Hósíà 2:1-23
2 “Ẹ sọ fún àwọn arákùnrin yín pé, ‘Ẹ̀yin èèyàn mi!’*+
Àti fún àwọn arábìnrin yín pé, ‘Ẹyin obìnrin tí Ọlọ́run ṣàánú!’*+
2 Ẹ fẹ̀sùn kan ìyá yín; ẹ fẹ̀sùn kàn án,Torí kì í ṣe aya mi,+ èmi kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Kí ó jáwọ́ nínú ìṣekúṣe* rẹ̀Kí ó sì mú ìwà àgbèrè kúrò láàárín ọmú rẹ̀,
3 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá tú u sí ìhòòhò, màá sì jẹ́ kó rí bíi ti ọjọ́ tí wọ́n bí i,Màá jẹ́ kó rí bí aginjù,Á sì di ilẹ̀ tí kò lómi,Màá sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ títí á fi kú.
4 Mi ò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,Torí pé ọmọ àlè* ni wọ́n.
5 Nítorí ìyá wọn ti ṣe ìṣekúṣe.*+
Ẹni tó lóyún wọn ti hùwà àìnítìjú,+ torí ó sọ pé,‘Màá lọ bá àwọn olólùfẹ́ mi àtàtà,+Àwọn tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,Irun àgùntàn àti aṣọ ọ̀gbọ̀,* òróró àti ohun mímu.’
6 Nítorí náà, màá fi ẹ̀gún ṣe ọgbà dí ojú ọ̀nà rẹ̀;Màá sì mọ ògiri olókùúta dí ojú ọ̀nà rẹ̀,Kó má bàa rí ọ̀nà kọjá.
7 Á sá tẹ̀ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà, àmọ́ kò ní bá wọn;+Á wá wọn, àmọ́ kò ní rí wọn.
Á wá sọ pé, ‘Màá pa dà sọ́dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́,+Nítorí nǹkan dáa fún mi ní àkókò yẹn ju ti ìgbà yìí lọ.’+
8 Kò mọ̀ pé èmi ló fún un ní ọkà,+ wáìnì tuntun àti òróró,Àti pé èmi ló fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fàdákàÀti wúrà tí wọ́n lò fún Báálì.+
9 ‘Torí náà, màá pa dà wá, màá sì kó ọkà mi lọ ní ìgbà ìkórèÀti wáìnì tuntun mi ní àsìkò rẹ̀,+Èmi yóò sì já irun àgùntàn mi gbà àti aṣọ ọ̀gbọ̀* mi tí ì bá bo ìhòòhò rẹ̀.
10 Nígbà náà, màá ṣí abẹ́ rẹ̀ síta lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,Ẹnì kankan ò sì ní lè gbà á lọ́wọ́ mi.+
11 Màá fòpin sí gbogbo ìdùnnú rẹ̀,Àwọn àjọyọ̀ rẹ̀,+ òṣùpá tuntun rẹ̀ àti àwọn sábáàtì rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìgbà àjọyọ̀ rẹ̀.
12 Màá run àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, tó sọ nípa wọn pé:
“Èrè tí mo gbà ni wọ́n, tí àwọn olólùfẹ́ mi àtàtà fún mi”;Màá sọ wọ́n di igbó,Àwọn ẹran inú igbó á sì jẹ wọ́n run.
13 Màá mú kí ó jíhìn nítorí àwọn ọjọ́ tó fi rúbọ sí àwọn ère Báálì,+Nígbà tó fi òrùka àti ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lóge, tó sì ń tẹ̀ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàtà,Ó sì ti gbàgbé mi,’+ ni Jèhófà wí.
14 ‘Nítorí náà, màá yí i lérò pa dà,Màá sì mú un lọ sí aginjù,Màá wá sọ̀rọ̀ tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
15 Màá dá àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pa dà fún un láti ìgbà náà lọ,+Màá sì fi Àfonífojì* Ákórì+ ṣe ọ̀nà ìrètí fún un;Yóò dáhùn níbẹ̀ bíi ti ìgbà èwe rẹ̀,Bíi ti ọjọ́ tó kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
16 Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà wí,‘Ọkọ Mi ni wàá máa pè mí, o ò ní pè mí ní Ọ̀gá Mi* mọ́.’
17 ‘Màá mú orúkọ àwọn ère Báálì kúrò ní ẹnu rẹ̀,+A ò sì ní rántí orúkọ wọn mọ́.+
18 Ní ọjọ́ yẹn, màá bá àwọn ẹran inú igbó dá májẹ̀mú nítorí wọn,+Màá sì bá àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ohun tó ń rákò lórí ilẹ̀ dá májẹ̀mú;+Màá mú ọfà* àti idà àti ogun kúrò ní ilẹ̀ náà,+Màá sì jẹ́ kí wọ́n dùbúlẹ̀* ní ààbò.+
19 Màá fẹ́ ọ fún ara mi títí láé;Màá sì fẹ́ ọ fún ara mi nínú òdodo àti nínú ìdájọ́ òdodo,Nínú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti nínú àánú.+
20 Màá fẹ́ ọ pẹ̀lú òtítọ́,Dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ Jèhófà.’+
21 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá dáhùn,’ ni Jèhófà wí,‘Màá dá àwọn ọ̀run lóhùn,Wọ́n á sì dá ilẹ̀ lóhùn;+
22 Ilẹ̀ á sì dá ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró lóhùn;Àwọn náà á sì dá Jésírẹ́lì*+ lóhùn.
23 Màá gbìn ín bí irúgbìn fún ara mi sórí ilẹ̀,+Màá sì ṣàánú rẹ̀, bí wọn ò tiẹ̀ ṣàánú rẹ̀;*Màá sọ fún àwọn tí kì í ṣe èèyàn mi pé:* “Èèyàn mi ni yín”,+Àwọn náà á sì sọ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run wa.”’”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Tàbí “Báálì Mi.”
^ Ní Héb., “ọrun.”
^ Tàbí “gbé.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Yóò Fún Irúgbìn.”