Àwọn Ọba Kejì 2:1-25
2 Nígbà tó kù díẹ̀ tí Jèhófà máa fi ìjì+ gbé Èlíjà+ lọ sí ọ̀run,* Èlíjà àti Èlíṣà+ jáde kúrò ní Gílígálì.+
2 Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Bẹ́tẹ́lì.” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+
3 Ìgbà náà ni àwọn ọmọ wòlíì* ní Bẹ́tẹ́lì jáde wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?”+ Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”
4 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀ọ́ dúró sí ibí yìí, nítorí pé, Jèhófà ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Jẹ́ríkò.
5 Àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”
6 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Jọ́dánì.” Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ.
7 Bákan náà, àádọ́ta (50) lára àwọn ọmọ wòlíì jáde lọ, wọ́n dúró lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń wo àwọn méjèèjì bí wọ́n ṣe dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì.
8 Nígbà náà, Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀,+ ó ká a, ó sì lu omi náà, ó pín sápá ọ̀tún àti sápá òsì, tó fi jẹ́ pé àwọn méjèèjì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá.+
9 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọdá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí Ọlọ́run tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní ìpín*+ méjì nínú ẹ̀mí rẹ.”+
10 Ó fèsì pé: “Ohun tí o béèrè yìí kò rọrùn. Tí o bá rí mi nígbà tí Ọlọ́run bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, á rí bẹ́ẹ̀ fún ọ; àmọ́ tí o ò bá rí mi, kò ní rí bẹ́ẹ̀.”
11 Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná àti àwọn ẹṣin oníná+ ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀, ìjì sì gbé Èlíjà lọ sí ọ̀run.*+
12 Bí Èlíṣà ṣe ń wò ó, ó ké jáde pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ Nígbà tí kò rí i mọ́, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+
13 Lẹ́yìn náà, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó pa dà, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí odò Jọ́dánì.
14 Ló bá mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó fi lu omi náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Nígbà tó lu omi náà, ó pín sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, tí Èlíṣà fi lè sọdá.+
15 Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí Èlíjà ti bà lé Èlíṣà.”+ Torí náà, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀.
16 Wọ́n sọ fún un pé: “Àádọ́ta (50) géńdé ọkùnrin wà níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ẹ̀mí* Jèhófà gbé e, orí ọ̀kan nínú àwọn òkè tàbí àwọn àfonífojì ni ó jù ú sí.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ má ṣe rán wọn.”
17 Síbẹ̀, wọ́n ń rọ̀ ọ́ ṣáá títí ó fi sú u, torí náà ó ní: “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n wá rán àádọ́ta (50) ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sì fi wá a, ṣùgbọ́n wọn ò rí i.
18 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣì wà ní Jẹ́ríkò.+ Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé mi ò sọ fún yín pé kí ẹ má lọ?”
19 Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún Èlíṣà pé: “Ọ̀gá wa, bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ibi tí ìlú yìí wà dáa;+ àmọ́ omi rẹ̀ kò dáa, ilẹ̀ rẹ̀ sì ti ṣá.”*
20 Ló bá sọ pé: “Ẹ mú abọ́ kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì bu iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n gbé e wá fún un.
21 Ó wá lọ sí orísun omi náà, ó da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mo ti wo omi yìí sàn. Kò ní fa ikú, kò sì ní sọni di àgàn* mọ́.’”
22 Ìwòsàn sì bá omi náà títí di òní yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà sọ.
23 Ó gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọkùnrin kan jáde wá láti inú ìlú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń sọ fún un pé: “Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!”
24 Níkẹyìn, ó bojú wẹ̀yìn, ó wò wọ́n, ó sì gégùn-ún fún wọn ní orúkọ Jèhófà. Ni abo bíárì+ méjì bá jáde láti inú igbó, wọ́n sì fa méjìlélógójì (42) lára àwọn ọmọ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+
25 Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Òkè Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó pa dà sí Samáríà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “sánmà.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ “Àwọn ọmọ wòlíì” ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn wòlíì ti ń gba ìtọ́ni tàbí ẹgbẹ́ àwọn wòlíì.
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “apá.”
^ Tàbí “sánmà.”
^ Tàbí “ìjì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ń ba oyún jẹ́.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kò sì ní ba oyún jẹ́.”