Jóòbù 24:1-25
24 “Kí ló dé tí Olódùmarè ò yan àkókò?+
Kí ló dé tí àwọn tó mọ̀ ọ́n kò rí ọjọ́ rẹ̀?*
2 Àwọn èèyàn ń sún ààlà;+Wọ́n ń jí àwọn agbo ẹran gbé lọ sí ibi ìjẹko wọn.
3 Wọ́n ń lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* dà nù,Wọ́n sì ń gba akọ màlúù opó láti fi ṣe ìdúró.*+
4 Wọ́n ń fipá lé àwọn aláìní kúrò lọ́nà;Àfi kí àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ láyé sá pa mọ́ fún wọn.+
5 Àwọn aláìní ń wá oúnjẹ kiri bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ nínú aginjù;Wọ́n ń wá oúnjẹ kiri fún àwọn ọmọ wọn nínú aṣálẹ̀.
6 Àfi kí wọ́n kórè nínú oko ẹlòmíì,*Kí wọ́n sì pèéṣẹ́* nínú ọgbà àjàrà ẹni burúkú.
7 Ìhòòhò ni wọ́n ń sùn mọ́jú, wọn ò ní aṣọ;+Wọn ò rí nǹkan kan fi bora nígbà òtútù.
8 Òjò orí òkè mú kí wọ́n rin gbingbin;Wọ́n rọ̀ mọ́ àpáta torí wọn ò ríbi forí pa mọ́ sí.
9 Wọ́n já ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú;+Wọ́n sì gba aṣọ aláìní láti fi ṣe ìdúró,+
10 Wọ́n fipá mú kí wọ́n máa rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ aṣọ,Ebi sì ń pa wọ́n, bí wọ́n ṣe gbé àwọn ìtí ọkà.
11 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele nínú ooru ọ̀sán gangan;*Wọ́n ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+
12 Àwọn tó ń kú lọ ń kérora nínú ìlú;Àwọn tó fara pa gan-an* ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+Àmọ́ Ọlọ́run ò ka èyí sí àìdáa.*
13 Àwọn kan wà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;+Wọn ò mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,Wọn kì í sì í tẹ̀ lé àwọn òpópónà rẹ̀.
14 Apààyàn dìde ní ojúmọmọ;Ó pa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àti aláìní,+Ó sì ń jalè ní òru.
15 Ojú alágbèrè ń dúró de ìrọ̀lẹ́,+Ó ń sọ pé, ‘Kò sẹ́ni tó máa rí mi!’+
Ó sì ń bo ojú rẹ̀.
16 Wọ́n ń fọ́ ilé* nínú òkùnkùn;Wọ́n ń ti ara wọn mọ́lé ní ọ̀sán.
Àjèjì ni wọ́n sí ìmọ́lẹ̀.+
17 Torí bákan náà ni àárọ̀ àti òkùnkùn biribiri rí fún wọn;Wọ́n mọ àwọn ohun tó ń dẹ́rù bani nínú òkùnkùn biribiri.
18 Àmọ́ omi yára gbé wọn lọ.*
Ègún máa wà lórí ilẹ̀ wọn.+
Wọn ò ní pa dà sí àwọn ọgbà àjàrà wọn.
19 Bí ọ̀gbẹlẹ̀ àti ooru ṣe ń mú kí yìnyín yọ́ kó sì gbẹ,Bẹ́ẹ̀ ni Isà Òkú* ń mú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ!+
20 Ìyá rẹ̀* máa gbàgbé rẹ̀; ìdin máa fi ṣe oúnjẹ.
Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́.+
A sì máa ṣẹ́ àìṣòdodo bí igi.
21 Ó ń rẹ́ àwọn àgàn jẹ,Ó sì ń ni opó lára.
22 Ọlọ́run* máa fi okun rẹ̀ mú àwọn alágbára kúrò;Bí wọ́n tiẹ̀ dìde, kò dájú pé wọ́n á ní ìyè.
23 Ọlọ́run* jẹ́ kí wọ́n dá ara wọn lójú, kí ọkàn wọn sì balẹ̀,+Àmọ́ ojú rẹ̀ tó gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*+
24 A gbé wọn ga fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn ò sí mọ́.+
A rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,+ a sì kó wọn jọ bíi gbogbo èèyàn yòókù;A gé wọn kúrò bí orí ọkà.
25 Ta ló wá lè mú mi ní onírọ́,Tàbí kó sọ pé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣòótọ́?”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀.
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Tàbí “ìdógò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kórè oúnjẹ ẹran nínú oko.”
^ Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ń fún òróró láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele.”
^ Tàbí “Ọkàn àwọn tó ṣèṣe.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run ò fi ẹ̀sùn kan ẹnikẹ́ni.”
^ Ní Héb., “dá ilé lu.”
^ Ní Héb., “Ó yára lórí omi.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “Ilé ọlẹ̀.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “àwọn ọ̀nà wọn.”