Ẹ́kísódù 12:1-51
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì ní ilẹ̀ Íjíbítì pé:
2 “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù fún yín. Òun ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín nínú ọdún.+
3 Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù yìí, kí kálukú wọn mú àgùntàn kan+ fún ilé bàbá wọn, àgùntàn kan fún ilé kan.
4 Àmọ́ tí àgùntàn kan bá ti pọ̀ jù fún agbo ilé náà, kí àwọn àti aládùúgbò wọn* tó múlé tì wọ́n jọ pín in nínú ilé wọn, kí wọ́n pín in sí iye èèyàn* tí wọ́n jẹ́. Kí ẹ ṣírò iye ẹran àgùntàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa jẹ.
5 Kí ara àgùntàn yín dá ṣáṣá,+ kó jẹ́ akọ, ọlọ́dún kan. Ẹ lè mú lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́.
6 Kí ẹ máa tọ́jú rẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí,+ kí gbogbo àpéjọ* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa á ní ìrọ̀lẹ́.*+
7 Kí wọ́n mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì wọ́n ọn sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ọ̀nà àwọn ilé tí wọ́n ti jẹ ẹ́.+
8 “‘Kí wọ́n jẹ ẹran náà lálẹ́ yìí.+ Kí wọ́n yan án lórí iná, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú+ àti ewébẹ̀ kíkorò.+
9 Ẹ má jẹ ẹ́ ní tútù tàbí ní bíbọ̀, ẹ má fi omi sè é, àmọ́ ẹ yan án lórí iná, ẹ yan orí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àwọn nǹkan inú rẹ̀.
10 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀, àmọ́ tí ìkankan lára rẹ̀ bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí ẹ fi iná sun ún.+
11 Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí, ẹ di àmùrè,* ẹ wọ bàtà, kí ẹ mú ọ̀pá yín dání; kí ẹ sì yára jẹ ẹ́. Ìrékọjá Jèhófà ni.
12 Torí màá lọ káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì lálẹ́ yìí, màá sì pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko;+ màá sì dá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì lẹ́jọ́.+ Èmi ni Jèhófà.
13 Ẹ̀jẹ̀ náà yóò jẹ́ àmì yín lára àwọn ilé tí ẹ wà; èmi yóò rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò sì ré yín kọjá, ìyọnu náà ò sì ní pa yín run nígbà tí mo bá kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+
14 “‘Kí ẹ máa rántí ọjọ́ yìí, kí ẹ sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀, kó jẹ́ àjọyọ̀ sí Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín. Ẹ máa pa àjọyọ̀ náà mọ́, ó ti di òfin fún yín títí láé.
15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ Lọ́jọ́ kìíní, kí ẹ mú àpòrọ́ kíkan kúrò ní ilé yín, kí ẹ pa ẹni* tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà* láti ọjọ́ kìíní títí dé ìkeje ní Ísírẹ́lì.
16 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣe àpéjọ mímọ́ míì ní ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ yìí.+ Ohun tí ẹnì* kọ̀ọ̀kan máa jẹ nìkan ni kí wọ́n sè.
17 “‘Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ torí ní ọjọ́ yìí gangan, èmi yóò mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ* yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ máa pa ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran yín, ó ti di òfin fún yín títí láé.
18 Kí ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú láti alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní títí di alẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún oṣù náà.+
19 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan nínú ilé yín rárá fún ọjọ́ méje, torí tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà, yálà àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀,+ kí ẹ pa* ẹni* yẹn kúrò nínú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
20 Ẹ má jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà. Búrẹ́dì aláìwú ni kí ẹ jẹ ní gbogbo ilé yín.’”
21 Mósè yára pe gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ mú àwọn ọmọ ẹran* fún ìdílé yín níkọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa ẹran tí ẹ máa fi rúbọ nígbà Ìrékọjá.
22 Kí ẹ wá ki ìdìpọ̀ ewéko hísópù bọnú ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú bàsíà, kí ẹ sì wọ́n ọn sí apá òkè ẹnu ọ̀nà àti sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn náà; kí ẹnì kankan nínú yín má sì jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ títí di àárọ̀.
23 Tí Jèhófà bá wá kọjá kó lè fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì rí ẹ̀jẹ̀ náà ní apá òkè ẹnu ọ̀nà àti lára òpó rẹ̀ méjèèjì, ó dájú pé Jèhófà yóò ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí ìyọnu ikú* wọnú ilé yín.+
24 “Kí ẹ máa pa àjọ̀dún yìí mọ́, ó ti di àṣẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín títí láé.+
25 Tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fún yín bó ṣe sọ, kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ yìí.+
26 Tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín pé, ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń ṣe àjọyọ̀ yìí?’+
27 kí ẹ sọ pé, ‘Ẹbọ Ìrékọjá sí Jèhófà ni, ẹni tó ré ilé àwa ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tó fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì dá ilé wa sí.’”
Àwọn èèyàn náà tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀.
28 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
29 Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹni tó wà lẹ́wọ̀n* àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.+
30 Fáráò dìde ní òru yẹn, òun àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará Íjíbítì yòókù, igbe ẹkún ńlá sì sọ láàárín àwọn ará Íjíbítì, torí kò sí ilé kankan tí èèyàn ò ti kú.+
31 Ló bá pe Mósè àti Áárónì+ ní òru, ó sì sọ pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.+
32 Kí ẹ kó àwọn agbo ẹran yín àti ọ̀wọ́ ẹran yín, kí ẹ sì lọ bí ẹ ṣe sọ.+ Àmọ́ kí ẹ súre fún mi.”
33 Àwọn ará Íjíbítì wá ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n tètè kúrò ní ilẹ̀ náà.+ Wọ́n sọ pé, “Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la máa kú!”+
34 Torí náà, àwọn èèyàn náà gbé àpòrọ́ ìyẹ̀fun wọn tí kò ní ìwúkàrà, wọ́n fi aṣọ wé ọpọ́n* tí wọ́n fi ń po nǹkan, wọ́n sì gbé e lé èjìká.
35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Mósè sọ fún wọn, wọ́n béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.+
36 Jèhófà mú kí àwọn èèyàn náà rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, wọ́n fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè, wọ́n sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.+
37 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Rámésésì,+ wọ́n sì forí lé Súkótù,+ wọ́n tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkùnrin tó ń fẹsẹ̀ rìn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé.+
38 Oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ*+ ló tún bá wọn lọ, pẹ̀lú àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn.
39 Wọ́n wá ń fi àpòrọ́ tí wọ́n mú kúrò ní Íjíbítì ṣe búrẹ́dì aláìwú tó rí ribiti. Kò ní ìwúkàrà, torí ṣe ni wọ́n lé wọn kúrò ní Íjíbítì lójijì débi pé wọn ò ráyè ṣètò oúnjẹ kankan fún ara wọn.+
40 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó gbé ní Íjíbítì,+ ti lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún.+
41 Ní ọjọ́ yìí tí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún pé ni gbogbo èèyàn Jèhófà tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
42 Òru yẹn ni wọ́n á ṣe àjọyọ̀ torí pé Jèhófà mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì máa pa òru ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran wọn láti bọlá fún Jèhófà.+
43 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé, “Àṣẹ tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nígbà Ìrékọjá nìyí: Àjèjì kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+
44 Àmọ́ tí ẹnì kan bá ní ẹrú tó jẹ́ ọkùnrin, tó fi owó rà, kí o dádọ̀dọ́ rẹ̀.*+ Ìgbà yẹn ló tó lè jẹ nínú rẹ̀.
45 Ẹni tó wá gbé láàárín yín àti alágbàṣe kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.
46 Inú ilé kan ni kí ẹ ti jẹ ẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ìkankan nínú ẹran náà kúrò nínú ilé lọ síta, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.+
47 Kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ayẹyẹ yìí.
48 Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín, tó sì fẹ́ ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá láti bọlá fún Jèhófà, kí gbogbo ọkùnrin ilé rẹ̀ dádọ̀dọ́.* Ìgbà yẹn ló lè ṣe ayẹyẹ náà, yóò sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀. Àmọ́ aláìdádọ̀dọ́* ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+
49 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ àti àjèjì tó ń gbé láàárín yín máa tẹ̀ lé.”+
50 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
51 Ọjọ́ yìí gan-an ni Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “òun àti aládùúgbò rẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “gbogbo ìjọ àpéjọ.”
^ Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
^ Ní Héb., “ẹ di ìbàdí yín lámùrè.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “kí ẹ ké ẹni tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà kúrò.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”
^ Tàbí “kí ẹ ké.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ìyẹn, ọmọ àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
^ Ní Héb., “ìparun.”
^ Ní Héb., “ní ilé kòtò omi.”
^ Tàbí “abọ́.”
^ Ìyẹn, oríṣiríṣi èèyàn tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn ará Íjíbítì.
^ Ní Héb., “gbogbo ọmọ ogun Jèhófà.”
^ Tàbí “kọ ọ́ nílà.”
^ Tàbí “kọlà.”
^ Tàbí “aláìkọlà.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”