Sámúẹ́lì Kejì 4:1-12

  • Wọ́n pa Íṣí-bóṣétì (1-8)

  • Dáfídì ní kí wọ́n pa àwọn apààyàn náà (9-12)

4  Nígbà tí Íṣí-bóṣétì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù* gbọ́ pé Ábínérì ti kú ní Hébúrónì,+ ọkàn rẹ̀ domi,* ìdààmú sì bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Àwọn ọkùnrin méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn akónilẹ́rù* tó jẹ́ ti ọmọ Sọ́ọ̀lù: ọ̀kan ń jẹ́ Báánà, èkejì sì ń jẹ́ Rékábù. Ọmọ Rímónì ará Béérótì ni wọ́n, wọ́n wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. (Nítorí pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń ka Béérótì+ mọ́ ara Bẹ́ńjámínì.  Àwọn ará Béérótì sá lọ sí Gítáímù,+ wọ́n di àjèjì níbẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní yìí.)  Jónátánì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ní ọmọkùnrin kan tó rọ lẹ́sẹ̀.*+ Ọmọ ọdún márùn-ún ni nígbà tí wọ́n mú ìròyìn wá láti Jésírẹ́lì+ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ti kú, ẹni tó ń tọ́jú rẹ̀ bá gbé e, ó sì sá lọ, àmọ́ bí ẹ̀rù ṣe ń ba obìnrin náà nígbà tó ń sá lọ, ọmọ náà já bọ́, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì rọ. Orúkọ rẹ̀ ni Méfíbóṣétì.+  Àwọn ọmọ Rímónì ará Béérótì, ìyẹn Rékábù àti Báánà, lọ sí ilé Íṣí-bóṣétì ní ọ̀sán gangan, nígbà tí ó ń sun oorun ọ̀sán lọ́wọ́.  Wọ́n wọnú ilé náà bíi pé wọ́n fẹ́ wá kó àlìkámà,* wọ́n sì gún un ní ikùn; Rékábù àti Báánà+ arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ.  Nígbà tí wọ́n wọnú ilé, ó ń sùn lórí ibùsùn nínú yàrá rẹ̀, wọ́n gún un pa, wọ́n sì gé orí rẹ̀ kúrò. Wọ́n gbé orí rẹ̀, wọ́n sì gba ọ̀nà tó lọ sí Árábà láti òru mọ́jú.  Wọ́n gbé orí Íṣí-bóṣétì + wá fún Dáfídì ní Hébúrónì, wọ́n sì sọ fún ọba pé: “Orí Íṣí-bóṣétì ọmọ Sọ́ọ̀lù ọ̀tá rẹ+ tí ó fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ+ rèé. Jèhófà ti bá olúwa mi ọba gbẹ̀san lára Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ lónìí yìí.”  Àmọ́, Dáfídì dá Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímónì ará Béérótì lóhùn pé: “Bí Jèhófà ẹni tí ó yọ mí* nínú gbogbo wàhálà+ ti wà láàyè, 10  nígbà tí ẹnì kan wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, Sọ́ọ̀lù ti kú,’+ ó rò pé ìròyìn ayọ̀ lòun mú wá fún mi, mo gbá a mú, mo sì pa á+ ní Síkílágì. Nǹkan tí mo fi san èrè iṣẹ́ tó wá jẹ́ nìyẹn! 11  Ṣé mi ò wá ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún àwọn èèyàn burúkú tó lọ pa ọkùnrin olódodo nínú ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀? Ǹjẹ́ kò yẹ kí n béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín,+ kí n sì mú yín kúrò lórí ilẹ̀?” 12  Dáfídì bá pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin pa wọ́n.+ Wọ́n gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì gbé wọn kọ́+ sí ẹ̀gbẹ́ adágún odò ní Hébúrónì. Àmọ́ wọ́n gbé orí Íṣí-bóṣétì, wọ́n sì sín in sí ibi tí wọ́n sin Ábínérì sí ní Hébúrónì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù.”
Ní Héb., “ọwọ́ rẹ̀ rọ.”
Tàbí “jàǹdùkú.”
Tàbí “yarọ.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tún ọkàn mi rà pa dà.”