Ìsíkíẹ́lì 15:1-8

  • Àjàrà tí kò wúlò ni Jerúsálẹ́mù (1-8)

15  Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Ọmọ èèyàn, ọ̀nà wo ni igi àjàrà gbà jọ àwọn igi yòókù tàbí àwọn ẹ̀ka igi inú igbó?  Ǹjẹ́ igi rẹ̀ wúlò fún iṣẹ́ kankan? Àbí àwọn èèyàn lè fi igi rẹ̀ ṣe èèkàn tí wọ́n á máa fi nǹkan kọ́?  Wò ó! Wọ́n fi dáná, iná jó o lórí àti ní ìdí, àárín rẹ̀ sì gbẹ. Ṣé ó wá wúlò fún iṣẹ́ kankan báyìí?  Nígbà tó ṣì wà lódindi, kò wúlò fún ohunkóhun. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí iná jó o, tó sì gbẹ!”  “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bí igi àjàrà láàárín àwọn igi inú igbó, tí mo ti sọ di ohun ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.+  Mo ti gbéjà kò wọ́n. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ iná, síbẹ̀ iná máa jó wọn run. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá gbéjà kò wọ́n.’”+  “‘Èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ torí pé wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé