Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 5:1-13
5 Ní tòótọ́, wọ́n ròyìn ìṣekúṣe*+ tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín, irú ìṣekúṣe* bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ń fẹ́* ìyàwó bàbá rẹ̀.+
2 Ṣé ẹ wá ń fìyẹn yangàn ni? Ṣé kì í ṣe pé ó yẹ kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀+ kí a lè mú ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí kúrò láàárín yín?+
3 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa tara, mo wà lọ́dọ̀ yín nípa tẹ̀mí, mo sì ti ṣèdájọ́ ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí, bíi pé èmi fúnra mi wà lọ́dọ̀ yín.
4 Nígbà tí ẹ bá pé jọ ní orúkọ Olúwa wa Jésù, tí ẹ sì mọ̀ pé mo wà pẹ̀lú yín nípa tẹ̀mí nínú agbára Olúwa wa Jésù,
5 kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́+ kí agbára ẹ̀ṣẹ̀ náà lè pa run, kí ipò tẹ̀mí ìjọ lè wà láìyingin ní ọjọ́ Olúwa.+
6 Bí ẹ ṣe ń fọ́nnu yìí kò dáa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú ni?+
7 Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè di ìṣùpọ̀ tuntun, tí kò bá ti sí amóhunwú nínú yín. Torí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá wa+ rúbọ.+
8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àjọyọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, àmọ́ ká ṣe é pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú ti òótọ́ inú àti ti òtítọ́.
9 Nínú lẹ́tà tí mo kọ sí yín, mo ní kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́* pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe,*
10 àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn oníṣekúṣe* ayé yìí+ tàbí àwọn olójúkòkòrò tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà ni mò ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, á di pé kí ẹ kúrò nínú ayé.+
11 Ṣùgbọ́n ní báyìí mò ń kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́*+ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, àmọ́ tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí olójúkòkòrò+ tàbí abọ̀rìṣà tàbí pẹ̀gànpẹ̀gàn* tàbí ọ̀mùtípara+ tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà,+ kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12 Torí kí ló kàn mí pẹ̀lú ṣíṣèdájọ́ àwọn tó wà lóde? Ṣebí àwọn tó wà nínú ìjọ lẹ̀ ń dá lẹ́jọ́,
13 nígbà tí Ọlọ́run ń dá àwọn tó wà lóde lẹ́jọ́?+ “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ń gbé pẹ̀lú.”
^ Tàbí “dídarapọ̀.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Tàbí “dídarapọ̀.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
^ Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”