Sámúẹ́lì Kejì 14:1-33
14 Nígbà náà, Jóábù ọmọ Seruáyà+ rí i pé ọkàn ọba ti ń fà sí Ábúsálómù.+
2 Torí náà, Jóábù ránṣẹ́ sí ìlú Tékóà,+ ó pe ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, ṣe bíi pé ò ń ṣọ̀fọ̀, kí o wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má sì fi òróró para.+ Kí o ṣe bí obìnrin tó ti pẹ́ tó ti ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tó kú.
3 Lẹ́yìn náà, kí o wọlé lọ bá ọba, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un.” Ọ̀nà yẹn ni Jóábù gbà fi ọ̀rọ̀ sí obìnrin náà lẹ́nu.*
4 Obìnrin ará Tékóà náà wọlé lọ bá ọba, ó wólẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọba, ràn mí lọ́wọ́!”
5 Ọba fèsì pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀?” Ló bá sọ pé: “Áà, opó ni mí; ọkọ mi ti kú.
6 Èmi ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì bá ara wọn jà ní pápá. Kò sí ẹni tó máa là wọ́n, ni ọ̀kan bá mú èkejì balẹ̀, ó sì pa á.
7 Ní báyìí, gbogbo ìdílé ti dìde sí èmi ìránṣẹ́ rẹ, wọ́n sì ń sọ pé, ‘Fi ẹni tó pa arákùnrin rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, kí a lè pa á nítorí ẹ̀mí* arákùnrin rẹ̀ tí ó gbà,+ ì báà tiẹ̀ jẹ́ ajogún, ńṣe la máa pa á!’ Wọ́n fẹ́ pa ọmọ mi kan ṣoṣo tó kù mí kù bí ẹni pa ẹyin iná, kí orúkọ ọkọ mi lè pa rẹ́, kó má sì sí ẹnì kankan tó ṣẹ́ kù* fún un lórí ilẹ̀.”
8 Ọba wá sọ fún obìnrin náà pé: “Máa lọ sí ilé rẹ, màá pàṣẹ pé kí a bójú tó ọ̀rọ̀ rẹ.”
9 Ni obìnrin ará Tékóà náà bá sọ fún ọba pé: “Olúwa mi ọba, kí ẹ̀bi náà wà lórí mi àti lórí ilé bàbá mi, àmọ́ kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìṣẹ̀.”
10 Ọba wá sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá tún bá ọ sọ nǹkan kan, kí o mú un wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dààmú rẹ mọ́.”
11 Àmọ́, ó sọ pé: “Jọ̀wọ́ ọba, rántí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ má bàa wá, kí ó sì pa mí lọ́mọ.” Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè,+ ìkankan nínú irun orí ọmọ rẹ kò ní bọ́ sílẹ̀.”
12 Obìnrin náà wá sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.” Nítorí náà, ọba sọ pé: “Sọ ọ́!”
13 Obìnrin náà bá sọ pé: “Kí wá nìdí tí o fi gbèrò láti ṣe irú nǹkan yìí sí àwọn èèyàn Ọlọ́run?+ Nítorí o ti lé ọmọ rẹ kúrò láwùjọ,+ o kọ̀, o ò mú un pa dà, ohun tí o sọ yìí sì ti fi hàn pé ìwọ náà jẹ̀bi.
14 Ó dájú pé a ó kú, a ó sì dà bí omi tí ó dà sílẹ̀, tí kò ṣeé kó jọ. Àmọ́ Ọlọ́run kì í fẹ́ kí ẹ̀mí* kankan bọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ronú nípa ìdí tí ẹni tí a lé kúrò láwùjọ fi yẹ kó pa dà sọ́dọ̀ òun.
15 Mo wọlé wá kí n lè sọ ọ̀rọ̀ yìí fún olúwa mi ọba torí pé àwọn èèyàn dẹ́rù bà mí. Nítorí náà, ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Á dáa kí n bá ọba sọ̀rọ̀. Bóyá ọba máa ṣe ohun tí ẹrú rẹ̀ béèrè.
16 Kí ọba fetí sílẹ̀, kí ó sì gba ẹrú rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń wá ọ̀nà láti pa èmi àti ọmọ mi kan ṣoṣo kúrò lórí ogún tí Ọlọ́run fún wa.’+
17 Nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ sọ pé, ‘Kí ọ̀rọ̀ olúwa mi ọba tù mí lára,’ nítorí olúwa mi ọba dà bí áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ tí ó mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì wà pẹ̀lú rẹ.”
18 Ọba wá dá obìnrin náà lóhùn pé: “Jọ̀wọ́, má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi nínú ohun tí mo bá béèrè lọ́wọ́ rẹ.” Obìnrin náà fèsì pé: “Olúwa mi ọba, jọ̀wọ́ béèrè.”
19 Nígbà náà, ọba béèrè pé: “Ṣé Jóábù ló ní kí o ṣe gbogbo ohun tí o ṣe yìí?”+ Obìnrin náà dáhùn pé: “Bí o* ti wà láàyè, olúwa mi ọba, bí olúwa mi ọba ṣe sọ ló rí,* nítorí ìránṣẹ́ rẹ Jóábù ló pàṣẹ fún mi, òun ló sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ìránṣẹ́ rẹ lẹ́nu.
20 Ìránṣẹ́ rẹ Jóábù fẹ́ kí ọ̀ràn náà lójú ni ó fi ṣe gbogbo ohun tí ó ṣe yìí, àmọ́ olúwa mi ní ọgbọ́n bíi ti áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́, ó sì mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ yìí.”
21 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Jóábù pé: “Ó dáa, màá ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe.+ Lọ mú ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù+ pa dà wá.”
22 Ni Jóábù bá dojú bolẹ̀, ó dọ̀bálẹ̀, ó sì yin ọba. Jóábù sọ pé: “Lónìí, èmi ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé mo ti rí ojú rere rẹ, olúwa mi ọba, nítorí ọba ti ṣe ohun tí ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè.”
23 Ìgbà náà ni Jóábù gbéra, ó lọ sí Géṣúrì,+ ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jerúsálẹ́mù.
24 Àmọ́ ọba sọ pé: “Ilé rẹ̀ ni kí ó pa dà sí, kò gbọ́dọ̀ fojú kàn mí.” Torí náà, Ábúsálómù pa dà sí ilé rẹ̀, kò sì fojú kan ọba.
25 Ní gbogbo Ísírẹ́lì, kò sí arẹwà ọkùnrin tí àwọn èèyàn yìn tó Ábúsálómù. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀.
26 Nígbà tí ó bá gé irun orí rẹ̀, ìwọ̀n irun náà jẹ́ igba (200) ṣékélì* ní ìwọ̀n òkúta* ọba. Ọdọọdún ni ó máa ń gé irun rẹ̀ torí ó máa ń wúwo jù fún un.
27 Ábúsálómù bí ọmọkùnrin mẹ́ta+ àti ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì. Obìnrin tó lẹ́wà gan-an ni.
28 Ọdún méjì gbáko ni Ábúsálómù fi gbé ní Jerúsálẹ́mù, síbẹ̀ kò fojú kan ọba.+
29 Nítorí náà, Ábúsálómù ránṣẹ́ pe Jóábù kí ó lè rán an sí ọba, ṣùgbọ́n Jóábù kò wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó tún ránṣẹ́ sí i nígbà kejì, síbẹ̀ kò wá.
30 Níkẹyìn, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Oko Jóábù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì ní ọkà bálì níbẹ̀. Ẹ lọ sọ iná sí i.” Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sọ iná sí oko náà.
31 Jóábù bá gbéra, ó wá bá Ábúsálómù nílé rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fi sọ iná sí oko mi?”
32 Ábúsálómù dá Jóábù lóhùn pé: “Wò ó! Mo ránṣẹ́ sí ọ pé, ‘Wá, kí o lè lọ bá mi béèrè lọ́wọ́ ọba pé: “Kí nìdí tí mo fi wá láti Géṣúrì?+ Ì bá dára kí n kúkú dúró síbẹ̀. Ní báyìí, jẹ́ kí n fojú kan ọba, tí mo bá sì jẹ̀bi, kí ó pa mí.”’”
33 Torí náà, Jóábù wọlé lọ bá ọba, ó sì sọ fún un. Lẹ́yìn náà, ó pe Ábúsálómù, Ábúsálómù sì wọlé wá bá ọba, ó dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú ọba. Ọba sì fẹnu ko Ábúsálómù lẹ́nu.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “sọ ohun tó máa sọ fún un.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “yè bọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “kò sẹ́ni tó lè yà sọ́tùn-ún tàbí sósì nínú ohun tí olúwa mi ọba sọ.”
^ Nǹkan bíi kìlógíráàmù 2.3. Wo Àfikún B14.
^ Èyí lè jẹ́ ìwọ̀n tí wọ́n gbé sí ààfin ọba tàbí ṣékélì “ọba” kan tó yàtọ̀ sí ṣékélì tí wọ́n sábà máa ń lò.