Ìsíkíẹ́lì 25:1-17

  • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Ámónì (1-7)

  • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Móábù (8-11)

  • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Édómù (12-14)

  • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Filísíà (15-17)

25  Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.+  Kí o sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí ẹ sọ pé ‘Àháà!’ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì di ahoro àti nígbà tí ilé Júdà lọ sí ìgbèkùn,  torí náà, èmi yóò mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn tẹ̀ ọ́, wàá sì di ohun ìní wọn. Wọ́n á kọ́ àwọn ibùdó* wọn sínú rẹ, wọ́n á sì pàgọ́ wọn sáàárín rẹ. Wọ́n á jẹ èso rẹ, wọ́n á sì mu wàrà rẹ.  Èmi yóò sọ Rábà+ di ibi tí àwọn ràkúnmí á ti máa jẹko, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì di ibi ìsinmi agbo ẹran; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí ẹ pàtẹ́wọ́,+ tí ẹ fẹsẹ̀ kilẹ̀, tí ẹ* sì ń yọ̀ bí ẹ ṣe ń fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe irú ẹlẹ́yà yìí,+  torí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ yín, kí n lè mú kí àwọn orílẹ̀-èdè kó ẹrù yín lọ. Màá pa yín rẹ́ láàárín àwọn èèyàn, màá sì pa yín run ní àwọn ilẹ̀ náà.+ Màá pa yín rẹ́, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí Móábù+ àti Séírì + sọ pé: “Wò ó! Ilé Júdà dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù,”  èmi yóò mú kó rọrùn láti gbógun ti àwọn ìlú tó wà ní ẹ̀gbẹ́* Móábù, ní ààlà rẹ̀. Àwọn ló rẹwà* jù ní ilẹ̀ náà, Bẹti-jẹ́ṣímótì, Baali-méónì, títí dé Kiriátáímù.+ 10  Màá mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn+ tẹ òun àti àwọn ọmọ Ámónì, yóò sì di ohun ìní wọn, kí a má bàa rántí àwọn ọmọ Ámónì mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 11  Èmi yóò ṣèdájọ́ ní Móábù,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’ 12  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13  torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+ 14  ‘Màá lo àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì láti gbẹ̀san lára Édómù.+ Wọ́n á mú ìbínú mi àti ìrunú mi wá sórí Édómù, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ló ń gbẹ̀san lára wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’ 15  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èrò ìkà tó wà lọ́kàn àwọn Filísínì* ti mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san kí wọ́n sì pani run, torí wọn ò yéé kórìíra.+ 16  Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ àwọn Filísínì,+ màá pa àwọn Kérétì rẹ́,+ màá sì run àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn tó ń gbé ní etí òkun.+ 17  Màá gbẹ̀san lára wọn lọ́nà tó lé kenkà, màá fi ìbínú jẹ wọ́n níyà, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àgọ́ olódi.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “lọ́ṣọ̀ọ́.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Tàbí “Bí àwọn Filísínì ṣe rẹró sínú.”