Émọ́sì 7:1-17

  • Ìran tó fi hàn pé òpin Ísírẹ́lì ti sún mọ́lé (1-9)

    • Eéṣú (1-3), iná (4-6), okùn ìwọ̀n (7-9)

  • Wọ́n ní kí Émọ́sì má sọ tẹ́lẹ̀ mọ́ (10-17)

7  Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Ó kó ọ̀wọ́ eéṣú jọ ní ìgbà tí irúgbìn àgbìnkẹ́yìn* bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Èyí ni irúgbìn àgbìnkẹ́yìn lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ọba.  Nígbà tí àwọn eéṣú náà jẹ ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà tán, mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, dárí jì wọ́n!+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*  Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà wí.  Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ lo iná láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀. Iná náà lá alagbalúgbú omi gbẹ, ó sì jẹ apá kan ilẹ̀ náà run.  Mo sì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀.+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*  Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.  Ohun tó fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà dúró lórí ògiri kan tí wọ́n fi okùn ìwọ̀n mú tọ́ nígbà tí wọ́n kọ́ ọ, okùn ìwọ̀n kan sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.  Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Kí lo rí, Émọ́sì?” Torí náà, mo sọ pé: “Okùn ìwọ̀n.” Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó, màá fi okùn ìwọ̀n wọn àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Mi ò sì ní forí jì wọ́n mọ́.+  Àwọn ibi gíga Ísákì+ máa di ahoro, àwọn ibùjọsìn Ísírẹ́lì á sì pa run;+ màá fi idà kọ lu ilé Jèróbóámù.”+ 10  Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì+ ránṣẹ́ sí Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì pé: “Émọ́sì ń dìtẹ̀ sí ọ láàárín ilé Ísírẹ́lì.+ Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò lè rí ara gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 11  Nítorí ohun tí Émọ́sì sọ nìyí, ‘Idà ni yóò pa Jèróbóámù, ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.’”+ 12  Ìgbà náà ni Amasááyà sọ fún Émọ́sì pé: “Ìwọ aríran, máa lọ, sá lọ sí ilẹ̀ Júdà, ibẹ̀ ni kí o ti máa wá bí wàá ṣe jẹun,* ibẹ̀ sì ni o ti lè sọ tẹ́lẹ̀.+ 13  Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì mọ́,+ nítorí pé ibùjọsìn ọba ni,+ ilé ìjọba sì ni.” 14  Ìgbà náà ni Émọ́sì dá Amasááyà lóhùn pé: “Wòlíì kọ́ ni mí tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì; olùṣọ́ agbo ẹran ni mí,+ mo sì máa ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.* 15  Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé kí n má ṣe da agbo ẹran mọ́, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 16  Torí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: ‘Ìwọ ń sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Ísírẹ́lì,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kéde ìkìlọ̀+ fún ilé Ísákì.” 17  Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Aya rẹ máa di aṣẹ́wó ní ìlú yìí, idà ni yóò pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ. Okùn ìdíwọ̀n ni wọ́n á fi pín ilẹ̀ rẹ, orí ilẹ̀ àìmọ́ ni wàá sì kú sí; ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, ní oṣù January sí February.
Ní Héb., “dìde?”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Ní Héb., “dìde?”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”
Tàbí “ń rẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.”