Òwe 29:1-27
29 Ẹni tó ń mú ọrùn rẹ̀ le* lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí +Yóò pa run lójijì láìsí àtúnṣe.+
2 Nígbà tí olódodo bá pọ̀, àwọn èèyàn á máa yọ̀,Àmọ́ tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn èèyàn á máa kérora.+
3 Ẹni tó fẹ́ràn ọgbọ́n ń mú bàbá rẹ̀ yọ̀,+Àmọ́ ẹni tó ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ń fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò.+
4 Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tòrò,+Àmọ́ ẹni tó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò da ibẹ̀ rú.
5 Ẹni tó ń pọ́n ọmọnìkejì rẹ̀Ń ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ rẹ̀.+
6 Ẹ̀ṣẹ̀ èèyàn búburú ń dẹkùn mú un,+Àmọ́ olódodo ń kígbe ayọ̀, inú rẹ̀ sì ń dùn.+
7 Ẹ̀tọ́ àwọn aláìní jẹ olódodo lọ́kàn,+Àmọ́ ẹni burúkú kì í ronú irú nǹkan bẹ́ẹ̀.+
8 Àwọn tó ń fọ́nnu máa ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ nínú ìlú,+Àmọ́ àwọn tó gbọ́n máa ń paná ìbínú.+
9 Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá ń bá òmùgọ̀ fa ọ̀rọ̀,Ariwo àti yẹ̀yẹ́ á gbòde kan, síbẹ̀ kò ní sí ìsinmi.+
10 Àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ máa ń kórìíra ẹni tó bá jẹ́ aláìṣẹ̀,*+Wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* àwọn adúróṣinṣin.*
11 Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára* òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.+
12 Tí alákòóso bá ti ń fetí sí irọ́,Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò di ẹni burúkú.+
13 Ohun tí aláìní àti aninilára fi jọra* ni pé:
Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú àwọn méjèèjì.*
14 Tí ọba bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní bó ṣe tọ́,+Ìtẹ́ rẹ̀ á fìdí múlẹ̀ títí lọ.+
15 Ọ̀pá* àti ìbáwí ń kọ́ni ní ọgbọ́n,+Àmọ́ ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.
16 Tí àwọn ẹni burúkú bá ti ń pọ̀ sí i, ẹ̀ṣẹ̀ á máa pọ̀ sí i,Àmọ́ àwọn olódodo yóò rí ìṣubú wọn.+
17 Kọ́ ọmọ rẹ, yóò fún ọ ní ìsinmi;Yóò sì mú inú rẹ dùn* gan-an.+
18 Níbi tí kò bá ti sí ìran,* àwọn èèyàn á máa ṣe bó ṣe wù wọ́n,+Àmọ́ aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa òfin mọ́.+
19 Ìránṣẹ́ kì í jẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu tọ́ òun sọ́nà,Bó tiẹ̀ yé e, kò ní ṣègbọràn.+
20 Ṣé o ti rí ẹni tí kì í ronú kó tó sọ̀rọ̀?+
Ìrètí wà fún òmùgọ̀ ju fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ.+
21 Tí a bá kẹ́ ìránṣẹ́ kan ní àkẹ́jù látìgbà èwe rẹ̀,Tó bá yá, kò ní mọ ọpẹ́ dá.
22 Ẹni tó bá ń tètè bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀;+Onínúfùfù sì máa ń dá ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀.+
23 Ìgbéraga èèyàn ni yóò rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò gba ògo.+
24 Ẹni tó ń bá olè kẹ́gbẹ́ kórìíra ara rẹ̀.*
Ó lè gbọ́ pé kí àwọn èèyàn wá jẹ́rìí,* àmọ́ kò ní sọ nǹkan kan.+
25 Ìbẹ̀rù* èèyàn jẹ́* ìdẹkùn,+Àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò rí ààbò.+
26 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ bá alákòóso sọ̀rọ̀,*Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èèyàn ti ń rí ìdájọ́ òdodo gbà.+
27 Aláìṣòótọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú olódodo,+Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́ sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú èèyàn burúkú.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tó ń ṣorí kunkun.”
^ Tàbí “aláìlẹ́bi.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àmọ́ adúróṣinṣin máa ń wá ọ̀nà láti dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀. ”
^ Ní Héb., “Gbogbo ẹ̀mí.”
^ Ní Héb., “bára pàdé.”
^ Ìyẹn ni pé, Òun ló fún wọn ní ẹ̀mí.
^ Tàbí “Ìbáwí; Ìfìyàjẹni.”
^ Tàbí “mú ọkàn rẹ yọ̀.”
^ Tàbí “ìran alásọtẹ́lẹ̀; ìfihàn.”
^ Tàbí “ọkàn òun fúnra rẹ̀.”
^ Tàbí “gbọ́ ìbúra kan tó ní ègún nínú.”
^ Ní Héb., “Wíwárìrì nítorí.”
^ Tàbí “ń dẹ.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ń wá ojú rere alákòóso.” Ní Héb., “ń wá ojú alákòóso.”