Kíróníkà Kìíní 26:1-32
26 Bí wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ́bodè+ nìyí: nínú àwọn ọmọ Kórà, Meṣelemáyà+ ọmọ Kórè látinú àwọn ọmọ Ásáfù.
2 Meṣelemáyà ní àwọn ọmọkùnrin: Sekaráyà ni àkọ́bí, Jédáélì ìkejì, Sebadáyà ìkẹta, Játíníélì ìkẹrin,
3 Élámù ìkarùn-ún, Jèhóhánánì ìkẹfà, Elieho-énáì ìkeje.
4 Obedi-édómù ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣemáyà ni àkọ́bí, Jèhósábádì ìkejì, Jóà ìkẹta, Sákà ìkẹrin, Nétánélì ìkarùn-ún,
5 Ámíélì ìkẹfà, Ísákà ìkeje àti Péúlétáì ìkẹjọ; nítorí pé Ọlọ́run bù kún un.
6 Wọ́n bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣemáyà ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ náà di olórí agbo ilé bàbá wọn nítorí wọ́n jẹ́ akíkanjú àti ọ̀jáfáfá ọkùnrin.
7 Àwọn ọmọkùnrin Ṣemáyà ni: Ótínì, Réfáélì, Óbédì àti Élísábádì; àwọn arákùnrin rẹ̀ Élíhù àti Semakáyà náà jẹ́ ọ̀jáfáfá.
8 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Obedi-édómù; àwọn àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá, wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ ìsìn náà, méjìlélọ́gọ́ta (62) jẹ́ ti Obedi-édómù.
9 Meṣelemáyà+ ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin, àwọn méjìdínlógún (18) tó jẹ́ ọ̀jáfáfá.
10 Hósà látinú àwọn ọmọ Mérárì ní àwọn ọmọkùnrin. Ṣímúrì ni olórí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun kọ́ ni àkọ́bí, bàbá rẹ̀ yàn án ṣe olórí,
11 Hilikáyà ìkejì, Tebaláyà ìkẹta, Sekaráyà ìkẹrin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti àwọn arákùnrin Hósà jẹ́ mẹ́tàlá (13).
12 Nínú àwọn àwùjọ tí a pín àwọn aṣọ́bodè yìí sí, bí àwọn olórí ṣe ní iṣẹ́ ni àwọn arákùnrin wọn náà ṣe ní iṣẹ́, láti máa ṣe ìránṣẹ́ ní ilé Jèhófà.
13 Torí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké+ fún ẹni kékeré bí wọ́n ṣe ṣẹ́ ẹ fún ẹni ńlá ní agbo ilé bàbá wọn, fún ẹnubodè kọ̀ọ̀kan.
14 Nígbà náà, kèké tí wọ́n ṣẹ́ fún ẹnubodè ìlà oòrùn jáde fún Ṣelemáyà. Wọ́n ṣẹ́ kèké náà fún Sekaráyà ọmọ rẹ̀, agbani-nímọ̀ràn tó lóye, kèké rẹ̀ sì mú àríwá.
15 Kèké Obedi-édómù mú gúúsù, a sì yan àwọn ilé ìkẹ́rùsí fún àwọn ọmọ rẹ̀.+
16 Kèké Ṣúpímù àti Hósà+ mú ìwọ̀ oòrùn nítòsí Ẹnubodè Ṣálékétì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tó lọ sókè, àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ kan sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ míì;
17 àwọn ọmọ Léfì mẹ́fà ló wà lápá ìlà oòrùn; mẹ́rin lápá àríwá fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti mẹ́rin lápá gúúsù fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan; àwọn méjì-méjì sì wà ní àwọn ilé ìkẹ́rùsí;+
18 fún ọ̀nà olórùlé tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹ́rin wà ní ojú ọ̀nà,+ àwọn méjì sì wà ní ọ̀nà olórùlé náà.
19 Bí wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ́bodè náà nìyẹn látinú àwọn ọmọ Kórà àti àwọn ọmọ Mérárì.
20 Ní ti àwọn ọmọ Léfì, Áhíjà ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́ àti àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di* mímọ́+ sí.
21 Àwọn ọmọ Ládánì nìyí: àwọn ọmọkùnrin látinú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì tí Ládánì bí, àwọn olórí agbo ilé Ládánì ọmọ Gẹ́ṣónì, Jẹ́híélì+
22 àti àwọn ọmọ Jẹ́híélì, Sétámù àti Jóẹ́lì arákùnrin rẹ̀. Àwọn ló ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà.+
23 Látinú àwọn ọmọ Ámúrámù, àwọn ọmọ Ísárì, àwọn ọmọ Hébúrónì àti àwọn ọmọ Úsíélì,+
24 Ṣẹ́búẹ́lì ọmọ Gẹ́ṣómù ọmọ Mósè jẹ́ aṣáájú tó ń bójú àwọn ilé ìkẹ́rùsí.
25 Àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Élíésérì+ ni Rehabáyà,+ Jeṣáyà, Jórámù, Síkírì àti Ṣẹ́lómótì.
26 Ṣẹ́lómótì yìí àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ló ń bójú tó gbogbo àwọn ibi ìṣúra tí wọ́n ń kó àwọn ohun tí a sọ di mímọ́+ sí, tí Ọba Dáfídì+ àti àwọn olórí agbo ilé+ àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú àwọn olórí ọmọ ogun ti sọ di mímọ́.
27 Lára àwọn ẹrù + tí wọ́n kó lójú ogun,+ wọ́n ya àwọn ohun kan sí mímọ́ láti máa fi tọ́jú ilé Jèhófà;
28 bákan náà ni gbogbo ohun tí Sámúẹ́lì aríran,+ Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ sọ di mímọ́. Ohun tí ẹnikẹ́ni bá sọ di mímọ́ ni wọ́n ń fi sí abẹ́ àbójútó Ṣẹ́lómítì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.
29 Nínú àwọn ọmọ Ísárì,+ wọ́n fún Kenanáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní iṣẹ́ àmójútó ní ìta láti jẹ́ aláṣẹ àti onídàájọ́+ lórí Ísírẹ́lì.
30 Nínú àwọn ọmọ Hébúrónì,+ Haṣabáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀jáfáfá, ni wọ́n ń bójú tó Ísírẹ́lì ní ìwọ̀ oòrùn agbègbè Jọ́dánì láti máa ṣe gbogbo iṣẹ́ Jèhófà àti iṣẹ́ ọba.
31 Nínú àwọn ọmọ Hébúrónì, Jéríjà+ ni olórí àwọn ọmọ Hébúrónì bí ìran wọn ṣe tẹ̀ léra nínú agbo ilé bàbá wọn. Ní ogójì ọdún ìjọba Dáfídì,+ wọ́n wá àwọn akíkanjú àti ọ̀jáfáfá ọkùnrin, wọ́n sì rí láàárín àwọn ọmọ Hébúrónì ní Jásérì+ ní Gílíádì.
32 Àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá àti olórí nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-un méje (2,700). Torí náà, Ọba Dáfídì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì pẹ̀lú ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè, láti máa bójú tó gbogbo ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́ àti ti ọba.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “yà sí.”