Àkọsílẹ̀ Jòhánù 17:1-26
17 Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbójú sókè wo ọ̀run, ó sọ pé: “Baba, wákàtí náà ti dé. Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo,+
2 bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,*+ kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un+ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+
3 Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun,+ pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo*+ àti Jésù Kristi,+ ẹni tí o rán.
4 Mo ti yìn ọ́ lógo ní ayé,+ ní ti pé mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe.+
5 Torí náà, ní báyìí, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.+
6 “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé.*+ Ìwọ lo ni wọ́n, o sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.*
7 Wọ́n ti wá mọ̀ báyìí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo ohun tí o fún mi ti wá;
8 torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi ni mo ti sọ fún wọn,+ wọ́n sì ti gbà á, ó dájú pé wọ́n ti wá mọ̀ pé mo wá bí aṣojú rẹ,+ wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.+
9 Mo gbàdúrà nípa wọn; kì í ṣe nípa ayé, àmọ́ nípa àwọn tí o fún mi, torí pé ìwọ lo ni wọ́n;
10 ìwọ lo ni gbogbo ohun tí mo ní, èmi ni mo sì ni tìrẹ,+ a sì ti ṣe mí lógo láàárín wọn.
11 “Mi ò sí ní ayé mọ́, àmọ́ àwọn wà ní ayé,+ mo sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan* bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.*+
12 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn, mo máa ń ṣọ́ wọn+ nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi; mo ti dáàbò bò wọ́n, ìkankan nínú wọn ò sì pa run+ àfi ọmọ ìparun,+ kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ.+
13 Àmọ́ ní báyìí, mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ, mo sì ń sọ àwọn nǹkan yìí ní ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nínú wọn.+
14 Mo ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, àmọ́ ayé ti kórìíra wọn, torí wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.
15 “Mi ò ní kí o mú wọn kúrò ní ayé, àmọ́ kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.+
16 Wọn kì í ṣe apá kan ayé,+ bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.+
17 Sọ wọ́n di mímọ́* nípasẹ̀ òtítọ́;+ òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.+
18 Bí o ṣe rán mi wá sí ayé, èmi náà rán wọn lọ sínú ayé.+
19 Mo sì ń sọ ara mi di mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn náà di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́.
20 “Kì í ṣe àwọn yìí nìkan ni mò ń gbàdúrà nípa wọn, mo tún ń gbàdúrà nípa àwọn tó máa ní ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn,
21 kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan,+ bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.
22 Mo ti fún wọn ní ògo tí o fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan.+
23 Èmi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn, ìwọ sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, kí a lè mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan délẹ̀délẹ̀,* kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi àti pé o nífẹ̀ẹ́ wọn bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi.
24 Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà,+ kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.+
25 Baba olódodo, ní tòótọ́, ayé ò tíì wá mọ̀ ọ́,+ àmọ́ èmi mọ̀ ọ́,+ àwọn yìí sì ti wá mọ̀ pé ìwọ lo rán mi.
26 Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n,+ kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “aráyé; èèyàn.”
^ Tàbí “kí wọ́n gba ìmọ̀ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo sínú.”
^ Tàbí “Mo ti jẹ́ kí àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé mọ orúkọ rẹ.”
^ Tàbí “ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.”
^ Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”
^ Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”
^ Tàbí “Yà wọ́n sọ́tọ̀; Jẹ́ kí wọ́n di mímọ́.”
^ Tàbí “kí a lè mú kí wọ́n ṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀.”