Émọ́sì 8:1-14
8 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Apẹ̀rẹ̀ kan tí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà nínú rẹ̀.
2 Ó wá sọ pé, “Kí lo rí, Émọ́sì?” Mo fèsì pé, “Apẹ̀rẹ̀ tí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà nínú rẹ̀.” Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Òpin ti dé bá àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi kò ní forí jì wọ́n mọ́.+
3 ‘Àwọn orin tẹ́ńpìlì máa di igbe ẹkún ní ọjọ́ yẹn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Òkú á sì sùn lọ bẹẹrẹ níbi gbogbo.+ Dákẹ́!’
4 Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ni àwọn tálákà láraTí ẹ sì ń pa àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ilẹ̀ yìí,+
5 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ìgbà wo ni àjọ̀dún òṣùpá tuntun máa parí,+ ká lè ta àwọn hóró ọkà wa,Àti ìparí Sábáàtì,+ ká lè gbé hóró ọkà lọ fún títà?
Ká lè sọ òṣùwọ̀n eéfà* di kékeréKí a sì sọ ṣékélì* di ńlá,Kí a dọ́gbọ́n sí àwọn òṣùwọ̀n wa, kí a lè fi tanni jẹ;+
6 Kí a lè fi fàdákà ra àwọn aláìníKí a sì fi owó bàtà ẹsẹ̀ méjì ra àwọn tálákà,+Kí a sì lè ta èyí tí kò dáa lára ọkà.’
7 Jèhófà ti fi Ògo Jékọ́bù+ búra,‘Mi ò ní gbàgbé gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.+
8 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà* á mì tìtì,Gbogbo àwọn tó ń gbé orí rẹ̀ á sì ṣọ̀fọ̀.+
Ǹjẹ́ kò ní ru sókè bí odò Náílì,Kí ó sì bì síwá sẹ́yìn, kí ó wá rọlẹ̀ bí odò Náílì Íjíbítì?’+
9 ‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,‘Màá mú kí oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán gangan,Màá sì mú kí ilẹ̀ náà ṣókùnkùn ní ojúmọmọ.+
10 Màá sọ àwọn àjọyọ̀ yín di ọ̀fọ̀+Gbogbo orin yín á sì di orin arò.*
Màá sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ gbogbo ìbàdí, màá sì mú gbogbo orí pá;Màá ṣe é bí ìgbà téèyàn ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo,Màá sì mú kí ìgbẹ̀yìn rẹ̀ dà bí ọjọ́ tó korò.’
11 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,‘Nígbà tí màá rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,Kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí ti omi,Bí kò ṣe ti gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
12 Wọ́n á ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ láti òkun dé òkunLáti àríwá sí ìlà oòrùn.*
Wọ́n á máa wá ọ̀rọ̀ Jèhófà káàkiri, ṣùgbọ́n wọn ò ní rí i.
13 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn arẹwà wúńdíá máa dá kú,Àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá, nítorí òùngbẹ náà;
14 Àwọn tó ń fi ẹ̀ṣẹ̀ Samáríà+ búra, tí wọ́n sì ń sọ pé,“Bí ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dánì!”+
Àti “Bí ọ̀nà Bíá-ṣébà+ ti ń bẹ!”
Wọ́n á ṣubú, wọn ò sì ní dìde mọ́.’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àfikún B14.
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ayé.”
^ Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “yíyọ oòrùn.”