, ó lè túmọ̀ sí (5) ẹni tó ti kú. Àmọ́ torí pé “ọkàn” kì í sábà túmọ̀ sí àwọn ohun tí a mẹ́nu bà yìí lédè Yorùbá, a pinnu pé ńṣe la máa túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó máa gbé ìtúmọ̀ tó yẹ gan-an jáde, àá sì fi “Tàbí ‘ọkàn’” sínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. (Wo àpẹẹrẹ nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:20; 2:7; Léfítíkù 19:28; Sáàmù 3:2; Òwe 16:26; Mátíù 6:25.) Àmọ́ o, láwọn ibi tí Bíbélì ti lò ó nínú ewì tàbí láwọn ibi tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” ṣì wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé sì wà níbẹ̀ tó tọ́ka sí Àlàyé Ọ̀rọ̀ tàbí tó sọ ọ̀rọ̀ míì tí a lè fi rọ́pò rẹ̀.—Diutarónómì 6:5; Sáàmù 131:2; Òwe 2:10; Mátíù 22:37.
Lọ́nà kan náà, a ò yí ọ̀rọ̀ náà “kíndìnrín” pa dà láwọn ibi tó ti jẹ́ pé ẹ̀yà ara ló ń tọ́ka sí. Àmọ́, nígbà tí Bíbélì bá lò ó lọ́nà àpèjúwe, bí àpẹẹrẹ ní Sáàmù 7:9; 26:2 àti Ìfihàn 2:23, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà gan-an ni “inú lọ́hùn-ún” tàbí “èrò inú,” ohun tó sì wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn nìyẹn, a wá fi ìtumọ̀ rẹ̀ ní tààràtà sínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ọkàn” lédè Yorùbá ní ìtumọ̀ tààràtà, ó sì tún lè dúró fún nǹkan míì, torí náà, òun la lò jù nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ti fara hàn. Àmọ́ láwọn ibi mélòó kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere, a lo ọ̀rọ̀ míì tó jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Òwe, ẹni “tí ọkàn-àyà kù fún” ti di ẹni “tí kò ní làákàyè,” àmọ́ ìtumọ̀ rẹ̀ Òwe 6:32; 7:7) Ohun kan náà la ṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “lọ́ràá,” “ẹran ara” àti “ìwo,” ohun tó bá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ mu la lò. (Jẹ́nẹ́sísì 45:18; Oníwàásù 5:6; Jóòbù 16:15) Àlàyé lórí àwọn kan lára àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú “Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.”
ní tààràtà wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé. ( -
Ó túbọ̀ dùn-ún kà. Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti tẹ́lẹ̀ lédè Yorùbá, a fi àwọn ọ̀rọ̀ kan ti ọ̀rọ̀ míì lẹ́yìn láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù kan ń tọ́ka sí ohun tá à ń ṣe lọ́wọ́ tàbí ohun tí a ti ṣe parí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ bíi “bẹ̀rẹ̀ sí,” “ń bá a lọ,” ‘sì wá’ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ la fi máa ń gbe àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe láti fi hàn pé ohun kan ti bẹ̀rẹ̀ àmọ́ kò tíì parí. A máa ń fi ọ̀rọ̀ bíi “dájúdájú,” “gbọ́dọ̀,” “ní ti tòótọ́,” àtàwọn ọ̀rọ̀ míì túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù tó ní ìtẹnumọ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà la lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nínú Bíbélì tuntun yìí, láwọn ibi tó ti yẹ ká fi hàn pé ohun kan ṣì ń lọ lọ́wọ́, a ò yí àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ń,” “máa” àti “sábà máa ń” tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:9; 34:1; Òwe 2:4) Síbẹ̀, láwọn ibi tí kò ti pọn dandan, tí kò sì ní yí ìtumọ̀ pa dà, a ti yọ ọ́ kúrò kí àwọn ọ̀rọ̀ ibẹ̀ lè túbọ̀ dùn-ún kà.
-
Bí a ṣe túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ akọ tàbí abo. Nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì, ọ̀rọ̀ orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń lò fún ọkùnrin àti obìnrin, àmọ́ èdè Gíríìkì tún ní ọ̀rọ̀ tó lè lọ fún àwọn méjèèjì. Láwọn ìgbà míì, tí a bá lo ọ̀rọ̀ tó fi hàn bóyá akọ tàbí abo ni ibì kan ń sọ, bó ṣe wà nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ìyẹn lè má jẹ́ kéèyàn lóye ohun tó túmọ̀ sí gan-an. Nínú èdè Hébérù àti Gíríìkì, àwọn ọ̀rọ̀ orúkọ ẹlẹ́ni púpọ̀ máa ń jẹ́ akọ, ì báà jẹ́ akọ àti abo ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì” lè tọ́ka sí àwọn ọmọkùnrin méjìlá (12) tí Jékọ́bù bí, lọ́pọ̀ ìgbà, gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló máa ń tọ́ka sí lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 46:5; Ẹ́kísódù 35:29) Torí náà, nínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí, “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì” la lò láwọn ibi tó ti ń tọ́ka sí gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Lọ́nà kan náà, ọ̀rọ̀ náà “ọmọdékùnrin aláìníbaba” ti di “ọmọ aláìníbaba” tàbí “aláìlóbìí” torí pé ọmọ náà lè jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Àmọ́, torí pé Bíbélì lo ọ̀rọ̀ orúkọ tó ń tọ́ka sí ọkùnrin nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, títí kan àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ẹ̀mí èṣù, kò sídìí tí a fi ní láti lo ọ̀rọ̀ tó lè túmọ̀ sí akọ tàbí abo fún wọn bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní kan ṣe lò ó.
A gbàdúrà gan-an, a sì fara balẹ̀ nígbà tá à ń ṣe àtúnṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀, a tún mọyì iṣẹ́ ribiribi tí ìgbìmọ̀ tó kọ́kọ́ túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun ṣe.
Àwọn nǹkan míì tó wà nínú Bíbélì yìí:
Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà nínú Bíbélì yìí mọ níwọ̀n. Àwọn apá tí àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé náà pín sí rèé:
-
“Tàbí” Ọ̀rọ̀ míì tí a lè fi tú ọ̀rọ̀ kan láti èdè Hébérù, Árámáíkì tàbí Gíríìkì, tí ìtúmọ̀ rẹ̀ ò sì ní yàtọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lórí “ẹ̀mí Ọlọ́run”; Jóṣúà 1:8, “fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á.”
-
“Tàbí kó jẹ́” Ọ̀rọ̀ míì tí a lè fi tú ọ̀rọ̀ kan, tó máa mú kí ìtúmọ̀ rẹ̀ yàtọ̀, àmọ́ tí á ṣì jẹ́ òótọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 21:6, “bá mi rẹ́rìn-ín”; Sekaráyà 14:21, “ọmọ Kénáánì.”
-
“Ní Héb.”, “Ní Grk.” àti “Ní Árámáíkì” Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan bó ṣe rí lédè Hébérù, Árámáíkì tàbí Gíríìkì tàbí ìtumọ̀ gbólóhùn kan ní tààràtà látinú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì.—Jẹ́nẹ́sísì 30:22, “lóyún”; Ẹ́kísódù 32:9, “alágídí.”
-
Ìtumọ̀ àti àlàyé síwájú sí i Ìtúmọ̀ àwọn orúkọ (Jẹ́nẹ́sísì 3:17, “Ádámù”; Ẹ́kísódù 15:23, “Márà”); àlàyé nípa òṣùwọ̀n àti ìdíwọ̀n (Jẹ́nẹ́sísì 6:15, “ìgbọ̀nwọ́”); ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ dúró fún (Jẹ́nẹ́sísì 38:5, “ó”); àwọn àlàyé tó wúlò tó wà nínú Àfikún àti Àlàyé Ọ̀rọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 37:35, “Isà Òkú”; Mátíù 5:22, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Àwọn ohun tí Bíbélì kọ́ni ló wà ní ọwọ́ iwájú, àkòrí rẹ̀ ni “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Àwọn ohun tó tẹ̀ lé ìwé tó parí Bíbélì ni, “Àtẹ Àwọn Ìwé inú Bíbélì,” “Atọ́ka Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì” àti “Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.” Àlàyé Ọ̀rọ̀ máa jẹ́ kí ẹni tó ń ka Bíbélì lóye bí wọ́n ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì. Àwọn ohun tó wà nínú Àfikún A nìyí: “Ìlànà Tó Wà fún Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Bíbélì,” “ Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Tí A Tún Ṣe Yìí,” “Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́,” “Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù,” “Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì,” “Àtẹ: Àwọn Wòlíì àti Àwọn Ọba Ilẹ̀ Júdà àti Ísírẹ́lì” àti “Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù.” Àwọn ohun tó wà nínú Àfikún B ni, àwòrán ilẹ̀, àtẹ àti àwọn ohun míì tó wúlò fún àwọn tó ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nínú Bíbélì yìí, ìwé kọ̀ọ̀kan ló níbi tí a kọ ohun tó wà nínú orí kọ̀ọ̀kan sí àti ẹsẹ tí wọ́n wà, èyí sì máa jẹ́ kí ẹni tó ń ka Bíbélì rí àwọn ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì náà. A tún kó lára àwọn atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù látinú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀ sínú atọ́ka tó wà láàárín ojú ìwé kọ̀ọ̀kan inú Bíbélì yìí.