Hósíà 7:1-16

  • Àpèjúwe nípa ìwà ibi Éfúrémù (1-16)

    • Kò sí ọ̀nà àbáyọ nínú àwọ̀n Ọlọ́run (12)

7  “Ìgbà tí mo fẹ́ mú Ísírẹ́lì lára dá,Ni ẹ̀ṣẹ̀ Éfúrémù pẹ̀lú fara hàn+Àti ìwà ìkà Samáríà.+ Nítorí wọ́n ń ṣẹ̀tàn;+Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàǹdùkú* sì ń ṣọṣẹ́ lóde.+   Àmọ́, ọkàn wọn ò sọ fún wọn pé màá rántí gbogbo ìwà ìkà wọn.+ Ní báyìí, ohun tí wọ́n ṣe ti hàn síta;Wọ́n wà ní iwájú mi.   Wọ́n ń fi ìwà ìkà wọn mú inú ọba dùn,Wọ́n sì ń fi ẹ̀tàn wọn mú inú àwọn ìjòyè dùn.   Alágbèrè ni gbogbo wọn,Ara wọn ń gbóná bí iná ààrò ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì,Tí kò nílò láti kò ó mọ́ látìgbà tó ti po ìyẹ̀fun títí á fi wú.   Lọ́jọ́ àjọyọ̀ ọba wa, àwọn ìjòyè ń ṣàìsàn,Wáìnì ti mú kí wọ́n bínú.+ Ọba ti tẹ́wọ́ gba àwọn afiniṣẹ̀sín.   Nítorí wọ́n wá pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wọn tó ń jó bí iná ààrò.* Ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì fi gbogbo òru sùn;Ní òwúrọ̀, iná ààrò náà ti ń jó fòfò.   Gbogbo wọn gbóná bí ààrò,Wọ́n sì jẹ àwọn alákòóso* wọn run. Gbogbo ọba wọn ti ṣubú;+Kò sí ìkankan lára wọn tó ké pè mí.+   Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+ Éfúrémù dà bí àkàrà tí a kò yí ẹ̀yìn rẹ̀ pa dà.   Àwọn àjèjì ti gba okun rẹ̀ tán,+ ṣùgbọ́n kò mọ̀. Irun orí rẹ̀ ti di funfun, síbẹ̀ kò kíyè sí i. 10  Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i pé ó gbéra ga,+Síbẹ̀ wọn kò pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn,+Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá a pẹ̀lú adúrú ohun tí wọ́n ṣe yìí. 11  Éfúrémù dà bí àdàbà tó gọ̀, tí kò ní làákàyè.*+ Wọ́n ti ké pe Íjíbítì;+ wọ́n ti lọ sí Ásíríà.+ 12  Ibikíbi tí wọn ì báà lọ, màá fi àwọ̀n mi mú wọn. Màá mú wọn wálẹ̀ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Màá bá wọn wí lọ́nà tí mo gbà kìlọ̀ fún àpéjọ wọn.+ 13  Wọ́n gbé! Torí wọ́n sá kúrò lọ́dọ̀ mi. Ìparun á bá wọn, torí wọ́n ti ṣẹ̀ mí! Mo ṣe tán láti rà wọ́n pa dà, àmọ́ wọ́n pa irọ́ mọ́ mi.+ 14  Wọn ò ké pè mí látinú ọkàn wọn fún ìrànlọ́wọ́,+Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sunkún ṣáá lórí ibùsùn wọn. Torí ọkà wọn àti wáìnì tuntun wọn, wọ́n ń fi nǹkan ya ara wọn;Wọ́n kẹ̀yìn sí mi. 15  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo bá wọn wí tí mo sì fún wọn lókun,Wọ́n kẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì ń gbèrò ibi. 16  Wọ́n yí pa dà, àmọ́ kì í ṣe sí Ọlọ́run tòótọ́;*Wọn ò ṣeé gbára lé bí ọrun tó ti dẹ̀.+ Idà ni yóò pa àwọn olórí wọn nítorí ahọ́n wọn mú. Torí èyí, wọ́n á di ẹni ẹ̀sín ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn akónilẹ́rù.”
Tàbí kó jẹ́, “Nítorí ọkàn wọn dà bí iná ààrò bí wọ́n ṣe ń bọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ wọn.”
Ní Héb., “àwọn onídàájọ́.”
Ní Héb., “tí kò ní ọkàn.”
Ìyẹn, ìjọsìn tòótọ́.