Kíróníkà Kejì 2:1-18

  • Ìmúrasílẹ̀ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-18)

2  Sólómọ́nì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà,+ kí wọ́n sì kọ́ ilé* kan fún ìjọba òun.+  Sólómọ́nì yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) ọkùnrin láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta ní àwọn òkè+ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó wọn.+  Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì ránṣẹ́ sí Hírámù+ ọba Tírè pé: “Ohun tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi nígbà tí o kó igi kédárì ránṣẹ́ sí i láti fi kọ́ ilé* tí á máa gbé ni kí o ṣe fún mi.+  Ní báyìí, mo fẹ́ kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, láti yà á sí mímọ́ fún un, láti máa sun tùràrí onílọ́fínńdà+ níwájú rẹ̀ àti láti máa kó búrẹ́dì onípele* síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà+ àti àwọn ẹbọ sísun ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́,+ ní àwọn Sábáàtì,+ ní àwọn òṣùpá tuntun+ àti ní àwọn àsìkò àjọyọ̀+ Jèhófà Ọlọ́run wa. Ohun tí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn títí láé.  Ilé tí mo fẹ́ kọ́ náà máa tóbi, nítorí Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run míì lọ.  Ta ni agbára rẹ̀ gbé e láti kọ́ ilé fún un? Nítorí àwọn ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò lè gbà á,+ ta wá ni mí tí màá fi kọ́ ilé fún un? Àfi kí n kàn kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ó ti máa mú ẹbọ rú èéfín níwájú rẹ̀.  Ní báyìí, fi ọkùnrin oníṣẹ́ ọnà kan ránṣẹ́ sí mi, tó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà,+ irin, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, tó sì mọ bí a ti ń fín àwọn iṣẹ́ ọnà. Ó máa ṣiṣẹ́ ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà mi tó já fáfá, àwọn tí Dáfídì bàbá mi ti pèsè sílẹ̀.+  Kí o kó àwọn gẹdú igi kédárì, ti igi júnípà+ àti ti igi álígọ́mù+ láti Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí mi, nítorí mo mọ̀ dáadáa pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ mọ bí a ṣe ń gé àwọn igi Lẹ́bánónì.+ Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́+  láti pèsè gẹdú tó pọ̀ gan-an sílẹ̀ fún mi, nítorí ilé tí mo fẹ́ kọ́ máa tóbi yàtọ̀. 10  Wò ó! Màá pèsè oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+ àwọn agégi tó máa gé igi náà, màá fún wọn ní: ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà,* ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ọkà bálì, ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì* wáìnì àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) báàtì òróró.” 11  Hírámù ọba Tírè wá kọ̀wé ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó fi ọ́ ṣe ọba wọn.” 12  Hírámù sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, nítorí ó ti fún Ọba Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ+ tó ní làákàyè àti òye,+ tó máa kọ́ ilé fún Jèhófà àti fún ìjọba òun fúnra rẹ̀. 13  Wò ó, mo ti rán ọkùnrin ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà kan sí ọ, ó ní òye, Hiramu-ábì+ ni orúkọ rẹ̀, 14  ó jẹ́ ọmọ obìnrin kan tó wá látinú ẹ̀yà Dánì, àmọ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ará Tírè; ó já fáfá nínú iṣẹ́ ọnà wúrà, fàdákà, bàbà, irin, òkúta, igi gẹdú, òwú aláwọ̀ pọ́pù, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, aṣọ àtàtà àti aṣọ rírẹ̀dòdò.+ Ó lè fín oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà, ó sì lè ṣe iṣẹ́ ọnà èyíkéyìí tí wọ́n bá fún un.+ Ó máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà rẹ àti àwọn ọ̀jáfáfá oníṣẹ́ ọnà olúwa mi Dáfídì bàbá rẹ. 15  Ní báyìí, kí olúwa mi fi àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti wáìnì tó ṣèlérí ránṣẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 16  A máa gé àwọn igi láti Lẹ́bánónì,+ bí èyí tí o nílò bá ṣe pọ̀ tó, a ó kó wọn wá sọ́dọ̀ rẹ ní àdìpọ̀ igi tó léfòó, a ó sì kó wọn gba orí òkun wá sí Jópà;+ wàá sì kó wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù.”+ 17  Sólómọ́nì wá ka gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn ìkànìyàn tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ṣe,+ iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́tà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (153,600). 18  Nítorí náà, ó yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lára wọn láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta+ ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó tí á máa kó àwọn èèyàn ṣiṣẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ààfin.”
Tàbí “láti máa ru ẹrù.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Báàtì kan jẹ́ Lítà 22 (gálọ́ọ̀nù 5.81). Wo Àfikún B14.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “láti máa ru ẹrù.”