Diutarónómì 31:1-30

  • Ikú Mósè sún mọ́lé (1-8)

  • Kí wọ́n máa ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí (9-13)

  • Ó faṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́ (14, 15)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ bí Ísírẹ́lì ṣe máa ya ọlọ̀tẹ̀ (16-30)

    • Orin láti fi kọ́ Ísírẹ́lì (19, 22, 30)

31  Lẹ́yìn náà, Mósè jáde lọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo Ísírẹ́lì,  ó sọ fún wọn pé: “Ẹni ọgọ́fà (120) ọdún ni mí lónìí.+ Mi ò lè darí yín mọ́,* torí Jèhófà ti sọ fún mi pé, ‘O ò ní sọdá Jọ́dánì yìí.’+  Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló máa sọdá ṣáájú rẹ, òun fúnra rẹ̀ máa pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run kúrò níwájú rẹ, wàá sì lé wọn kúrò.+ Jóṣúà ló máa kó yín sọdá,+ bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́.  Ohun tí Jèhófà ṣe sí Síhónì+ àti Ógù,+ àwọn ọba Ámórì àti sí ilẹ̀ wọn, nígbà tó pa wọ́n run ló máa ṣe sí wọn gẹ́lẹ́.+  Jèhófà máa bá yín ṣẹ́gun wọn, gbogbo ohun tí mo sì pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ ṣe sí wọn gẹ́lẹ́.+  Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára.+ Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì gbọ̀n rìrì níwájú wọn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bá yín lọ. Kò ní pa yín tì, kò sì ní fi yín sílẹ̀.”+  Mósè wá pe Jóṣúà, ó sì sọ fún un níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn èèyàn yìí wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wọn, wàá sì fún wọn kí wọ́n lè jogún rẹ̀.+  Jèhófà ló ń lọ níwájú rẹ, ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò sì ní fi ọ́ sílẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jáyà.”+  Mósè wá kọ Òfin yìí,+ ó sì fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì. 10  Mósè pàṣẹ fún wọn pé: “Ní òpin ọdún méje-méje, ní àkókò rẹ̀ nígbà ọdún ìtúsílẹ̀,+ ní àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ 11  nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá síwájú Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní ibi tó yàn, kí ẹ ka Òfin yìí sí gbogbo Ísírẹ́lì létí.+ 12  Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé* àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú* yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí. 13  Àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ Òfin yìí á wá fetí sílẹ̀,+ wọ́n á sì kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.”+ 14  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Ọjọ́ ikú rẹ ti sún mọ́lé.+ Pe Jóṣúà, kí ẹ sì lọ síwájú* àgọ́ ìpàdé, kí n lè faṣẹ́ lé e lọ́wọ́.”+ Mósè àti Jóṣúà wá lọ síwájú àgọ́ ìpàdé. 15  Jèhófà wá fara hàn ní àgọ́ náà nínú ọwọ̀n ìkùukùu,* ọwọ̀n ìkùukùu náà sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.+ 16  Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+ 17  Màá bínú sí wọn gidigidi nígbà yẹn,+ màá pa wọ́n tì,+ màá sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn+ títí wọ́n á fi pa run. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá wá dé bá wọn,+ wọ́n á sọ pé, ‘Ṣebí torí Ọlọ́run wa ò sí láàárín wa ni àjálù yìí ṣe dé bá wa?’+ 18  Àmọ́ màá fi ojú mi pa mọ́ fún wọn lọ́jọ́ yẹn torí gbogbo ìwà ibi tí wọ́n hù, tí wọ́n lọ ń tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn.+ 19  “Ẹ kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sílẹ̀ fún ara yín,+ kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ẹ fi kọ́ wọn,* kí orin yìí lè ṣe ẹlẹ́rìí mi lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 20  Tí mo bá mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ tí wọ́n jẹun tẹ́rùn, tí nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn,*+ wọ́n á lọ máa tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, wọ́n á sì máa sìn wọ́n, wọ́n á hùwà àfojúdi sí mi, wọ́n á sì da májẹ̀mú mi.+ 21  Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá dé bá wọn,+ orin yìí máa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wọn, (torí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé rẹ̀), torí mo ti mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn+ kí n tiẹ̀ tó mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀.” 22  Mósè wá kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 23  Lẹ́yìn náà, Ó* fa iṣẹ́ lé Jóṣúà+ ọmọ Núnì lọ́wọ́, ó sọ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ tí mo búra fún wọn nípa rẹ̀,+ mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.” 24  Gbàrà tí Mósè kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sínú ìwé tán,+ 25  Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì tó ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà, pé: 26  “Ẹ gba ìwé Òfin yìí,+ kí ẹ fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lòdì sí yín níbẹ̀. 27  Torí mo mọ̀ dáadáa pé ọlọ̀tẹ̀ ni yín,+ ẹ sì lágídí.*+ Tí ẹ bá ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó báyìí nígbà tí mo ṣì wà láàyè pẹ̀lú yín, tí mo bá wá kú ńkọ́! 28  Ẹ kó gbogbo àgbààgbà ẹ̀yà yín àti àwọn olórí yín jọ sọ́dọ̀ mi, kí n lè fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tó wọn létí, kí n sì fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí wọn.+ 29  Torí mo mọ̀ dáadáa pé tí mo bá ti kú, ó dájú pé ẹ máa ṣe ohun tó burú,+ ẹ sì máa yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín. Ó dájú pé àjálù máa dé bá yín+ nígbẹ̀yìn ọjọ́, torí ẹ máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, iṣẹ́ ọwọ́ yín sì máa múnú bí i.” 30  Mósè wá ka àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí sí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì létí, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí:+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Mi ò lè máa jáde kí n sì máa wọlé mọ́.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ kéékèèké.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “lọ dúró níwájú.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ.”
Ní Héb., “Ẹ fi sí wọn lẹ́nu.”
Ní Héb., “tí wọ́n sì sanra.”
Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “ẹ sì jẹ́ ọlọ́rùn líle.”