Sámúẹ́lì Kejì 20:1-26
20 Ọkùnrin oníwàhálà kan wà tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni. Ó fun ìwo,+ ó sì sọ pé: “Àwa kò ní ìpín kankan nínú Dáfídì, a kò sì ní ogún kankan nínú ọmọ Jésè.+ Ìwọ Ísírẹ́lì! Kí kálukú pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run* rẹ̀.”+
2 Ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá pa dà lẹ́yìn Dáfídì kí wọ́n lè tẹ̀ lé Ṣébà ọmọ Bíkíráì;+ ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Júdà dúró ti ọba wọn láti Jọ́dánì títí dé Jerúsálẹ́mù.+
3 Nígbà tí Dáfídì dé ilé* rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,+ ọba mú àwọn wáhàrì* mẹ́wàá tó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ilé,+ ó sì fi wọ́n sínú ilé tó ní ẹ̀ṣọ́. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ àmọ́ kò bá wọn lò pọ̀.+ Inú àhámọ́ ni wọ́n wà títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n ń gbé bíi pé opó ni wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ wọn ṣì wà láàyè.
4 Ọba wá sọ fún Ámásà+ pé: “Pe àwọn ọkùnrin Júdà jọ fún mi láàárín ọjọ́ mẹ́ta, kí ìwọ náà sì wà níbí.”
5 Torí náà, Ámásà lọ pe Júdà jọ, àmọ́ àkókò tí wọ́n dá fún un kọjá kí ó tó dé.
6 Nígbà náà, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì+ pé: “Aburú tí Ṣébà+ ọmọ Bíkíráì máa ṣe fún wa máa ju ti Ábúsálómù lọ.+ Mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má bàa wọnú àwọn ìlú olódi, kí ó sì sá mọ́ wa lọ́wọ́.”
7 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jóábù+ àti àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn alágbára ọkùnrin tẹ̀ lé e; wọ́n sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì.
8 Nígbà tí wọ́n dé tòsí òkúta ńlá tó wà ní Gíbíónì,+ Ámásà+ wá pàdé wọn. Lásìkò yìí, aṣọ ogun ni Jóábù wọ̀, ó sì sán idà kan tó wà nínú àkọ̀ mọ́ ìbàdí rẹ̀. Bí ó ṣe rìn síwájú, idà náà já bọ́.
9 Jóábù sọ fún Ámásà pé: “Arákùnrin mi, ṣé dáadáa lo wà?” Ni Jóábù bá fi ọwọ́ ọ̀tún di irùngbọ̀n Ámásà mú bíi pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó lẹ́nu.
10 Ámásà kò fura sí idà ọwọ́ Jóábù; Jóábù fi idà náà gún un ní ikùn,+ ìfun rẹ̀ sì tú síta sórí ilẹ̀. Kò gún un lẹ́ẹ̀mejì, ìgbà kan péré ti tó láti pa á. Lẹ́yìn náà, Jóábù àti Ábíṣáì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì.
11 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin Jóábù dúró sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ẹni tó bá wà lẹ́yìn Jóábù àti ẹni tó bá ń ṣe ti Dáfídì tẹ̀ lé Jóábù!”
12 Ní gbogbo àkókò yìí, Ámásà ń yí nínú ẹ̀jẹ̀ láàárín ọ̀nà. Nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé gbogbo àwọn èèyàn náà ń dúró, ó gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà, ó sì gbé e lọ sínú igbó. Ó wá fi aṣọ bò ó torí pé gbogbo àwọn tó ń dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ló ń dúró wò ó.
13 Lẹ́yìn tí ó gbé e kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo àwọn ọkùnrin náà tẹ̀ lé Jóábù láti lépa Ṣébà+ ọmọ Bíkíráì.
14 Ṣébà gba àárín gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọjá lọ sí Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà.+ Àwọn ọmọ Bíkíráì kóra jọ, wọ́n sì tẹ̀ lé e wọnú ìlú.
15 Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀* dé, wọ́n sì dó tì í ní Ébẹ́lì ti Bẹti-máákà, wọ́n mọ òkìtì ti odi ìlú náà, tí ó fi jẹ́ pé òkìtì yí ìlú náà ká. Gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Jóábù sì ń gbẹ́ ògiri náà lábẹ́, kí wọ́n lè wó o lulẹ̀.
16 Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan láti inú ìlú náà pè, ó ní: “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Jóábù pé kó máa bọ̀ kí n lè bá a sọ̀rọ̀.”
17 Torí náà, ó sún mọ́ ọn, obìnrin náà sì sọ pé: “Ṣé ìwọ ni Jóábù?” Ó dáhùn pé: “Èmi ni.” Ni ó bá sọ fún un pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.” Ó sọ pé: “Mò ń gbọ́.”
18 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń sọ pé, ‘Ẹ lọ wádìí ní Ébẹ́lì, ọ̀ràn náà á sì yanjú.’
19 Àwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà tí wọ́n sì lóòótọ́ ní Ísírẹ́lì ni mò ń ṣojú fún. Ìlú tó dà bí ìyá ní Ísírẹ́lì lo fẹ́ pa run. Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ogún Jèhófà+ run?”*
20 Jóábù dáhùn pé: “Kò ṣeé gbọ́ sétí pé mo mú un balẹ̀ tàbí pé mo pa á run.
21 Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣébà,+ ọmọ Bíkíráì láti agbègbè olókè Éfúrémù,+ ti dìtẹ̀* sí Ọba Dáfídì. Tí ẹ bá lè fi ọkùnrin yìí nìkan lé mi lọ́wọ́, màá fi ìlú yìí sílẹ̀.” Obìnrin náà bá sọ fún Jóábù pé: “Wò ó! A ó ju orí rẹ̀ sí ọ láti orí ògiri!”
22 Ní kíá, ọlọ́gbọ́n obìnrin náà wọlé lọ bá gbogbo àwọn èèyàn náà, wọ́n gé orí Ṣébà ọmọ Bíkíráì, wọ́n sì jù ú sí Jóábù. Ni ó bá fun ìwo, wọ́n tú ká kúrò ní ìlú náà, kálukú sì lọ sí ilé rẹ̀;+ Jóábù wá pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ ọba.
23 Nígbà náà, Jóábù ni olórí gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì;+ Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà+ sì jẹ́ olórí àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+
24 Ádórámù+ ni olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun; Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí.
25 Ṣéfà ni akọ̀wé; Sádókù+ àti Ábíátárì+ sì ni àlùfáà.
26 Írà ọmọ Jáírì pẹ̀lú sì di olórí àwọn òjíṣẹ́* Dáfídì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “sí àgọ́.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
^ Ní Héb., “Wọ́n.”
^ Ní Héb., “gbé ogún Jèhófà mì.”
^ Ní Héb., “gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.”
^ Ní Héb., “àlùfáà.”