Kíróníkà Kejì 5:1-14
5 Níkẹyìn, Sólómọ́nì parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà tó yẹ ní ṣíṣe.+ Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì kó àwọn ohun tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọlé,+ ó kó fàdákà, wúrà àti gbogbo ohun èlò wá sínú ibi ìṣúra ilé Ọlọ́run tòótọ́.+
2 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, gbogbo olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì. Wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ìlú Dáfídì,+ ìyẹn Síónì.+
3 Gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì pé jọ síwájú ọba nígbà àjọyọ̀* tí wọ́n ń ṣe ní oṣù keje.+
4 Nítorí náà, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, àwọn ọmọ Léfì sì gbé Àpótí náà.+
5 Wọ́n gbé Àpótí náà àti àgọ́ ìpàdé + wá pẹ̀lú gbogbo nǹkan èlò mímọ́ tó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì* ló gbé wọn wá.
6 Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn tó ní kí wọ́n pàdé òun, wà níwájú Àpótí náà. Àgùntàn àti màlúù tí wọ́n fi rúbọ+ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé kà, wọn ò sì níye.
7 Nígbà náà, àwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá sí àyè rẹ̀, ní yàrá inú lọ́hùn-ún ilé náà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ apá àwọn kérúbù.+
8 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde sórí ibi tí Àpótí náà wà, tó fi jẹ́ pé àwọn kérúbù náà bo Àpótí náà àti àwọn ọ̀pá rẹ̀+ láti òkè.
9 Àwọn ọ̀pá náà gùn débi pé a lè rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ ní iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún, ṣùgbọ́n a kò lè rí wọn láti òde. Wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.
10 Kò sí nǹkan míì nínú Àpótí náà àfi wàláà méjì tí Mósè kó sínú rẹ̀ ní Hórébù,+ nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú+ bí wọ́n ṣe ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì.+
11 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́ (nítorí gbogbo àwọn àlùfáà tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́,+ láìka àwùjọ tí wọ́n wà sí),+
12 gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin+ tí wọ́n jẹ́ ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì + àti ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn ló wọ aṣọ àtàtà, síńbálì* wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù; wọ́n dúró sí apá ìlà oòrùn pẹpẹ, àwọn pẹ̀lú ọgọ́fà (120) àlùfáà tó ń fun kàkàkí.+
13 Gbàrà tí àwọn tó ń fun kàkàkí àti àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà, tí wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ohùn tó ṣọ̀kan, tí ìró kàkàkí àti síńbálì pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin míì ń dún sókè bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé,”+ ni ìkùukùu+ bá kún inú ilé náà, ìyẹn ilé Jèhófà.
14 Àwọn àlùfáà kò lè dúró ṣe iṣẹ́ wọn nítorí ìkùukùu náà, torí pé ògo Jèhófà kún inú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+