Kíróníkà Kejì 6:1-42
6 Ní àkókò yẹn, Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà sọ pé inú ìṣúdùdù tó kàmàmà+ ni òun á máa gbé.
2 Ní báyìí, mo ti kọ́ ilé ológo kan fún ọ, ibi tó fìdí múlẹ̀ tí wàá máa gbé títí láé.”+
3 Lẹ́yìn náà, ọba yíjú pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, bí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ṣe wà ní ìdúró.+
4 Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó fi ẹnu ara rẹ̀ ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi, tó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un ṣẹ, tó sọ pé,
5 ‘Láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò yan ìlú kankan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí màá kọ́ ilé sí fún orúkọ mi, kí ó lè máa wà níbẹ̀,+ mi ò sì yan ọkùnrin kankan láti jẹ́ aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.
6 Ṣùgbọ́n mo ti yan Jerúsálẹ́mù+ kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀, mo sì ti yan Dáfídì láti ṣe olórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+
7 Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Dáfídì bàbá mi pé kí ó kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+
8 Àmọ́, Jèhófà sọ fún Dáfídì bàbá mi pé, ‘Ìfẹ́ ọkàn rẹ ni pé kí o kọ́ ilé fún orúkọ mi, ó sì dára bó ṣe ń wù ọ́ yìí.
9 Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé náà, ọmọ tí o máa bí* ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+
10 Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, torí mo ti jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì,+ bí Jèhófà ti ṣèlérí.+ Mo tún kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,
11 ibẹ̀ ni mo sì gbé Àpótí tí májẹ̀mú+ Jèhófà wà nínú rẹ̀ sí, èyí tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá.”
12 Ó wá dúró níwájú pẹpẹ Jèhófà ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ síwájú.+
13 (Sólómọ́nì ṣe pèpéle bàbà, ó sì gbé e sí àárín àgbàlá.*+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; ó sì dúró sórí rẹ̀.) Ó kúnlẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀run,+
14 ó wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tó dà bí rẹ ní ọ̀run tàbí ní ayé, ò ń pa májẹ̀mú mọ́, o sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tó ń fi gbogbo ọkàn+ wọn rìn níwájú rẹ.
15 O ti mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ.+ Ẹnu rẹ lo fi ṣe ìlérí náà, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú un ṣẹ lónìí yìí.+
16 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn nínú òfin mi+ bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+
17 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì ṣẹ.
18 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run á máa bá àwọn èèyàn gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+
19 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ.
20 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé wàá fi orúkọ rẹ sí,+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí.
21 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí,+ kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé, láti ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+
22 “Tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí+ nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà,
23 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o san ẹni burúkú lẹ́san, kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí,+ kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+
24 “Tí ọ̀tá bá ṣẹ́gun àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n sì pa dà wá, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga,+ tí wọ́n gbàdúrà,+ tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ nínú ilé yìí pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+
25 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run,+ kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jì wọ́n, kí o sì mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí o fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.+
26 “Nígbà tí ọ̀run bá sé pa, tí òjò kò sì rọ̀ + torí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí ọ,+ tí wọ́n wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí, tí wọ́n gbé orúkọ rẹ ga, tí wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé o rẹ̀ wọ́n wálẹ̀,*+
27 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, ìyẹn àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé wàá tọ́ wọn sí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa rìn;+ kí o sì rọ̀jò+ sórí ilẹ̀ rẹ tí o fún àwọn èèyàn rẹ láti jogún.
28 “Bí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ náà+ tàbí tí àjàkálẹ̀ àrùn+ bá jà, tí ooru tó ń jó ewéko gbẹ tàbí èbíbu+ bá wà, tí ọ̀wọ́ eéṣú tàbí ọ̀yánnú eéṣú*+ bá wà tàbí tí àwọn ọ̀tá wọn bá dó tì wọ́n ní ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ náà*+ tàbí tí ìyọnu èyíkéyìí tàbí àrùn bá wáyé,+
29 àdúrà+ èyíkéyìí tí ì báà jẹ́, ìbéèrè fún ojú rere+ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá béèrè tàbí èyí tí gbogbo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì bá béèrè (nítorí pé kálukú ló mọ ìṣòro rẹ̀ àti ìrora rẹ̀),+ tí wọ́n bá tẹ́ ọwọ́ wọn sí apá ibi tí ilé yìí wà,+
30 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé,+ kí o sì dárí jì wọ́n;+ kí o san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn rẹ̀ (ìwọ nìkan lo mọ ọkàn èèyàn),+
31 kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi gbé lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa.
32 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ ńlá rẹ*+ àti ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde, tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí,+
33 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.
34 “Tí àwọn èèyàn rẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà lójú ogun bí o ṣe rán wọn,+ tí wọ́n sì gbàdúrà + sí ọ ní ìdojúkọ ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+
35 nígbà náà, kí o gbọ́ àdúrà wọn láti ọ̀run àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn, kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn.+
36 “Tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí kò sí èèyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀),+ tí inú rẹ ru sí wọn, tí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ọ̀tá, tí àwọn tó mú wọn sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ kan, bóyá èyí tó jìnnà tàbí èyí tó wà nítòsí,+
37 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ ẹrú, tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+
38 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn+ wọn àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe ẹrú,+ ìyẹn ibi tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn+ àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,
39 nígbà náà, láti ibi tí ò ń gbé ní ọ̀run, kí o gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn pé kí o ṣojú rere sí àwọn,+ kí o sì ṣe ìdájọ́ nítorí wọn, kí o dárí ji àwọn èèyàn rẹ tó ṣẹ̀ ọ́.
40 “Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, ṣí ojú rẹ, kí o sì tẹ́tí sí àdúrà tí a bá gbà ní* ibí yìí.+
41 Torí náà, dìde, Jèhófà Ọlọ́run, wá síbi ìsinmi rẹ,+ ìwọ àti Àpótí agbára rẹ. Jèhófà Ọlọ́run, fi aṣọ ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ, sì jẹ́ kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yọ̀ nínú ohun rere.+
42 Jèhófà Ọlọ́run, má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.*+ Rántí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ọmọ rẹ, tó máa jáde láti abẹ́ rẹ.”
^ Tàbí “gbàgede.”
^ Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
^ Ní Héb., “ègún.”
^ Ní Héb., “ègún.”
^ Tàbí “tí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ sì gégùn-ún fún un.” Ìyẹn, ìbúra tó ní ègún nínú gẹ́gẹ́ bí ìyà tó máa jẹ ẹni tó bá búra èké tàbí tó dalẹ̀.
^ Ní Héb., “olódodo.”
^ Tàbí “fìyà jẹ wọ́n.”
^ Ní Héb., “ní ilẹ̀ àwọn ẹnubodè rẹ̀.”
^ Tàbí “tata.”
^ Tàbí “ohun tó gbọ́ nípa rẹ.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Tàbí “nípa.”
^ Ní Héb., “má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró rẹ kúrò.”