Ìsíkíẹ́lì 44:1-31
44 Ó mú mi pa dà wá sí ẹnubodè ibi mímọ́ tó wà níta tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ ó sì wà ní títì pa.+
2 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ẹnubodè yìí yóò wà ní títì pa. Wọn ò ní ṣí i, èèyàn kankan ò sì ní gba ibẹ̀ wọlé; torí Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti gba ibẹ̀ wọlé,+ torí náà, yóò wà ní títì pa.
3 Àmọ́, ìjòyè yóò jókòó síbẹ̀ kó lè jẹ oúnjẹ níwájú Jèhófà,+ torí ìjòyè ni. Yóò gba ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà wọlé, ibẹ̀ sì ni yóò gbà jáde.”+
4 Lẹ́yìn náà, ó mú mi gba ẹnubodè àríwá wá sí iwájú tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí mo wò, mo rí i pé ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Torí náà, mo dojú bolẹ̀.+
5 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, fiyè sílẹ̀,* la ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ohun tí mo bá sọ fún ọ nípa àwọn ìlànà àti òfin tẹ́ńpìlì Jèhófà. Fiyè sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà dáadáa àti gbogbo ọ̀nà àbájáde ibi mímọ́.+
6 Kí o sọ fún ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwà ìríra tí ẹ̀ ń hù tó gẹ́ẹ́, ilé Ísírẹ́lì.
7 Tí ẹ bá mú àwọn àjèjì tí kò kọlà* ọkàn àti ara wá sínú ibi mímọ́ mi, ṣe ni wọ́n ń sọ tẹ́ńpìlì mi di aláìmọ́. Ẹ̀ ń gbé oúnjẹ, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀ wá fún mi, àmọ́ torí ìwà ìríra yín, ẹ̀ ń da májẹ̀mú mi.
8 Ẹ ò bójú tó àwọn ohun mímọ́ mi.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yan àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n bójú tó iṣẹ́ nínú ibi mímọ́ mi.”’
9 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Àjèjì kankan tó ń gbé ní Ísírẹ́lì, tí kò kọlà* ọkàn àti ara kò gbọ́dọ̀ wọnú ibi mímọ́ mi.”’
10 “‘Àmọ́ àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n kúrò lẹ́yìn mi+ nígbà tí Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11 Wọ́n á di ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ mi kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì,+ kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Wọn yóò pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rú odindi ẹbọ sísun àti ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ torí àwọn èèyàn, wọn yóò sì dúró níwájú àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún wọn.
12 Torí pé iwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ni àwọn ọmọ Léfì náà ti ṣiṣẹ́ fún wọn, tí wọ́n sì di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó mú kí ilé Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀,+ ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn tí mo sì búra, wọ́n á sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
13 ‘Wọn ò ní wá sọ́dọ̀ mi láti ṣe àlùfáà mi, wọn ò ní sún mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ohun mímọ́ jù lọ, ojú á sì tì wọ́n torí ohun ìríra tí wọ́n ṣe.
14 Àmọ́ èmi yóò mú kí wọ́n máa bójú tó àwọn iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì, màá mú kí wọ́n máa bójú tó ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú rẹ̀.’+
15 “‘Ní ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àwọn ọmọ Sádókù,+ àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀,+ wọn yóò wá sọ́dọ̀ mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi, wọn yóò sì dúró níwájú mi kí wọ́n lè fi ọ̀rá+ àti ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
16 ‘Àwọn ni yóò wọnú ibi mímọ́ mi, wọ́n á wá síbi tábìlì mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi,+ wọ́n á sì bójú tó iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe fún mi.+
17 “‘Tí wọ́n bá wá sí àwọn ẹnubodè àgbàlá inú, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀.*+ Wọn ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ kankan tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹnubodè àgbàlá inú tàbí tí wọ́n bá wọlé.
18 Kí wọ́n wé láwàní tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe sórí, kí wọ́n sì wọ ṣòkòtò péńpé tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe tó máa bo ìbàdí wọn.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ wọ ohunkóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n làágùn.
19 Kí wọ́n tó jáde lọ sí àgbàlá ìta, ní àgbàlá ìta tí àwọn èèyàn wà, kí wọ́n bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ kí wọ́n sì kó wọn sínú àwọn yàrá ìjẹun mímọ́.*+ Kí wọ́n wá wọ aṣọ míì, kí wọ́n má bàa fi aṣọ wọn sọ àwọn èèyàn di mímọ́.
20 Wọn ò gbọ́dọ̀ fá orí wọn,+ wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn gùn jù. Kí wọ́n máa gé irun orí wọn lọ sílẹ̀.
21 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tí wọ́n bá wá sí àgbàlá inú.+
22 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ opó tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀;+ àmọ́ wọ́n lè fẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ wúńdíá tàbí ìyàwó àlùfáà tó ti di opó.’+
23 “‘Kí wọ́n fún àwọn èèyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ; wọ́n á sì kọ́ wọn ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́.+
24 Tí ẹjọ́ kan bá wáyé, àwọn ni kí wọ́n ṣe adájọ́;+ ẹjọ́ tí wọ́n bá dá gbọ́dọ̀ bá àwọn ìdájọ́ mi mu.+ Kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà mi tó wà fún gbogbo àwọn àjọ̀dún mi,+ kí wọ́n sì máa sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́.
25 Wọn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ òkú èèyàn, torí yóò mú kí wọ́n di aláìmọ́. Àmọ́ wọ́n lè di aláìmọ́ torí bàbá wọn, ìyá wọn, ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin, torí arákùnrin wọn tàbí arábìnrin wọn tí kò tíì ní ọkọ.+
26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti wẹ àlùfáà kan mọ́, kí wọ́n jẹ́ kó dúró fún ọjọ́ méje.
27 Ní ọjọ́ tó bá wọnú ibi mímọ́, tó wá sí àgbàlá inú láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, kó rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
28 “‘Èyí ni yóò jẹ́ ogún wọn: Èmi ni ogún wọn.+ Ẹ má ṣe fún wọn ní ohun ìní kankan ní Ísírẹ́lì, torí èmi ni ohun ìní wọn.
29 Àwọn ni yóò máa jẹ ọrẹ ọkà,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi,+ gbogbo ohun tí wọ́n bá sì yà sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yóò di tiwọn.+
30 Èyí tó dáa jù nínú gbogbo àkọ́so èso àti onírúurú ọrẹ tí ẹ bá mú wá yóò di ti àwọn àlùfáà.+ Kí ẹ fún àlùfáà ní àkọ́so ọkà yín tí ẹ ò lọ̀ kúnná.+ Èyí máa mú kí ìbùkún wà lórí ilé yín.+
31 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹyẹ tàbí ẹran kankan tó ti kú tàbí èyí tí ẹranko fà ya.’+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gọ̀bì.”
^ Ní Héb., “fọkàn sí i.”
^ Tàbí “dádọ̀dọ́.”
^ Tàbí “dádọ̀dọ́.”
^ Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “àwọn yàrá mímọ́.”