Kíróníkà Kejì 25:1-28
25 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Amasááyà nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jèhóádánì láti Jerúsálẹ́mù.+
2 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.
3 Nígbà tí ìjọba rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ọba.+
4 Àmọ́ kò pa àwọn ọmọ wọn, torí pé ó ṣe ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin, nínú ìwé Mósè, níbi tí Jèhófà ti pàṣẹ pé: “Àwọn bàbá kò gbọ́dọ̀ kú nítorí àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ kò gbọ́dọ̀ kú nítorí àwọn bàbá; kí kálukú kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.”+
5 Amasááyà wá kó gbogbo Júdà jọ, ó sì ní kí wọ́n dúró ní agboolé-agboolé, sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì.+ Ó forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ ó rí i pé wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) akọgun* tó ń ṣiṣẹ́ ológun, tí wọ́n sì lè lo aṣóró àti apata ńlá.
6 Bákan náà, ó fi ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà háyà ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) jagunjagun tó lákíkanjú láti Ísírẹ́lì.
7 Àmọ́, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kan wá bá a, ó sì sọ pé: “Ọba, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì bá ọ lọ, torí Jèhófà kò sí lẹ́yìn Ísírẹ́lì,+ kò sí lẹ́yìn ìkankan lára àwọn ọmọ Éfúrémù.
8 Ìwọ fúnra rẹ ni kí o lọ, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe bí akin lójú ogun. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tòótọ́ lè mú kí o kọsẹ̀ níwájú ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ranni lọ́wọ́+ àti láti múni kọsẹ̀.”
9 Ni Amasááyà bá sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà pé: “Ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì tí mo wá fún àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ńkọ́?” Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà fèsì pé: “Jèhófà mọ bó ṣe máa fi èyí tó pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ san án fún ọ.”+
10 Torí náà, Amasááyà ní kí àwọn ọmọ ogun tó wá láti Éfúrémù máa lọ, pé kí wọ́n pa dà sí àyè wọn. Àmọ́, inú bí wọn gidigidi sí Júdà, wọ́n sì pa dà sí àyè wọn tìbínútìbínú.
11 Lẹ́yìn náà, Amasááyà mọ́kàn le, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀,+ ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára àwọn ọkùnrin Séírì.+
12 Àwọn ọkùnrin Júdà wá mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láàyè. Wọ́n kó wọn wá sí orí àpáta, wọ́n sì jù wọ́n láti orí àpáta náà, gbogbo wọn sì já jálajàla.
13 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun tí Amasááyà dá pa dà pé kí wọ́n má ṣe bá òun lọ sí ogun+ wá ń kó ẹrù àwọn tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà, láti Samáríà+ títí dé Bẹti-hórónì,+ wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹrù.
14 Ṣùgbọ́n, nígbà tí Amasááyà dé láti ibi tó ti lọ pa àwọn ọmọ Édómù, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Séírì wá, ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run fún ara rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í forí balẹ̀ níwájú wọn, ó sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí wọn.
15 Nítorí náà, Jèhófà bínú gan-an sí Amasááyà, ó sì rán wòlíì kan sí i tó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń sin àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tí kò gba àwọn èèyàn wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”+
16 Bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ọba sọ pé: “Ṣé a fi ọ́ ṣe agbani-nímọ̀ràn ọba ni?+ Dákẹ́!+ Àbí o fẹ́ kí wọ́n pa ọ́ ni?” Àmọ́, kí wòlíì náà tó dákẹ́, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò sì fetí sí ìmọ̀ràn mi.”+
17 Lẹ́yìn tí Amasááyà ọba Júdà fọ̀rọ̀ lọ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá, jẹ́ ká dojú ìjà kọ ara wa.”*+
18 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí igi kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kó fi ṣe aya.’ Àmọ́, ẹranko kan láti Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà pa.
19 Ò ń sọ pé, ‘Wò ó! Mo* ti ṣẹ́gun Édómù.’+ Torí bẹ́ẹ̀, ìgbéraga wọ̀ ẹ́ lẹ́wù, o sì fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbé ògo fún ọ. Àmọ́ ní báyìí, dúró sí ilé* rẹ. Kí ló dé tí wàá fi fa àjálù bá ara rẹ, tí wàá sì gbé ara rẹ àti Júdà ṣubú?”
20 Ṣùgbọ́n Amasááyà ò gbọ́,+ torí pé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ni èyí ti wá kí ó lè fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́,+ nítorí pé wọ́n sin àwọn ọlọ́run Édómù.+
21 Torí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, òun àti Amasááyà ọba Júdà sì dojú ìjà kọra ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì, + tó jẹ́ ti Júdà.
22 Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Júdà, kálukú sì sá lọ sí ilé* rẹ̀.
23 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú Amasááyà ọba Júdà, ọmọ Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì,* ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì. Lẹ́yìn náà, ó mú un wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù láti Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Igun,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbọ̀nwọ́.*
24 Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà pẹ̀lú gbogbo ohun èlò tó wà ní ilé Ọlọ́run tòótọ́ lọ́dọ̀* Obedi-édómù àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ àti àwọn tí wọ́n mú lóǹdè. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Samáríà.
25 Amasááyà+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí i lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.+
26 Ní ti ìyókù ìtàn Amasááyà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wò ó! ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì?
27 Láti ìgbà tí Amasááyà ti pa dà lẹ́yìn Jèhófà ni wọ́n ti ń dìtẹ̀+ mọ́ ọn ní Jerúsálẹ́mù, ó sì sá lọ sí Lákíṣì, àmọ́ wọ́n rán àwọn kan tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì pa á síbẹ̀.
28 Nítorí náà, wọ́n fi ẹṣin gbé e pa dà, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí ìlú Júdà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “jẹ́ ká wojú ara wa.”
^ Ní Héb., “O.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Ní Héb., “àgọ́.”
^ Nǹkan bíi mítà 178 (ẹsẹ̀ bàtà 584). Wo Àfikún B14.
^ Wọ́n tún ń pè é ní Ahasáyà.
^ Tàbí “lábẹ́ àbójútó.”
^ Tàbí “ààfin.”