Kíróníkà Kìíní 21:1-30
21 Nígbà náà, Sátánì* dìde sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí Dáfídì ka iye Ísírẹ́lì.+
2 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jóábù+ àti àwọn olórí àwọn èèyàn náà pé: “Lọ, ka Ísírẹ́lì láti Bíá-ṣébà dé Dánì;+ kí o sì wá jábọ̀ fún mi kí n lè mọ iye wọn.”
3 Ṣùgbọ́n Jóábù sọ pé: “Kí Jèhófà sọ àwọn èèyàn rẹ̀ di púpọ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100)! Olúwa mi ọba, ṣebí ìránṣẹ́ olúwa mi ni gbogbo wọn? Kí nìdí tí olúwa mi fi fẹ́ ṣe nǹkan yìí? Kí ló dé tí wàá fi mú kí Ísírẹ́lì jẹ̀bi?”
4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọba borí ti Jóábù. Torí náà, Jóábù jáde lọ, ó sì rin gbogbo Ísírẹ́lì já, lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerúsálẹ́mù.+
5 Jóábù wá fún Dáfídì ní iye àwọn tó forúkọ wọn sílẹ̀. Gbogbo Ísírẹ́lì jẹ́ mílíọ̀nù kan ó lé ọ̀kẹ́ márùn-ún (1,100,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà, Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (470,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà.+
6 Àmọ́ Léfì àti Bẹ́ńjámínì kò sí lára àwọn tí Jóábù forúkọ wọn sílẹ̀,+ torí ohun tí ọba sọ burú lójú rẹ̀.+
7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí burú gan-an lójú Ọlọ́run tòótọ́, torí náà, ó kọ lu Ísírẹ́lì.
8 Dáfídì wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+
9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní:
10 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’”
11 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mú èyí tí o bá fẹ́,
12 bóyá kí ìyàn+ fi ọdún mẹ́ta mú tàbí kí àwọn ọ̀tá rẹ fi oṣù mẹ́ta gbá ọ dà nù bí idà àwọn ọ̀tá rẹ ti ń lé ọ bá+ tàbí kí idà Jèhófà, ìyẹn àjàkálẹ̀ àrùn ní ilẹ̀ yìí,+ fi ọjọ́ mẹ́ta jà, kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa pani run+ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.’ Ní báyìí, ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.”
13 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+
14 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì, tó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) èèyàn lára Ísírẹ́lì kú.+
15 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì kan sí Jerúsálẹ́mù láti pa á run; àmọ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà rí i, ó sì pèrò dà* lórí àjálù náà,+ ó sọ fún áńgẹ́lì tó ń pani run náà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!+ Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀.” Áńgẹ́lì Jèhófà dúró nítòsí ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.+
16 Nígbà tí Dáfídì gbójú sókè, ó rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró láàárín ayé àti ọ̀run pẹ̀lú idà tó fà yọ+ ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì nà án sí Jerúsálẹ́mù. Ní kíá, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀*+ bora wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+
17 Dáfídì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ṣebí èmi ni mo ní kí wọ́n lọ ka àwọn èèyàn náà! Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo sì ṣe ohun tí kò dáa;+ àmọ́ kí ni àwọn àgùntàn yìí ṣe? Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀ọ́, èmi àti ilé bàbá mi ni kí o gbé ọwọ́ rẹ sókè sí; má ṣe mú àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn èèyàn rẹ.”+
18 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà ní kí Gádì+ sọ fún Dáfídì pé kó lọ ṣé pẹpẹ kan fún Jèhófà ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì.+
19 Torí náà, Dáfídì lọ ṣe ohun tí Gádì sọ, èyí tó sọ fún un ní orúkọ Jèhófà.
20 Lákòókò yìí, Ọ́nánì bojú wẹ̀yìn, ó rí áńgẹ́lì náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì fara pa mọ́. Nígbà yẹn, Ọ́nánì ń pa ọkà àlìkámà.*
21 Nígbà tí Dáfídì dé ọ̀dọ̀ Ọ́nánì, Ọ́nánì gbójú sókè, ó sì rí Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kúrò ní ibi ìpakà náà, ó tẹrí ba fún Dáfídì, ó sì dojú bolẹ̀.
22 Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Ta* ilẹ̀ tó wá ní ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà. Iye tó bá jẹ́ ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn yìí lè dáwọ́ dúró.”+
23 Ṣùgbọ́n Ọ́nánì sọ fún Dáfídì pé: “Máa mú un, kí olúwa mi ọba ṣe ohun tó bá rí pé ó dára.* Mo tún fi màlúù sílẹ̀ fún àwọn ẹbọ sísun àti ohun èlò ìpakà+ láti fi ṣe igi ìdáná àti àlìkámà* fún ọrẹ ọkà. Gbogbo rẹ̀ ni mo fi sílẹ̀.”
24 Àmọ́, Ọba Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Rárá o, iye tó bá jẹ́ ni màá rà á, torí mi ò ní gba ohun tó jẹ́ tìrẹ kì n sì fún Jèhófà tàbí kí n fi rú àwọn ẹbọ sísun láìná nǹkan kan.”+
25 Nítorí náà, Dáfídì fún Ọ́nánì ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì* wúrà fún ilẹ̀ náà.
26 Dáfídì mọ pẹpẹ kan+ síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ẹni tó wá fi iná dá a lóhùn+ láti ọ̀run sórí pẹpẹ ẹbọ sísun náà.
27 Lẹ́yìn náà, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì+ náà pé kí ó dá idà rẹ̀ pa dà sínú àkọ̀ rẹ̀.
28 Lákòókò yẹn, nígbà tí Dáfídì rí i pé Jèhófà ti dá òun lóhùn ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì, ó ń rúbọ níbẹ̀ nìṣó.
29 Àgọ́ ìjọsìn Jèhófà tí Mósè ṣe ní aginjù àti pẹpẹ ẹbọ sísun ṣì wà ní ibi gíga Gíbíónì+ ní àkókò yẹn.
30 Àmọ́ Dáfídì kò tíì lọ síwájú rẹ̀ láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ẹ̀rù idà áńgẹ́lì Jèhófà ń bà á.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “alátakò.”
^ Tàbí “kẹ́dùn.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Ní Héb., “Fi.”
^ Ní Héb., “ohun tó bá dára lójú rẹ̀.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.