Àkọsílẹ̀ Jòhánù 11:1-57

  • Ikú Lásárù (1-16)

  • Jésù tu Màtá àti Màríà nínú (17-37)

  • Jésù jí Lásárù dìde (38-44)

  • Wọ́n gbìmọ̀ láti pa Jésù (45-57)

11  Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Lásárù ń ṣàìsàn; Bẹ́tánì ló ti wá, ibẹ̀ ni abúlé Màríà àti Màtá+ arábìnrin rẹ̀.  Òun ni Màríà tó da òróró onílọ́fínńdà sí ara Olúwa, tó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ;+ Lásárù arákùnrin rẹ̀ ló ń ṣàìsàn.  Torí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí o nífẹ̀ẹ́ gan-an ń ṣàìsàn.”  Àmọ́ nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ pé: “Ikú kọ́ ló máa gbẹ̀yìn àìsàn yìí, àmọ́ ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run,+ ká lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”  Jésù fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.  Àmọ́ nígbà tó gbọ́ pé Lásárù ń ṣàìsàn, ó lo ọjọ́ méjì sí i níbi tó wà.  Lẹ́yìn èyí, ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jẹ́ ká tún lọ sí Jùdíà.”  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Rábì,+ ẹnu àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà fẹ́ sọ ọ́ lókùúta,+ ṣé o tún fẹ́ lọ síbẹ̀ ni?”  Jésù dáhùn pé: “Wákàtí méjìlá (12) ló wà ní ojúmọmọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? + Tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní ojúmọmọ, kì í kọ lu ohunkóhun, torí ó ń rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá ń rìn ní òru, ó máa kọsẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ kò sí nínú rẹ̀.” 11  Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó fi kún un pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn,+ àmọ́ mò ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ kí n lè jí i.” 12  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ pé ó ń sùn ni, ara rẹ̀ máa yá.” 13  Àmọ́, ọ̀rọ̀ ikú rẹ̀ ni Jésù ń sọ. Wọ́n rò pé ó sọ pé ó ń sùn kó lè sinmi. 14  Jésù wá sọ fún wọn ní tààràtà pé: “Lásárù ti kú,+ 15  mo sì yọ̀ nítorí yín pé mi ò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbà gbọ́. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 16  Torí náà, Tọ́másì, tí wọ́n ń pè ní Ìbejì, sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, ká lè bá a kú.”+ 17  Nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé Lásárù ti wà nínú ibojì* náà fún ọjọ́ mẹ́rin. 18  Bẹ́tánì ò jìnnà sí Jerúsálẹ́mù, kò ju nǹkan bíi máìlì méjì* lọ síbẹ̀. 19  Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ti wá sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà kí wọ́n lè tù wọ́n nínú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin wọn. 20  Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀; àmọ́ Màríà+ ṣì jókòó sílé. 21  Màtá wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú. 22  Síbẹ̀, mo ṣì mọ̀ pé ohunkóhun tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run máa fún ọ.” 23  Jésù sọ fún un pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” 24  Màtá sọ fún un pé: “Mo mọ̀ pé ó máa dìde nígbà àjíǹde+ ní ọjọ́ ìkẹyìn.” 25  Jésù sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.+ Ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, tó bá tiẹ̀ kú, ó máa yè; 26  gbogbo ẹni tó bá wà láàyè, tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi kò ní kú láé.+ Ṣé o gba èyí gbọ́?” 27  Ó sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tó ń bọ̀ wá sí ayé.” 28  Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó lọ pe Màríà arábìnrin rẹ̀, ó sọ fún un ní bòókẹ́lẹ́ pé: “Olùkọ́+ ti dé, ó ń pè ọ́.” 29  Bó ṣe gbọ́ èyí, ó yára dìde, ó sì lọ bá a. 30  Jésù ò tíì wọnú abúlé náà, ó ṣì wà níbi tí Màtá ti pàdé rẹ̀. 31  Nígbà tí àwọn Júù tó wà lọ́dọ̀ Màríà nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí i pé ó yára dìde, tó sì jáde, wọ́n tẹ̀ lé e torí wọ́n rò pé ibi ibojì*+ náà ló ń lọ láti lọ sunkún níbẹ̀. 32  Nígbà tí Màríà dé ibi tí Jésù wà, tó sì tajú kán rí i, ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” 33  Nígbà tí Jésù rí i tí òun àti àwọn Júù tó tẹ̀ lé e wá ń sunkún, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi,* ìdààmú sì bá a. 34  Ó sọ pé: “Ibo lẹ tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, wá wò ó.” 35  Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.+ 36  Ni àwọn Júù bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ẹ wò ó, ó mà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an o!” 37  Àmọ́ àwọn kan lára wọn sọ pé: “Ṣé ọkùnrin yìí tó la ojú ọkùnrin afọ́jú+ kò lè ṣe é kí ẹni yìí má kú ni?” 38  Lẹ́yìn tí ẹ̀dùn ọkàn tún bá Jésù, ó wá síbi ibojì* náà. Inú ihò kan ni, wọ́n sì fi òkúta kan dí i. 39  Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Màtá, arábìnrin olóògbé náà, sọ fún un pé: “Olúwa, á ti máa rùn báyìí, torí ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin.” 40  Jésù sọ fún un pé: “Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?”+ 41  Torí náà, wọ́n gbé òkúta náà kúrò. Jésù wá gbójú sókè wo ọ̀run,+ ó sì sọ pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. 42  Lóòótọ́, mo mọ̀ pé o máa ń gbọ́ tèmi; àmọ́ torí èrò tó dúró yí ká ni mo fi sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.”+ 43  Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó sọ pé: “Lásárù, jáde wá!”+ 44  Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.” 45  Torí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n sì rí ohun tó ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,+ 46  àmọ́ àwọn kan lára wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí, wọ́n sì sọ àwọn ohun tí Jésù ṣe fún wọn. 47  Torí náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sàhẹ́ndìrìn jọ, wọ́n sì sọ pé: “Kí ni ká ṣe, torí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?+ 48  Tí a bá jẹ́ kó máa bá a lọ báyìí, gbogbo wọn ló máa gbà á gbọ́, àwọn ará Róòmù á sì wá gba àyè* wa àti orílẹ̀-èdè wa.” 49  Àmọ́ ọ̀kan lára wọn, Káyáfà,+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ nǹkan kan rárá, 50  ẹ ò sì rò ó pé ó máa ṣe yín láǹfààní pé kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn dípò kí gbogbo orílẹ̀-èdè pa run.” 51  Àmọ́ èrò ara rẹ̀ kọ́ ni ohun tó sọ yìí, ṣùgbọ́n torí pé òun ni àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa kú fún orílẹ̀-èdè náà, 52  kì í sì í ṣe fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, àmọ́ kó tún lè kó àwọn ọmọ Ọlọ́run tó ti fọ́n káàkiri jọ, kí wọ́n sì di ọ̀kan. 53  Torí náà, láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. 54  Torí ìyẹn, Jésù ò rìn káàkiri ní gbangba mọ́ láàárín àwọn Júù, àmọ́ ó kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè tó wà nítòsí aginjù, sí ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Éfúrémù,+ ó sì dúró síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn. 55  Ìrékọjá+ àwọn Júù ti sún mọ́lé, ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù kó tó dìgbà Ìrékọjá kí wọ́n lè wẹ ara wọn mọ́ bí Òfin ṣe sọ. 56  Wọ́n ń wá Jésù, bí wọ́n sì ṣe dúró káàkiri nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Kí lèrò yín? Ṣé pé kò ní wá síbi àjọyọ̀ yìí rárá?” 57  Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá mọ ibi tí Jésù wà, kó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ibojì ìrántí.”
Nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta. Ní Grk., “nǹkan bíi sítédíọ̀mù 15.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Ní Grk., “bá a nínú ẹ̀mí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Ìyẹn, tẹ́ńpìlì.
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”