Kíróníkà Kejì 10:1-19
-
Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Rèhóbóámù (1-19)
10 Rèhóbóámù lọ sí Ṣékémù,+ nítorí gbogbo Ísírẹ́lì ti wá sí Ṣékémù láti fi í jọba.+
2 Gbàrà tí Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì gbọ́ (ó ṣì wà ní Íjíbítì torí ó ti sá lọ nítorí Ọba Sólómọ́nì),+ Jèróbóámù pa dà wá láti Íjíbítì.
3 Lẹ́yìn náà, wọ́n ránṣẹ́ pe Jèróbóámù, òun àti gbogbo Ísírẹ́lì sì wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sọ pé:
4 “Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo.+ Àmọ́ tí o bá mú kí iṣẹ́ tó nira tí bàbá rẹ fún wa rọ̀ wá lọ́rùn, tí o sì mú kí àjàgà tó wúwo* tó fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́, a ó máa sìn ọ́.”
5 Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà wá bá mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Torí náà, àwọn èèyàn náà lọ.+
6 Ọba Rèhóbóámù wá fọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbà ọkùnrin* tó bá Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó wà láàyè, ó ní: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn yìí?”
7 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Tí o bá ṣe dáadáa sí àwọn èèyàn yìí, tí o ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, tí o sì fún wọn ní èsì rere, ìwọ ni wọ́n á máa sìn títí lọ.”
8 Àmọ́, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un, ó sì fọ̀rọ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà, àmọ́ tí wọ́n ti di ẹmẹ̀wà* rẹ̀ báyìí.+
9 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ẹ gbà mí nímọ̀ràn, èsì wo ni ká fún àwọn èèyàn tó sọ fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí bàbá rẹ fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́’?”
10 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ dàgbà sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí o máa sọ fún àwọn èèyàn tó sọ fún ọ pé, ‘Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo, ṣùgbọ́n mú kí ó fúyẹ́ lọ́rùn wa’; ohun tí wàá sọ fún wọn ni pé, ‘Ọmọ ìka ọwọ́ mi tó kéré jù* yóò nípọn ju ìbàdí bàbá mi lọ.
11 Bàbá mi fi àjàgà tó wúwo kọ́ yín lọ́rùn, àmọ́ ńṣe ni màá fi kún àjàgà yín. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.’”
12 Jèróbóámù àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá bá Rèhóbóámù ní ọjọ́ kẹta, bí ọba ṣe sọ pé: “Ẹ pa dà wá bá mi ní ọjọ́ kẹta.”+
13 Àmọ́, ńṣe ni ọba jágbe mọ́ wọn. Bí Ọba Rèhóbóámù kò ṣe gba ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin* fún un nìyẹn.
14 Ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin fún un ló tẹ̀ lé, ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Màá mú kí àjàgà yín wúwo sí i, màá sì tún fi kún un. Pàṣán ni bàbá mi fi nà yín, ṣùgbọ́n kòbókò oníkókó ni màá fi nà yín.”
15 Nítorí náà, ọba ò fetí sí àwọn èèyàn náà, torí pé Ọlọ́run tòótọ́+ ló mú kí ìyípadà náà wáyé, kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè ṣẹ, èyí tó gbẹnu Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sọ fún Jèróbóámù ọmọ Nébátì.
16 Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, torí pé ọba ò gbọ́ tiwọn, àwọn èèyàn náà fún ọba lésì pé: “Kí ló pa àwa àti Dáfídì pọ̀? A ò ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè. Ìwọ Ísírẹ́lì, kí kálukú lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run rẹ̀. Ìwọ Dáfídì,+ máa mójú tó ilé ara rẹ!” Bí gbogbo Ísírẹ́lì ṣe pa dà sí ilé* wọn nìyẹn.+
17 Àmọ́ Rèhóbóámù ń jọba nìṣó lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà.+
18 Lẹ́yìn náà, Ọba Rèhóbóámù rán Hádórámù,+ ẹni tó jẹ́ olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Agbára káká ni Ọba Rèhóbóámù fi rọ́nà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti sá lọ sí Jerúsálẹ́mù.+
19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dáfídì títí di òní yìí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tó nira.”
^ Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
^ Tàbí “ìránṣẹ́.”
^ Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
^ Tàbí “ọmọńdinrín mi.”
^ Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
^ Ní Héb., “àgọ́.”