Àwọn Ọba Kejì 11:1-21
11 Nígbà tí Ataláyà,+ ìyá Ahasáyà rí i pé ọmọ òun ti kú,+ ó dìde, ó sì pa gbogbo ìdílé ọba* run.+
2 Àmọ́, Jèhóṣébà ọmọbìnrin Ọba Jèhórámù, arábìnrin Ahasáyà, gbé Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà, ó jí i gbé láàárín àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, ó fi òun àti obìnrin tó ń tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. Wọ́n sì rọ́nà fi í pa mọ́ kí Ataláyà má bàa rí i, torí náà kò rí i pa.
3 Ọdún mẹ́fà ló fi wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé Jèhófà nígbà tí Ataláyà ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.
4 Ní ọdún keje, Jèhóádà ránṣẹ́ sí àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀ṣọ́ Káríà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin,*+ ó ní kí wọ́n wá bá òun ní ilé Jèhófà. Ó bá wọn ṣe àdéhùn,* ó sì ní kí wọ́n búra sí i ní ilé Jèhófà, lẹ́yìn náà ó fi ọmọ ọba hàn wọ́n.+
5 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta yín á wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì, ẹ ó sì máa ṣọ́ ilé* ọba+ lójú méjèèjì,
6 ìdá mẹ́ta míì á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, ìdá mẹ́ta míì á sì wà ní ẹnubodè tó wà lẹ́yìn àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin. Kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ ṣíṣọ́ ilé náà ní àṣegbà.
7 Ìdá méjì tí kò ní sí lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì ní láti máa ṣọ́ ilé Jèhófà lójú méjèèjì láti dáàbò bo ọba.
8 Kí ẹ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú àwọn ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹni tó bá wọlé wá sáàárín àwọn ọmọ ogun ni a ó pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*
9 Àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ṣe ohun tí àlùfáà Jèhóádà pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Torí náà, kálukú mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì pẹ̀lú àwọn tí kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Jèhóádà.+
10 Àlùfáà wá fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní àwọn ọ̀kọ̀ àti apata* tó jẹ́ ti Ọba Dáfídì, tó wà ní ilé Jèhófà.
11 Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin+ wà ní ìdúró, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, gbogbo wọn yí ọba ká.
12 Lẹ́yìn náà Jèhóádà mú ọmọ ọba+ jáde, ó fi adé* dé e, ó si fi Ẹ̀rí*+ sí i lórí, wọ́n fi jọba, wọ́n sì fòróró yàn án. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́, wọ́n sì ń sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”+
13 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn èèyàn tó ń sáré, ní kíá, ó lọ bá àwọn èèyàn tó wà ní ilé Jèhófà.+
14 Ó wá rí ọba níbẹ̀ tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn ọba.+ Àwọn olórí àti àwọn tó ń fun kàkàkí+ wà lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, wọ́n sì ń fun kàkàkí. Ni Ataláyà bá fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ọ̀tẹ̀ rèé o! Ọ̀tẹ̀ rèé o!”
15 Àmọ́ àlùfáà Jèhóádà pàṣẹ fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn tí a yàn ṣe olórí ọmọ ogun, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un kúrò láàárín àwọn ọmọ ogun, tí ẹnikẹ́ni bá sì tẹ̀ lé e, kí ẹ fi idà pa á!” Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Ẹ má ṣe pa á ní ilé Jèhófà.”
16 Torí náà, wọ́n mú un, nígbà tó sì dé ibi tí ẹṣin ti máa ń wọ ilé* ọba,+ wọ́n pa á níbẹ̀.
17 Lẹ́yìn náà, Jèhóádà dá májẹ̀mú láàárín Jèhófà àti ọba àti àwọn èèyàn náà,+ pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó, ó sì tún dá májẹ̀mú láàárín ọba àti àwọn èèyàn náà.+
18 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà wá sí ilé* Báálì, wọ́n wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀,+ wọ́n fọ́ àwọn ère rẹ̀ túútúú,+ wọ́n sì pa Mátánì àlùfáà Báálì+ níwájú àwọn pẹpẹ náà.
Àlùfáà wá yan àwọn alábòójútó lórí ilé Jèhófà.+
19 Yàtọ̀ síyẹn, ó kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn ẹ̀ṣọ́ Káríà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin+ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kí wọ́n lè tẹ̀ lé ọba láti ilé Jèhófà, wọ́n sì gba ọ̀nà ẹnubodè ẹ̀ṣọ́ ààfin wá sí ilé* ọba. Ó wá jókòó sórí ìtẹ́ ọba.+
20 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, ìlú náà sì tòrò, nítorí pé wọ́n ti pa* Ataláyà ní ilé ọba.
21 Ọmọ ọdún méje ni Jèhóáṣì+ nígbà tó jọba.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “gbogbo èso ìjọba.”
^ Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
^ Tàbí “dá májẹ̀mú.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Ní Héb., “nígbà tó bá jáde àti nígbà tó bá wọlé.”
^ Tàbí “apata ribiti.”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé tí Òfin Ọlọ́run wà nínú rẹ̀.
^ Tàbí “dáyádémà.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Ní Héb., “fi idà pa.”