Òwe 2:1-22

  • Ìwúlò ọgbọ́n (1-22)

    • Máa wá ọgbọ́n bí ìṣúra tó fara sin (4)

    • Làákàyè ń dáàbò boni (11)

    • Ìṣekúṣe máa ń fa àjálù (16-19)

2  Ọmọ mi, tí o bá gba àwọn ọ̀rọ̀ miTí o sì fi àwọn àṣẹ mi ṣe ìṣúra rẹ,+   Nípa fífi etí sí ọgbọ́n+Àti fífi ọkàn sí ìfòyemọ̀;+   Bákan náà, tí o bá ké pe òye+Tí o sì nahùn pe ìfòyemọ̀;+   Tí o bá ń wá a bíi fàdákà,+Tí o sì ń wá a kiri bí àwọn ìṣúra tó fara sin;+   Nígbà náà, wàá lóye ìbẹ̀rù Jèhófà,+Wàá sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.+   Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n;+Ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.   Ó ń to ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣinṣin;Ó jẹ́ apata fún àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.+   Ó ń pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́,Ó sì ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin rẹ̀.+   Nígbà náà, wàá lóye ohun tó jẹ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ àti àìṣègbè,Gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere.+ 10  Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn rẹ+Tí ìmọ̀ sì tù ọ́ lára,*+ 11  Làákàyè yóò máa ṣọ́ ọ,+Ìfòyemọ̀ yóò sì máa dáàbò bò ọ́, 12  Láti gbà ọ́ kúrò ní ọ̀nà búburú,Kúrò lọ́wọ́ ẹni tó ń sọ ọ̀rọ̀ àyídáyidà,+ 13  Kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ọ̀nà òdodo* sílẹ̀Kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀nà òkùnkùn,+ 14  Kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ìwà àìtọ́ ṣayọ̀,Àwọn tí ìwà tó burú jáì ń múnú wọn dùn, 15  Àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́Tí gbogbo ọ̀nà wọn sì jẹ́ békebèke. 16  Yóò dáàbò bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin oníwàkiwà,*Kúrò lọ́wọ́ ọ̀rọ̀ dídùn* obìnrin oníṣekúṣe,*+ 17  Ẹni tó fi ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́* ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀+Tó sì gbàgbé májẹ̀mú Ọlọ́run rẹ̀; 18  Nítorí ilé rẹ̀ ń rini sínú ikú,Àwọn ọ̀nà* rẹ̀ sì lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ikú ti pa.*+ 19  Kò sí ìkankan lára àwọn tó ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀* tó máa pa dà,Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní pa dà sí ọ̀nà ìyè.+ 20  Torí náà, máa gba ọ̀nà àwọn ẹni rereMá sì kúrò ní ọ̀nà àwọn olódodo,+ 21  Nítorí àwọn adúróṣinṣin ló máa gbé ní ayé,Àwọn aláìlẹ́bi* ló sì máa ṣẹ́ kù sínú rẹ̀.+ 22  Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé,+Ní ti àwọn oníbékebèke, a ó fà wọ́n tu kúrò nínú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìdúróṣinṣin.”
Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Ó ṣe kedere pé èyí tí ìwà rẹ̀ kò bá ti Ọlọ́run mu mọ́ ni.
Tàbí “fífanimọ́ra.”
Ní Héb., “obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.” Ó ṣe kedere pé èyí tí ìwà rẹ̀ jìnnà sí ti Ọlọ́run ni.
Tàbí “ọkọ.”
Ní Héb., “Àwọn ipa ọ̀nà.”
Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
Ní Héb., “wọlé sọ́dọ̀ rẹ̀.”
Tàbí “Àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”