Àwọn Ọba Kìíní 16:1-34
16 Jèhófà gbẹnu Jéhù+ ọmọ Hánáánì+ kéde ìdájọ́ sórí Bááṣà pé:
2 “Mo gbé ọ dìde láti inú iyẹ̀pẹ̀, mo sì sọ ọ́ di aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ ṣùgbọ́n ò ń rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù, o sì mú kí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì ṣẹ̀, tí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá+ sì mú mi bínú.
3 Torí náà, màá gbá Bááṣà àti ilé rẹ̀ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì.
4 Ajá ni yóò jẹ ará ilé Bááṣà èyíkéyìí tí ó bá kú sínú ìlú; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ni yóò sì jẹ ará ilé rẹ̀ èyíkéyìí tí ó bá kú sí pápá.”
5 Ní ti ìyókù ìtàn Bááṣà àti ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
6 Níkẹyìn, Bááṣà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sin ín sí Tírísà,+ Élà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
7 Jèhófà tún gbẹnu wòlíì Jéhù ọmọ Hánáánì kéde ìdájọ́ sórí Bááṣà àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo ìwà búburú tí ó hù ní ojú Jèhófà, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú un bínú, bí ilé Jèróbóámù àti nítorí pé ó ṣá a* balẹ̀.+
8 Ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Élà ọmọ Bááṣà di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Tírísà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso.
9 Ìránṣẹ́ rẹ̀ Símírì, tó jẹ́ olórí ìdajì àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun, dìtẹ̀ mọ́ ọn nígbà tó wà ní Tírísà, tí ó ń fi ọtí rọ ara rẹ̀ yó ní ilé Árísà, ẹni tí ó ń bójú tó agbo ilé ní Tírísà.
10 Símírì wọlé, ó ṣá a balẹ̀,+ ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, ó sì jọba ní ipò rẹ̀.
11 Nígbà tí ó jọba, gbàrà tí ó gorí ìtẹ́, ó pa gbogbo ará ilé Bááṣà. Kò fi ọkùnrin* kankan sílẹ̀, ì báà jẹ́ ìbátan* rẹ̀ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12 Bí Símírì ṣe pa gbogbo ilé Bááṣà rẹ́ nìyẹn, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Jéhù kéde sórí Bááṣà.+
13 Èyí jẹ́ nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Bááṣà àti Élà ọmọ rẹ̀ dá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n mú kí Ísírẹ́lì dá, tí wọ́n fi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.
14 Ní ti ìyókù ìtàn Élà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
15 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Símírì di ọba ní Tírísà, ọjọ́ méje ló sì fi jọba nígbà tí àwọn ọmọ ogun dó ti Gíbétónì,+ tó jẹ́ ti àwọn Filísínì.
16 Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ogun tó wà ní ibùdó gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé: “Símírì ti dìtẹ̀, ó sì ti pa ọba.” Torí náà, gbogbo Ísírẹ́lì fi Ómírì,+ olórí àwọn ọmọ ogun jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn ní ibùdó.
17 Ómírì àti gbogbo Ísírẹ́lì tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá gbéra ní Gíbétónì, wọ́n sì lọ dó ti Tírísà.
18 Nígbà tí Símírì rí i pé wọ́n ti gba ìlú náà, ó wọ inú ilé gogoro tó láàbò tó wà ní ilé* ọba, ó dáná sun ilé náà mọ́ ara rẹ̀ lórí, ó sì kú.+
19 Èyí jẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà, tí ó sì rìn ní ọ̀nà Jèróbóámù àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó mú kí Ísírẹ́lì dá.+
20 Ní ti ìyókù ìtàn Símírì àti ọ̀tẹ̀ tí ó dì, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
21 Ìgbà náà ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pín sí apá méjì. Apá kan lára wọn tẹ̀ lé Tíbínì ọmọ Gínátì, wọ́n fẹ́ fi jọba, apá kejì sì tẹ̀ lé Ómírì.
22 Àmọ́, àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé Ómírì borí àwọn tó tẹ̀ lé Tíbínì ọmọ Gínátì. Torí náà, Tíbínì kú, Ómírì sì di ọba.
23 Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà, Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ọdún méjìlá (12) ló sì fi ṣàkóso. Ọdún mẹ́fà ló fi jọba ní Tírísà.
24 Ó ra òkè Samáríà lọ́wọ́ Ṣémérì ní tálẹ́ńtì* méjì fàdákà, ó kọ́ ìlú kan sórí òkè náà. Ó fi orúkọ Ṣémérì, ẹni tí ó ni* òkè náà pe ìlú tí ó kọ́, ó pè é ní Samáríà.*+
25 Ómírì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà nígbà gbogbo, tiẹ̀ tún burú ju ti gbogbo àwọn tó ṣáájú rẹ̀.+
26 Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jèróbóámù ọmọ Nébátì àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó mú kí Ísírẹ́lì dá, tí wọ́n ń fi àwọn òrìṣà asán+ wọn mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì bínú.
27 Ní ti ìyókù ìtàn Ómírì àti ohun tí ó ṣe àti àwọn ohun ribiribi tí ó gbé ṣe, ǹjẹ́ wọn kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
28 Níkẹyìn, Ómírì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà; Áhábù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
29 Áhábù ọmọ Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní ọdún kejìdínlógójì Ásà ọba Júdà, ọdún méjìlélógún (22) ni Áhábù ọmọ Ómírì sì fi ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà.+
30 Ìwà Áhábù ọmọ Ómírì tún wá burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀.+
31 Àfi bíi pé nǹkan kékeré ni lójú rẹ̀ bó ṣe ń rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì, ó tún fẹ́ Jésíbẹ́lì+ ọmọ Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Báálì,+ ó sì ń forí balẹ̀ fún un.
32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ pẹpẹ kan fún Báálì ní ilé* Báálì+ tí ó kọ́ sí Samáríà.
33 Áhábù tún ṣe òpó òrìṣà.*+ Áhábù sì ṣe ohun tó bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì nínú ju gbogbo àwọn ọba Ísírẹ́lì tó jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.
34 Nígbà tí Áhábù ń jọba, Híélì ará Bẹ́tẹ́lì tún Jẹ́ríkò kọ́. Ẹ̀mí Ábírámù àkọ́bí rẹ̀ ló fi dí i nígbà tó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ẹ̀mí Ségúbù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ló sì fi dí i nígbà tó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nàró, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jóṣúà ọmọ Núnì sọ.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, Nádábù, ọmọ Jèróbóámù.
^ Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.
^ Tàbí “agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Ní Héb., “olúwa.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ó Jẹ́ Ti Agbo Ilé Ṣémérì.”
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.