Sí Àwọn Hébérù 5:1-14
5 Torí gbogbo àlùfáà àgbà tí a mú láàárín àwọn èèyàn ni a yàn nítorí wọn láti bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run,+ kó lè fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀.+
2 Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàánú àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tó ń ṣàṣìṣe,* torí òun náà ní àìlera tiẹ̀,*
3 ìdí nìyẹn tí òun náà fi gbọ́dọ̀ rú ẹbọ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀, bó ṣe ń ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn gẹ́lẹ́.+
4 Èèyàn kì í fún ara rẹ̀ ní irú ọlá yìí, àfi tí Ọlọ́run bá pè é ló máa rí i gbà, bíi ti Áárónì.+
5 Bákan náà, Kristi kọ́ ló ṣe ara rẹ̀ lógo + nígbà tó di àlùfáà àgbà, àmọ́ Ẹni tó sọ fún un pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”+ ló ṣe é lógo.
6 Ó tún sọ ní ibòmíì pé, “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+
7 Nígbà tí Kristi wà ní ayé,* ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì fi ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé tọrọ+ lọ́wọ́ Ẹni tó lè gbà á lọ́wọ́ ikú, a sì gbọ́ ọ, a ṣojúure sí i torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ni, ó kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ.+
9 Lẹ́yìn tí a sì sọ ọ́ di pípé,+ ipasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí i fi máa ní ìgbàlà àìnípẹ̀kun,+
10 torí Ọlọ́run ti fi ṣe àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì.+
11 A ní ohun tó pọ̀ láti sọ nípa rẹ̀, ó sì ṣòroó ṣàlàyé, torí pé ẹ kì í fọkàn sí ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ mọ́.*
12 Torí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ ti di olùkọ́ báyìí,* ẹ ṣì tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nípa àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run, ẹ sì ti pa dà di ẹni tó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle.
13 Torí gbogbo ẹni tí kò yéé mu wàrà kò mọ ọ̀rọ̀ òdodo, torí pé ọmọdé ni.+
14 Àmọ́ àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún, àwọn tó ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀* wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ó lè fi sùúrù (ìwọ̀ntúnwọ̀nsì) bá àwọn aláìmọ̀kan lò.”
^ Tàbí “oníwàkiwà.”
^ Tàbí “àìlera tiẹ̀ náà ń nípa lórí rẹ̀.”
^ Ní Grk., “Ní àwọn ọjọ́ Kristi nínú ẹran ara.”
^ Tàbí “ẹ ti yigbì ní gbígbọ́.”
^ Ní Grk., “níbi tí àkókò dé yìí.”
^ Tàbí “ìwòye.”