Àwọn Ọba Kìíní 11:1-43

  • Àwọn ìyàwó Sólómọ́nì yí i lọ́kàn pa dà (1-13)

  • Àwọn alátakò dìde sí Sólómọ́nì (14-25)

  • Ọlọ́run ṣèlérí ẹ̀yà mẹ́wàá fún Jèróbóámù (26-40)

  • Sólómọ́nì kú; wọ́n fi Rèhóbóámù jọba (41-43)

11  Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+  Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn.  Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.*  Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó,+ àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run míì,+ kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì bàbá rẹ̀.  Sólómọ́nì yíjú sí Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì àti Mílíkómù,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.  Sólómọ́nì ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà, kò sì tẹ̀ lé Jèhófà délẹ̀délẹ̀* bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.+  Ìgbà náà ni Sólómọ́nì kọ́ ibi gíga+ kan fún Kémóṣì, ọlọ́run ìríra Móábù, lórí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù, ó sì tún kọ́ òmíràn fún Mólékì,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.+  Ohun tí ó ṣe fún gbogbo ìyàwó ilẹ̀ àjèjì tó fẹ́ nìyẹn, àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn.  Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì, nítorí ọkàn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì,+ 10  tí ó sì kìlọ̀ fún un nípa nǹkan yìí pé kí ó má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì.+ Àmọ́ kò ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. 11  Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò pa májẹ̀mú mi àti òfin mi mọ́, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, màá rí i dájú pé mo fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, màá sì fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+ 12  Àmọ́, nítorí Dáfídì bàbá rẹ, mi ò ní ṣe èyí nígbà ayé rẹ. Ọwọ́ ọmọ rẹ ni màá ti fà á ya,+ 13  àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìjọba náà+ ni màá fà ya. Màá fún ọmọ rẹ ní ẹ̀yà kan,+ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerúsálẹ́mù tí mo yàn.”+ 14  Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé alátakò kan dìde sí Sólómọ́nì,+ ìyẹn Hádádì ọmọ Édómù, láti ìdílé ọba Édómù.+ 15  Nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun Édómù,+ Jóábù olórí ọmọ ogun lọ sin àwọn tó kú, ó sì wá ọ̀nà láti pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù. 16  (Nítorí oṣù mẹ́fà ni Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì fi gbé ibẹ̀ títí ó fi pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù run.*) 17  Àmọ́ Hádádì fẹsẹ̀ fẹ pẹ̀lú àwọn kan lára ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Édómù, wọ́n sì lọ sí Íjíbítì; ọmọdé ni Hádádì nígbà yẹn. 18  Nítorí náà, wọ́n kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì wá sí Páránì. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin kan láti Páránì,+ wọ́n sì wá sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, ẹni tó fún un ní ilé, tó ṣètò bí á ṣe máa rí oúnjẹ gbà, tó sì fún un ní ilẹ̀. 19  Hádádì rí ojú rere Fáráò débi pé ó fún un ní àbúrò ayaba Tápénésì, ìyàwó rẹ̀, pé kó fi ṣe aya. 20  Nígbà tó yá, àbúrò Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un, Génúbátì lorúkọ rẹ̀, Tápénésì tọ́ ọ dàgbà* ní ilé Fáráò, Génúbátì sì ń gbé ní ilé Fáráò láàárín àwọn ọmọ Fáráò. 21  Hádádì gbọ́ ní Íjíbítì pé Dáfídì ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ àti pé Jóábù olórí ọmọ ogun ti kú.+ Torí náà, Hádádì sọ fún Fáráò pé: “Jẹ́ kí n lọ, kí n lè lọ sí ilẹ̀ mi.” 22  Àmọ́ Fáráò sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ tí o kò ní lọ́dọ̀ mi tí o fi fẹ́ lọ sí ilẹ̀ rẹ?” Ó fèsì pé: “Kò sí, àmọ́ jọ̀wọ́ jẹ́ kí n lọ.” 23  Ọlọ́run tún gbé alátakò míì dìde+ sí Sólómọ́nì, ìyẹn Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tó sá kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, Hadadésà+ ọba Sóbà. 24  Ó kó àwọn ọkùnrin jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí àwọn jàǹdùkú* nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun*+ àwọn ọkùnrin Sóbà. Nítorí náà, wọ́n lọ sí Damásíkù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣàkóso ní Damásíkù. 25  Ó di alátakò Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé Sólómọ́nì, ó dá kún jàǹbá tí Hádádì ṣe, ó sì kórìíra Ísírẹ́lì gan-an nígbà tó ń jọba lórí Síríà. 26  Ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì nínú ẹ̀yà Éfúrémù, ó wá láti Sérédà, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì+ ni. Sérúà lorúkọ ìyá rẹ̀, opó sì ni. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀* sí ọba.+ 27  Ohun tó jẹ́ kó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni pé: Sólómọ́nì mọ Òkìtì,*+ ó sì dí àlàfo Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀.+ 28  Ọkùnrin tó dáńgájíá ni Jèróbóámù. Nígbà tí Sólómọ́nì rí i pé ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ó fi í ṣe alábòójútó+ gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọ̀ranyàn ní ilé Jósẹ́fù. 29  Ní àkókò yẹn, Jèróbóámù jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wòlíì Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sì rí i lọ́nà. Ẹ̀wù tuntun ló wà lọ́rùn Áhíjà, àwọn méjèèjì nìkan ló sì wà ní pápá. 30  Áhíjà di ẹ̀wù tuntun tó wà lọ́rùn rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá (12). 31  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèróbóámù pé: “Gba mẹ́wàá yìí, torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, màá sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 32  Àmọ́ ẹ̀yà kan ṣì máa jẹ́ tirẹ̀+ nítorí ìránṣẹ́ mi Dáfídì+ àti nítorí Jerúsálẹ́mù, ìlú tí mo yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+ 33  Ohun tí màá ṣe nìyí torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún Áṣítórétì, abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì, fún Kémóṣì, ọlọ́run Móábù àti fún Mílíkómù, ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì, wọn ò rìn ní àwọn ọ̀nà mi láti máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi àti láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómọ́nì ti ṣe. 34  Àmọ́ mi ò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, màá ṣì fi ṣe olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí mo yàn,+ torí ó pa àwọn àṣẹ àti òfin mi mọ́. 35  Ṣùgbọ́n màá gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, màá sì fi í fún ọ, ìyẹn ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 36  Màá fún ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀yà kan ṣoṣo, kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ṣàkóso* níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerúsálẹ́mù,+ ìlú tí mo yàn fún ara mi láti fi orúkọ mi sí. 37  Màá yàn ọ́, wàá ṣàkóso lórí gbogbo ohun tí o* fẹ́, wàá sì di ọba lórí Ísírẹ́lì. 38  Tí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi láti máa pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe,+ èmi náà á wà pẹ̀lú rẹ. Màá kọ́ ilé tó máa wà títí lọ fún ọ, bí mo ṣe kọ́ ọ fún Dáfídì,+ màá sì fún ọ ní Ísírẹ́lì. 39  Màá dójú ti àtọmọdọ́mọ Dáfídì nítorí èyí,+ àmọ́ kò ní jẹ́ títí lọ.’”+ 40  Torí náà, Sólómọ́nì wá ọ̀nà láti pa Jèróbóámù, àmọ́ Jèróbóámù sá lọ sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì,+ ó sì ń gbé ní Íjíbítì títí Sólómọ́nì fi kú. 41  Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì, gbogbo ohun tí ó ṣe àti ọgbọ́n rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn Sólómọ́nì?+ 42  Gbogbo ọdún* tí Sólómọ́nì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ogójì (40) ọdún. 43  Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀; Rèhóbóámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fẹ́ wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ yín.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Tàbí “àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Ní Héb., “ní kíkún.”
Ní Héb., “ké gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù kúrò.”
Tàbí kó jẹ́, “gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “pa.”
Ní Héb., “gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.”
Tàbí “Mílò.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “iyẹ̀pẹ̀ tí a kó jọ gègèrè.”
Ní Héb., “ní fìtílà.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “Àwọn ọjọ́.”