Òwe 20:1-30
20 Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì,+ aláriwo ni ọtí;+Ẹni tó bá sì tipasẹ̀ wọn ṣìnà kò gbọ́n.+
2 Ẹ̀rù* tó wà lára ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn;+Ẹnikẹ́ni tó bá mú un bínú ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu.+
3 Ògo ló jẹ́ fún èèyàn láti yẹra fún ìjà,+Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ jẹ́ aríjàgbá.+
4 Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù,Tó bá dìgbà ìkórè, á máa tọrọ torí pé kò ní nǹkan kan.*+
5 Èrò* ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn,Àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,Àmọ́ ibo la ti lè rí olóòótọ́ èèyàn?
7 Olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀.+
Aláyọ̀ ni àwọn ọmọ* tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀.+
8 Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ láti dájọ́,+Ó máa ń fi ojú rẹ̀ yẹ ọ̀ràn wò kí ó lè mú gbogbo ìwà ibi kúrò.+
9 Ta ló lè sọ pé: “Mo ti wẹ ọkàn mi mọ́;+Mo ti mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi”?+
10 Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n èké*Àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà.+
11 Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé* pàápàá dá a mọ̀,Bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.+
12 Etí tí a fi ń gbọ́ràn àti ojú tí a fi ń ríranJèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+
13 Má ṣe nífẹ̀ẹ́ oorun, torí wàá di aláìní.+
La ojú rẹ, wàá sì máa jẹ àjẹtẹ́rùn.+
14 “Èyí ò dáa, tọ̀hún ò dáa!” ni ẹni tó ń rajà ń sọ;Lẹ́yìn náà, ó bá tirẹ̀ lọ, ó sì ń yangàn.+
15 Wúrà wà, ọ̀pọ̀ iyùn* sì wà,Àmọ́ ètè ìmọ̀ jẹ́ ohun tó ṣeyebíye.+
16 Gba ẹ̀wù ẹni tó bá ṣe onídùúró fún àjèjì;+Tó bá sì jẹ́ pé obìnrin àjèjì* ló ṣe é fún, gba ohun tó fi ṣe ìdúró lọ́wọ́ rẹ̀.+
17 Oúnjẹ tí a fi èrú kó jọ máa ń dùn lẹ́nu èèyàn,Àmọ́ tó bá yá, òkúta ni yóò kún ẹnu rẹ̀.+
18 Ìmọ̀ràn* máa ń jẹ́ kí ohun téèyàn fẹ́ ṣe yọrí sí rere,*+Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n sì ni kí o fi ja ogun rẹ.+
19 Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri;+Má ṣe bá ẹni tó fẹ́ràn láti máa ṣòfófó* kẹ́gbẹ́.
20 Ẹni tó bá bú bàbá àti ìyá rẹ̀,Fìtílà rẹ̀ yóò kú nígbà tí òkùnkùn bá ṣú.+
21 Ogún téèyàn bá fi ojúkòkòrò gbà níbẹ̀rẹ̀Kì í ní ìbùkún lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+
22 Má ṣe sọ pé: “Màá fi búburú san búburú!”+
Ní ìrètí nínú Jèhófà,+ yóò sì gbà ọ́ là.+
23 Jèhófà kórìíra ìwọ̀n èké,*Òṣùwọ̀n èké kò sì dára.
24 Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ èèyàn;+Báwo ni èèyàn ṣe lè lóye ọ̀nà ara rẹ̀?*
25 Ìdẹkùn ni téèyàn bá sọ láìronú pé, “Mímọ́!”+
Lẹ́yìn náà, kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú lórí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́.+
26 Ọlọ́gbọ́n ọba máa ń yọ àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀+Á sì wa àgbá kẹ̀kẹ́ ìpakà kọjá lórí wọn.+
27 Èémí èèyàn jẹ́ fìtílà Jèhófà,Ó ń ṣàyẹ̀wò inú rẹ̀ lọ́hùn-ún.
28 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ ń dáàbò bo ọba;+Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sì ń jẹ́ kó pẹ́ lórí ìtẹ́ rẹ̀.+
29 Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn,+Iyì àwọn arúgbó sì ni ewú orí wọn.+
30 Ọgbẹ́ àti egbò máa ń fọ* ibi dà nù,+Lílù sì ń fọ inú èèyàn lọ́hùn-ún mọ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ìpayà.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Tàbí kó jẹ́, “Á máa wá nǹkan nígbà ìkórè, àmọ́ kò ní rí nǹkan kan.”
^ Ní Héb., “Ìmọ̀ràn.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
^ Tàbí “Òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì àti ohun èèlò ìdíwọ̀n oríṣi méjì.”
^ Tàbí “ọmọdékùnrin.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àjèjì kan.”
^ Tàbí “Àmọ̀ràn.”
^ Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
^ Tàbí “ẹni tó máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ fajú èèyàn mọ́ra.”
^ Tàbí “òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì.”
^ Tàbí “ọ̀nà tó yẹ kó gbà?”
^ Tàbí “nu.”