Àìsáyà 48:1-22
48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+
2 Torí wọ́n ń fi ìlú mímọ́+ pe ara wọn,Wọ́n sì ń wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+Tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
3 “Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti sọ àwọn ohun àtijọ́* fún ọ.
Wọ́n ti ẹnu mi jáde,Mo sì jẹ́ kó di mímọ̀.+
Mo gbé ìgbésẹ̀ lójijì, wọ́n sì ṣẹlẹ̀.+
4 Torí mo mọ bí o ṣe lágídí tó,Pé irin ni iṣan ọrùn rẹ àti pé bàbà ni iwájú orí rẹ,+
5 Mo sọ fún ọ tipẹ́tipẹ́.
Kó tó ṣẹlẹ̀, mo mú kí o gbọ́ ọ,Kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ló ṣe èyí,Ère gbígbẹ́ mi àti ère onírin* mi ló pa á láṣẹ.’
6 Ẹ ti gbọ́, ẹ sì ti rí gbogbo èyí.
Ṣé ẹ ò ní kéde rẹ̀ ni?+
Láti ìsinsìnyí lọ, màá kéde àwọn ohun tuntun fún ọ,+Àwọn àṣírí tí mo pa mọ́, tí o kò mọ̀.
7 A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn ni, kì í ṣe látìgbà àtijọ́,Àwọn ohun tí o ò gbọ́ rí kó tó di òní,Kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.’
8 Rárá, o ò tíì gbọ́,+ o ò tíì mọ̀ ọ́n,Etí rẹ ò sì là nígbà àtijọ́.
Nítorí mo mọ̀ pé ọ̀dàlẹ̀ paraku ni ọ́,+A sì ti pè ọ́ ní ẹlẹ́ṣẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti bí ọ.+
9 Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,Mi ò sì ní pa ọ́ run.+
10 Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, àmọ́ kì í ṣe bíi ti fàdákà.+
Mo ti dán ọ wò* nínú iná ìléru ti ìyà, tí a fi ń yọ́ nǹkan.+
11 Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi, màá gbé ìgbésẹ̀,+Ṣé màá wá jẹ́ kí wọ́n kẹ́gàn mi ni?+
Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì.*
12 Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè,Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́; èmi náà ni ẹni ìkẹyìn.+
13 Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+Ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo sì fi na ọ̀run.+
Tí mo bá pè wọ́n, wọ́n jọ máa dìde.
14 Gbogbo yín, ẹ kóra jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀.
Ta ni nínú wọn ló kéde àwọn nǹkan yìí?
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+
Ó máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú sí Bábílónì,+Apá rẹ̀ sì máa kọ lu àwọn ará Kálídíà.+
15 Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pè é.+
Mo ti mú un wá, ọ̀nà rẹ̀ sì máa yọrí sí rere.+
16 Ẹ sún mọ́ mi, kí ẹ sì gbọ́ èyí.
Láti ìbẹ̀rẹ̀, mi ò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀.+
Látìgbà tó ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.”
Ní báyìí, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti rán mi àti* ẹ̀mí rẹ̀.
17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+
“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,*+Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+
18 Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+
Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+Òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+
19 Àwọn ọmọ* rẹ ì bá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ ì bá sì pọ̀ bí iyanrìn.+
A ò ní pa orúkọ wọn rẹ́ tàbí ká pa á run kúrò níwájú mi láé.”
20 Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!+Ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà!
Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+
Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+
Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+
21 Òùngbẹ ò gbẹ wọ́n nígbà tó mú wọn gba àwọn ibi tó ti pa run.+
Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta fún wọn;Ó la àpáta, ó sì mú kí omi rọ́ jáde.”+
22 Jèhófà sọ pé, “Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “ṣẹ̀ wá láti.”
^ Ní Héb., “àkọ́kọ́.”
^ Tàbí “ère dídà.”
^ Tàbí “yẹ̀ ọ́ wò.” Tàbí kó jẹ́, “yàn ọ́.”
^ Tàbí “Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi.”
^ Tàbí “pẹ̀lú.”
^ Tàbí “fún àǹfààní ara rẹ.”
^ Ní Héb., “èso.”