Kíróníkà Kìíní 17:1-27
17 Gbàrà tí Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú ilé* rẹ̀, ó sọ fún wòlíì Nátánì+ pé: “Mò ń gbé inú ilé tí wọ́n fi igi kédárì+ kọ́ nígbà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà wà lábẹ́ àwọn aṣọ àgọ́.”+
2 Nátánì dá Dáfídì lóhùn pé: “Ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.”
3 Lóru ọjọ́ yẹn, Ọlọ́run bá Nátánì sọ̀rọ̀, ó ní:
4 “Lọ sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé tí màá gbé fún mi.+
5 Nítorí mi ò gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Ísírẹ́lì jáde títí di òní yìí, àmọ́ mò ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti látinú àgọ́ ìjọsìn kan dé òmíràn.*+
6 Ní gbogbo àkókò tí mò ń bá gbogbo Ísírẹ́lì rìn, ṣé mo fìgbà kankan sọ fún ọ̀kan lára àwọn onídàájọ́ tí mo yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò fi kọ́ ilé onígi kédárì fún mi?’”’
7 “Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́, kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+
8 Màá wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ,+ màá sì mú* gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ màá jẹ́ kí orúkọ rẹ lókìkí bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tó wà láyé.+
9 Màá yan ibì kan fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, màá fìdí wọn kalẹ̀, wọ́n á sì máa gbé ibẹ̀ láìsì ìyọlẹ́nu mọ́; àwọn ẹni burúkú kò ní pọ́n wọn lójú* mọ́, bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀,+
10 láti ọjọ́ tí mo ti yan àwọn onídàájọ́ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ Màá ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.+ Wò ó, yàtọ̀ síyẹn, ó dájú pé, ‘Jèhófà yóò kọ́ ilé fún ọ.’*
11 “‘“Nígbà tí o bá kú, tí o sì lọ síbi tí àwọn baba ńlá rẹ wà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ,+ màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+
12 Òun ló máa kọ́ ilé fún mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+
13 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lára rẹ̀+ bí mo ṣe mú un kúrò lára ẹni tó ṣáájú rẹ.+
14 Màá mú kó dúró nínú ilé mi àti nínú ìjọba mi títí láé,+ ìtẹ́ rẹ̀ á sì wà títí láé.”’”+
15 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí fún Dáfídì.
16 Ni Ọba Dáfídì bá wọlé, ó jókòó níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run, ta ni mí? Kí ni ilé mi sì já mọ́ tí o fi mú mi dé ibi tí mo dé yìí?+
17 Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ìwọ Ọlọ́run, o tún sọ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà,+ o sì ṣíjú wò mí bíi pé ẹni tó yẹ ká túbọ̀ gbé ga* ni mí, Jèhófà Ọlọ́run.
18 Kí ni Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ tún lè sọ fún ọ nípa bí o ṣe bọlá fún mi, nígbà tí o sì mọ ìránṣẹ́ rẹ dáadáa?+
19 Jèhófà, nítorí ìránṣẹ́ rẹ àti nítorí ohun tó wà lọ́kàn rẹ* ni o fi ṣe gbogbo àwọn ohun ńlá yìí, tí o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi títóbi rẹ+ hàn.
20 Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i.
21 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run tòótọ́ lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀.+ O ṣe orúkọ fún ara rẹ bí o ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu,+ tí o sì ń lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn èèyàn rẹ+ tí o rà pa dà láti Íjíbítì.
22 O sọ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì di àwọn èèyàn tí á máa jẹ́ tìrẹ títí lọ;+ ìwọ Jèhófà sì di Ọlọ́run wọn.+
23 Ní báyìí, Jèhófà, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe nípa ìránṣẹ́ rẹ àti nípa ilé rẹ̀ ṣẹ títí láé, kí o sì ṣe ohun tí o ṣèlérí.+
24 Kí orúkọ rẹ wà* títí láé, kí a sì máa gbé e ga,+ kí àwọn èèyàn lè sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni Ọlọ́run tó ń ṣàkóso Ísírẹ́lì,’ kí ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ sì fìdí múlẹ̀ níwájú rẹ.+
25 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fi han ìránṣẹ́ rẹ ìdí tí o fẹ́ fi kọ́ ilé fún un.* Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ rẹ fi ní ìgboyà láti gba àdúrà yìí sí ọ.
26 Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, o sì ti ṣèlérí àwọn ohun rere yìí nípa ìránṣẹ́ rẹ.
27 Nítorí náà, jẹ́ kí ó dùn mọ́ ọ nínú láti bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ, sì jẹ́ kí ó máa wà títí láé níwájú rẹ, nítorí ìwọ, Jèhófà, ti bù kún un, ìbùkún á sì wà lórí rẹ̀ títí láé.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ààfin.”
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “láti ibi tí àgọ́ kan wà dé òmíràn àti láti ibi gbígbé kan dé òmíràn.”
^ Ní Héb., “ké.”
^ Ní Héb., “tán wọn lókun.”
^ Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “ẹni tó wà níbi gíga.”
^ Tàbí “bá ìfẹ́ rẹ mu.”
^ Tàbí “fìdí múlẹ̀.”
^ Tàbí “sọ ìdílé rẹ̀ di ìdílé tó ń jọba.”