Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 8:1-13
8 Nígbà tó+ ṣí èdìdì keje,+ gbogbo ọ̀run pa rọ́rọ́ fún nǹkan bí ààbọ̀ wákàtí.
2 Mo sì rí àwọn áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run, a fún wọn ní kàkàkí méje.
3 Áńgẹ́lì míì dé, ó dúró níbi pẹpẹ,+ ó gbé àwo tùràrí tí wọ́n fi wúrà ṣe* dání, a sì fún un ní tùràrí tó pọ̀ gan-an+ pé kó sun ún lórí pẹpẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú ìtẹ́ náà bí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ṣe ń gbàdúrà.
4 Èéfín tùràrí látọwọ́ áńgẹ́lì náà àti àdúrà+ àwọn ẹni mímọ́ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run.
5 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì náà mú àwo tùràrí náà, ó kó díẹ̀ lára iná pẹpẹ sínú rẹ̀, ó sì jù ú sí ayé. Ààrá sán, a gbọ́ ohùn, mànàmáná kọ yẹ̀rì,+ ìmìtìtì ilẹ̀ sì wáyé.
6 Àwọn áńgẹ́lì méje tí kàkàkí méje wà lọ́wọ́ wọn+ sì múra láti fun wọ́n.
7 Áńgẹ́lì àkọ́kọ́ fun kàkàkí rẹ̀. Yìnyín àti iná dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀, a sì dà á sí ayé; + ìdá mẹ́ta ayé sì jóná àti ìdá mẹ́ta àwọn igi pẹ̀lú gbogbo ewéko tútù.+
8 Áńgẹ́lì kejì fun kàkàkí rẹ̀. A sì ju ohun kan tó rí bí òkè ńlá tí iná ń jó sínú òkun.+ Ìdá mẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀;+
9 ìdá mẹ́ta àwọn ohun alààyè* tó wà nínú òkun sì kú,+ ìdá mẹ́ta àwọn ọkọ̀ òkun sì fọ́ túútúú.
10 Áńgẹ́lì kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá tó ń jó bíi fìtílà já bọ́ láti ọ̀run, ó já bọ́ sórí ìdá mẹ́ta àwọn odò àti sórí àwọn ìsun omi.*+
11 Iwọ* ni orúkọ ìràwọ̀ náà. Ìdá mẹ́ta àwọn omi di iwọ, àwọn omi náà sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn, torí a ti mú kí wọ́n korò.+
12 Áńgẹ́lì kẹrin fun kàkàkí rẹ̀. A sì lu ìdá mẹ́ta oòrùn+ àti ìdá mẹ́ta òṣùpá àti ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, kí òkùnkùn lè bo ìdá mẹ́ta wọn,+ kí ìmọ́lẹ̀ má bàa wà ní ìdá mẹ́ta ọ̀sán àti òru pẹ̀lú.
13 Mo rí ẹyẹ idì kan tó ń fò lójú ọ̀run, mo sì gbọ́ tó ń ké jáde pé: “Ẹ gbé, ẹ gbé, ẹ gbé+ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní ayé nítorí ìró kàkàkí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta yòókù tí wọ́n máa tó fun kàkàkí wọn!”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ohun tí wọ́n fi ń sun tùràrí.”
^ Tàbí “àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí.”
^ Tàbí “àwọn orísun omi.”
^ Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.