Àwọn Ọba Kejì 7:1-20
7 Nígbà náà, Èlíṣà sọ pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n síà* ìyẹ̀fun kíkúnná yóò di ṣékélì* kan, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì yóò sì di ṣékélì kan ní ẹnubodè* Samáríà.’”+
2 Ni olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tí ọba fọkàn tán bá dá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn pé: “Ká tiẹ̀ ní Jèhófà ṣí ibú omi ojú ọ̀run sílẹ̀, ṣé irú nǹkan* yìí lè ṣẹlẹ̀?”+ Èlíṣà dáhùn pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i,+ ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.”+
3 Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rin kan wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè ìlú,+ wọ́n sì sọ fún ara wọn pé: “Kí nìdí tí a fi máa jókòó síbí títí a ó fi kú?
4 Tí a bá ní ká wọnú ìlú nígbà tí ìyàn ṣì mú nínú ìlú,+ ibẹ̀ la máa kú sí. Tí a bá sì jókòó síbí, a ṣì máa kú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà. Tí wọ́n bá dá ẹ̀mí wa sí, a ò ní kú, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pa wá, a kú náà nìyẹn.”
5 Ni wọ́n bá dìde nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, wọ́n sì wọ ibùdó àwọn ará Síríà. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀yìn ibùdó àwọn ará Síríà, kò sí ẹnì kankan níbẹ̀.
6 Jèhófà ti mú kí ibùdó àwọn ará Síríà gbọ́ ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ìró àwọn ẹṣin àti ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun.+ Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wò ó! Ọba Ísírẹ́lì ti háyà àwọn ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Íjíbítì láti wá gbéjà kò wá!”
7 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n dìde, wọ́n sì sá lọ nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, wọ́n fi àwọn àgọ́ wọn àti àwọn ẹṣin wọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, gbogbo ibùdó náà wà bó ṣe wà, wọ́n sì sá lọ nítorí ẹ̀mí* wọn.
8 Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ yìí dé ẹ̀yìn ibùdó náà, wọ́n wọnú àgọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń mu. Wọ́n kó fàdákà, wúrà àti aṣọ láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ kó wọn pa mọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà wá, wọ́n wọnú àgọ́ míì, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ kó wọn pa mọ́.
9 Níkẹyìn, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára. Ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ lọjọ́ òní! Tí a bá dákẹ́, tí a sì dúró títí ilẹ̀ á fi mọ́, ìyà máa tọ́ sí wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ ròyìn nǹkan yìí ní ilé ọba.”
10 Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n pe àwọn aṣọ́bodè ìlú náà, wọ́n sì ròyìn fún wọn pé: “A wọnú ibùdó àwọn ará Síríà, àmọ́ kò sí ẹnì kankan níbẹ̀, a ò gbọ́ ìró èèyàn kankan. Àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ àti àwọn àgọ́ tó wà bí wọ́n ṣe wà nìkan la rí.”
11 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn aṣọ́bodè lọ ròyìn fún àwọn tó wà ní ilé ọba.
12 Ní kíá, ọba dìde lóru, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí àwọn ará Síríà fẹ́ ṣe sí wa fún yín. Wọ́n mọ̀ pé ebi ń pa wá,+ torí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kúrò ní ibùdó láti lọ fara pa mọ́ ní pápá, wọ́n sọ pé, ‘Wọ́n máa jáde kúrò nínú ìlú, a ó mú wọn láàyè, a ó sì wọnú ìlú náà.’”+
13 Ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí àwọn ọkùnrin kan mú márùn-ún lára àwọn ẹṣin tó ṣẹ́ kù nínú ìlú. Wò ó! Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù síbí náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àbí kó jẹ́ pé, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ti kú náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Torí náà, jẹ́ ká rán wọn, ká sì wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀.”
14 Torí náà, wọ́n mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin méjì pẹ̀lú àwọn ẹṣin, ọba sì rán wọn lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà, ó sọ pé: “Ẹ lọ wò ó.”
15 Wọ́n tẹ̀ lé wọn títí dé Jọ́dánì, àwọn ẹ̀wù àti àwọn nǹkan èlò tí àwọn ará Síríà jù dà nù bí wọ́n ṣe ń sá lọ kíjokíjo kún gbogbo ojú ọ̀nà. Àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà, wọ́n sì ròyìn fún ọba.
16 Àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó àwọn nǹkan tó wà ní ibùdó àwọn ará Síríà, tó fi jẹ́ pé òṣùwọ̀n síà ìyẹ̀fun kíkúnná di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì sì di ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
17 Ọba ti yan olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tó fọkàn tán, láti máa bójú tó ẹnubodè, àmọ́ àwọn èèyàn náà tẹ̀ ẹ́ pa ní ẹnubodè, bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ fún ọba nígbà tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
18 Ọ̀rọ̀ náà ṣẹ gẹ́lẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ fún ọba pé: “Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì yóò di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n síà ìyẹ̀fun kíkúnná yóò sì di ṣékélì kan ní ẹnubodè Samáríà.”+
19 Àmọ́ ohun tí olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni pé: “Ká tiẹ̀ ní Jèhófà ṣí ibú omi ojú ọ̀run sílẹ̀, ṣé irú nǹkan* yìí lè ṣẹlẹ̀?” Èlíṣà sì fún un lésì pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i, ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.”
20 Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sí i gan-an nìyẹn, torí pé àwọn èèyàn náà tẹ̀ ẹ́ pa ní ẹnubodè.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ọjà.”
^ Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”