Ìsíkíẹ́lì 7:1-27

  • Òpin ti dé (1-27)

    • Àjálù tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (5)

    • Wọ́n ju owó sí ojú ọ̀nà (19)

    • Wọ́n á sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́ (22)

7  Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:  “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: ‘Òpin! Òpin ti dé bá igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà.  Òpin ti dé bá yín báyìí, màá bínú sí yín. Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.  Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín,+ torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san. Ẹ ó jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+  “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Wò ó! Àjálù, àjálù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ń bọ̀.+  Òpin ń bọ̀; òpin yóò dé; yóò dé* bá yín lójijì. Wò ó! Ó ń bọ̀.  Ó* ti dé bá yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ náà. Àkókò ń bọ̀, ọjọ́ náà sún mọ́lé.+ Gbogbo nǹkan dà rú, ariwo ayọ̀ kò sì dún lórí àwọn òkè.  “‘Láìpẹ́, inú mi á ru sí yín,+ màá bínú sí yín gidigidi.+ Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.  Mi ò ní ṣàánú yín; mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ Màá fi ìwà yín san yín lẹ́san, ẹ ó sì jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń fìyà jẹ yín.+ 10  “‘Wò ó, ọjọ́ náà! Wò ó, ó ń bọ̀!+ Ó* ti dé bá yín; ọ̀pá ti yọ ìtànná, ìgbéraga* sì ti rúwé. 11  Ìwà ipá ti hù, ó sì ti di ọ̀pá ìwà burúkú.+ Wọn ò ní yè bọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ọrọ̀ wọn, àwọn èèyàn àti òkìkí wọn kò sì ní yè bọ́. 12  Àkókò á tó, ọjọ́ náà á dé. Kí ẹni tó ń ra nǹkan má ṣe yọ̀, kí ẹni tó sì ń ta nǹkan má ṣe ṣọ̀fọ̀, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.*+ 13  Tí ẹni tó ta nǹkan bá tiẹ̀ yè é, kò ní pa dà sí ìdí ohun tó tà, torí ìran náà kan gbogbo wọn. Kò sẹ́ni tó máa pa dà, kò sì sẹ́ni tó máa gba ara rẹ̀ là torí àṣìṣe òun fúnra rẹ̀.* 14  “‘Wọ́n ti fun kàkàkí,+ gbogbo èèyàn sì ti gbára dì, àmọ́ kò sẹ́ni tó ń lọ sí ojú ogun, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.+ 15  Idà wà níta,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú. Idà ni yóò pa ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa run àwọn tó bá wà nínú ìlú.+ 16  Àwọn tó bá jàjà bọ́ yóò sá lọ sórí àwọn òkè, kálukú wọn á sì ké tẹ̀dùntẹ̀dùn torí àṣìṣe rẹ̀ bí àwọn àdàbà inú àfonífojì.+ 17  Gbogbo ọwọ́ wọn á rọ jọwọrọ, omi á sì máa ro tótó ní orúnkún wọn.*+ 18  Wọ́n ti wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+ jìnnìjìnnì sì bá wọn.* Ojú á ti gbogbo wọn, orí gbogbo wọn á sì pá.*+ 19  “‘Wọ́n á ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà, wúrà wọn á sì di ohun ìríra lójú wọn. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+ Kò ní tẹ́ wọn* lọ́rùn, wọn ò sì ní yó, torí ó* ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí wọ́n ṣe àṣìṣe. 20  Wọ́n ń fi ẹwà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn yangàn, wọ́n sì fi wọ́n* ṣe àwọn ère wọn tó ń ríni lára, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kó di ohun ìríra lójú wọn. 21  Màá mú kí àwọn àjèjì kó wọn, màá sì mú kí àwọn ẹni burúkú inú ayé kó wọn* bí ẹrù ogun, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́. 22  “‘Èmi yóò yí ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n á sì sọ ibi ìṣúra* mi di aláìmọ́, àwọn olè á wọ ibẹ̀, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 23  “‘Ṣe ẹ̀wọ̀n,*+ torí wọ́n ń fi ìdájọ́ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ ìwà ipá sì kún ìlú náà.+ 24  Màá mú orílẹ̀-èdè tó burú jù wá,+ wọ́n á sì gba àwọn ilé wọn,+ màá fòpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, àwọn ibi mímọ́ wọn á sì di aláìmọ́.+ 25  Nígbà tí wọ́n bá ń jẹ̀rora, wọ́n á wá àlàáfíà àmọ́ wọn kò ní rí i.+ 26  Àjálù á ré lu àjálù, wọ́n á gbọ́ ìròyìn kan tẹ̀ lé òmíràn, àwọn èèyàn á wá ìran lọ sọ́dọ̀ wòlíì,+ àmọ́ òfin* yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àlùfáà, ìmọ̀ràn ò sì ní sí lẹ́nu àwọn àgbààgbà.+ 27  Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,+ ìbànújẹ́* máa bá àwọn ìjòyè, ìbẹ̀rù yóò sì mú kí ọwọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa gbọ̀n. Ìwà wọn ni màá fi san wọ́n lẹ́san, èmi yóò sì dá wọn lẹ́jọ́ bí wọ́n ṣe dá àwọn míì lẹ́jọ́. Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “jí.”
Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”
Ìyẹn ni pé, àwọn tó ń rà àti àwọn tó ń tà kò ní rí àǹfààní kankan, torí gbogbo wọn ló máa pa run.
Tàbí kó jẹ́, “torí àṣìṣe rẹ̀.”
Ìyẹn ni pé, ìbẹ̀rù á mú kí wọ́n máa tọ̀ sára.
Ìyẹn ni pé, wọ́n á fá orí wọn torí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀.
Ní Héb., “jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọkàn wọn.”
Ìyẹn, fàdákà àti wúrà wọn.
Ìyẹn, àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà wọn ṣe.
Ìyẹn, wúrà àti fàdákà wọn tí wọ́n fi ṣe ère.
Ó jọ pé ibi mímọ́ Jèhófà ní inú lọ́hùn-ún ló ń sọ.
Ìyẹn, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n á fi kó wọn lẹ́rú.
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “ìrẹ̀wẹ̀sì.”