Ìsíkíẹ́lì 13:1-23
13 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn wòlíì Ísírẹ́lì,+ kí o sì sọ fún àwọn tó ń hùmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tiwọn* pé,+ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.
3 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé, ẹ̀yin òmùgọ̀ wòlíì, tí ẹ̀ ń sọ èrò ọkàn yín, láìrí nǹkan kan!+
4 Ìwọ Ísírẹ́lì, àwọn wòlíì rẹ dà bíi kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàárín àwọn àwókù ilé.
5 Ẹ ò ní lọ sí àwọn ibi tó ti fọ́ lára àwọn ògiri olókùúta láti tún un kọ́ fún ilé Ísírẹ́lì,+ kí Ísírẹ́lì má bàa ṣubú lójú ogun ní ọjọ́ Jèhófà.”+
6 “Ìran èké ni wọ́n rí, àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni wọ́n sì sọ, àwọn tó ń sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni pé,’ tó sì jẹ́ pé Jèhófà ò rán wọn, wọ́n sì ti dúró kí ọ̀rọ̀ wọn lè ṣẹ.+
7 Ṣebí ìran èké lẹ rí, àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ lẹ sì sọ nígbà tí ẹ sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà ni pé,’ tó sì jẹ́ pé mi ò sọ nǹkan kan?”’
8 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “‘Torí ẹ ti parọ́ tí ẹ sì ń rí ìran èké, mo kẹ̀yìn sí yín,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”+
9 Àwọn wòlíì tó ń rí ìran èké àti àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ máa jìyà lọ́wọ́ mi.+ Wọn ò ní sí lára àwọn èèyàn tí mo fọkàn tán; orúkọ wọn ò ní sí nínú àkọsílẹ̀ orúkọ ilé Ísírẹ́lì; wọn ò ní pa dà sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+
10 Gbogbo èyí jẹ́ torí pé wọ́n ti ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà, bí wọ́n ṣe ń sọ pé, “Àlàáfíà wà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà.+ Tí wọ́n bá mọ ògiri tí kò lágbára, wọ́n á kùn ún ní ẹfun.’*+
11 “Sọ fún àwọn tó ń kun ògiri ní ẹfun pé, ó máa wó. Àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò yóò rọ̀, yìnyín* máa já bọ́, ìjì líle yóò sì wó o palẹ̀.+
12 Tí ògiri náà bá sì wó, wọ́n á bi yín pé, ‘Ẹfun tí ẹ fi kùn ún dà?’+
13 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Màá fi ìbínú mú kí ìjì líle jà, màá fi ìrunú rọ àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò, ìbínú tó le ni màá sì fi rọ yìnyín láti pa á run.
14 Èmi yóò wó ògiri tí ẹ kùn ní ẹfun, màá ya á lulẹ̀, ìpìlẹ̀ rẹ̀ á sì hàn síta. Tí ìlú náà bá pa run, ẹ máa kú sínú rẹ̀; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
15 “‘Tí mo bá ti bínú tán sí ògiri náà àti àwọn tó kùn ún ní ẹfun, èmi yóò sọ fún yín pé: “Ògiri náà kò sí mọ́, àwọn tó sì ń kùn ún ní ẹfun kò sí mọ́.+
16 Kò sí wòlíì mọ́ ní Ísírẹ́lì, àwọn tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n ń rí ìran àlàáfíà fún un, nígbà tí kò sí àlàáfíà,”’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
17 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ń hùmọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tiwọn, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.
18 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé ẹ̀yin obìnrin tó ń rán ìfúnpá fún gbogbo ọwọ́,* tí ẹ sì ń ṣe ìbòrí fún onírúurú orí kí ẹ lè dọdẹ ẹ̀mí* àwọn èèyàn! Ṣé ẹ̀mí* àwọn èèyàn mi ni ẹ̀ ń dọdẹ rẹ̀, tí ẹ wá ń dáàbò bo ẹ̀mí* tiyín?
19 Ṣé ẹ máa sọ mí di aláìmọ́ láàárín àwọn èèyàn mi torí ẹ̀kúnwọ́ ọkà bálì àti èérún búrẹ́dì?+ Ẹ̀ ń pa àwọn* tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn* tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn èèyàn mi, tí àwọn náà sì ń fetí sí i.”’+
20 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Ẹ̀yin obìnrin yìí, mo kórìíra àwọn ìfúnpá yín tí ẹ fi ń dọdẹ àwọn èèyàn* bíi pé wọ́n jẹ́ ẹyẹ, èmi yóò já a kúrò ní ọwọ́ yín, èmi yóò sì tú àwọn tí ẹ̀ ń dọdẹ wọn bí ẹyẹ sílẹ̀.
21 Èmi yóò fa ìbòrí yín ya, màá sì gba àwọn èèyàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ yín, ẹ ò ní lè dọdẹ wọn mọ́; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+
22 Torí ẹ ti fi èké ba olódodo lọ́kàn jẹ́,+ nígbà tí èmi kò bà á nínú jẹ́,* ẹ sì ti ki ẹni burúkú láyà,+ kó má bàa fi iṣẹ́ burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kó lè wà láàyè.+
23 Torí náà, ẹ̀yin obìnrin yìí ò ní rí ìran èké mọ́, ẹ ò sì ní woṣẹ́+ mọ́; èmi yóò gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ yín, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ látinú ọkàn wọn.”
^ Ìyẹn ni pé, wọ́n máa ń fi ẹfun kun àwọn ògiri inú tí kò lágbára kó lè dà bíi pé ó lágbára.
^ Ní Héb., “àti ìwọ yìnyín.”
^ Ìyẹn, ìfúnpá tàbí ẹ̀gbà àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “àwọn ọkàn.”
^ Tàbí “àwọn ọkàn.”
^ Tàbí “àwọn ọkàn.”
^ Tàbí “ni ín lára.”