Jóòbù 28:1-28

  • Jóòbù fi àwọn ìṣúra ayé wé ọgbọ́n (1-28)

    • Bí èèyàn ṣe ń sapá láti wa kùsà (1-11)

    • Ọgbọ́n níye lórí ju péálì lọ (18)

    • Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n tòótọ́ (28)

28  “Ibì kan wà tí wọ́n ti lè wa fàdákà,Ibì kan sì wà tí wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́ wà;+   Inú ilẹ̀ ni wọ́n ti ń mú irin,Inú àpáta sì ni wọ́n ti ń yọ́ bàbà.*+   Èèyàn ń borí òkùnkùn;Ó ń wá ibi gbogbo nínú ìṣúdùdù àti òkùnkùn,Ó ń wá òkúta iyebíye.*   Ó gbẹ́ ihò jìnnà sí ibi tí àwọn èèyàn ń gbé,Láwọn ibi tí wọ́n ti gbàgbé, tó jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbà kọjá;Àwọn èèyàn kan sọ̀ kalẹ̀, wọ́n sì rọ̀ dirodiro.   Oúnjẹ ń hù lórí ilẹ̀;Àmọ́ nísàlẹ̀, nǹkan ń dà rú, bí ìgbà tí iná ń jó.*   Sàfáyà wà nínú òkúta níbẹ̀,Wúrà sì wà nínú iyẹ̀pẹ̀.   Kò sí ẹyẹ aṣọdẹ tó mọ ọ̀nà débẹ̀;Ojú àwòdì dúdú kò rí i.   Àwọn ẹranko ńlá ò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ rí;Ọmọ kìnnìún ò rìn kiri níbẹ̀.   Èèyàn fi ọwọ́ rẹ̀ lu akọ òkúta;Ó dojú àwọn òkè dé níbi ìpìlẹ̀ wọn. 10  Ó la ọ̀nà sínú àpáta fún omi;+Ojú rẹ̀ ń rí gbogbo ohun tó ṣeyebíye. 11  Ó ń sé àwọn orísun odò,Ó sì ń mú àwọn ohun tó pa mọ́ wá sínú ìmọ́lẹ̀. 12  Àmọ́ ibo la ti lè rí ọgbọ́n,+Ibo sì ni orísun òye?+ 13  Kò sí èèyàn tó mọ bó ṣe níye lórí tó,+A ò sì lè rí i ní ilẹ̀ alààyè. 14  Ibú omi sọ pé, ‘Kò sí nínú mi!’ Òkun sì sọ pé, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi!’+ 15  Kò ṣeé fi ògidì wúrà rà;A kò sì lè díwọ̀n fàdákà láti fi pààrọ̀ rẹ̀.+ 16  Kò ṣeé fi wúrà Ófírì rà,+Kò sì ṣeé fi òkúta ónísì tó ṣọ̀wọ́n àti sàfáyà rà. 17  Wúrà àti gíláàsì kò ṣeé fi wé e;A kò lè fi ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi wúrà tó dáa* ṣe pààrọ̀ rẹ̀.+ 18  A ò lè mẹ́nu kan iyùn àti òkúta kírísítálì,+Torí ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju àpò tí péálì kún inú rẹ̀. 19  Tópásì + ti Kúṣì kò ṣeé fi wé e;Ògidì wúrà pàápàá kò lè rà á. 20  Àmọ́ ibo ni ọgbọ́n ti wá,Ibo sì ni orísun òye?+ 21  Ó ti fara sin kúrò lójú gbogbo ohun alààyè,+Ó sì pa mọ́ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. 22  Ìparun àti ikú sọ pé,‘Ìròyìn rẹ̀ nìkan ló dé etí wa.’ 23  Ọlọ́run mọ bí a ṣe lè rí i;Òun nìkan ló mọ ibi tó ń gbé,+ 24  Torí ó ń wo ayé títí dé àwọn ìkángun rẹ̀,Ó sì ń rí gbogbo ohun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ 25  Nígbà tó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,*+Tó sì díwọ̀n omi,+ 26  Nígbà tó gbé ìlànà kalẹ̀ fún òjò,+Tó sì lànà fún ìjì tó ń sán ààrá nínú ìkùukùu,*+ 27  Ó wá rí ọgbọ́n, ó sì ṣàlàyé rẹ̀;Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò. 28  Ó sì sọ fún èèyàn pé: ‘Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n,+Yíyẹra fún ìwà burúkú sì ni òye.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “da bàbà jáde.”
Ní Héb., “òkúta.”
Ó jọ pé bí wọ́n ṣe ń wa kùsà ló ń sọ.
Tàbí “tí wọ́n yọ́ mọ́.”
Ní Héb., “ìwọ̀n.”
Tàbí “àwọsánmà.”