Jóòbù 31:1-40
31 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú.+
Ṣé ó wá yẹ kí n máa tẹjú mọ́ wúńdíá?+
2 Kí ló wá máa jẹ́ ìpín mi látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lókè,Ogún wo ni màá gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè lókè?
3 Ṣebí jàǹbá ń dúró de ẹni burúkú,Àjálù sì ń dúró de àwọn aṣebi?+
4 Ṣebí ó ń rí àwọn ọ̀nà mi,+Tó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
5 Ṣé mo ti rìn nínú àìṣòótọ́* rí?
Ṣé ẹsẹ̀ mi ti yára ṣe ẹ̀tàn ni?+
6 Kí Ọlọ́run wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n tó péye;+Ó máa wá mọ ìwà títọ́ mi.+
7 Tí ẹsẹ̀ mi bá yà kúrò lọ́nà,+Tàbí tí ọkàn mi bá tẹ̀ lé ojú mi,+Tàbí tí ọwọ́ mi di aláìmọ́,
8 Kí n fún irúgbìn, kí ẹlòmíì sì jẹ ẹ́,+Kí wọ́n sì fa ohun tí mo gbìn* tu.
9 Tí ọkàn mi bá ti fà sí obìnrin kan,+Tí mo sì lúgọ+ sẹ́nu ọ̀nà ọmọnìkejì mi,
10 Kí ìyàwó mi lọ ọkà fún ọkùnrin míì,Kí àwọn ọkùnrin míì sì bá a lò pọ̀.*+
11 Torí ìwà àìnítìjú nìyẹn,Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́+ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà.
12 Ó máa jẹ́ iná tó ń jẹ nǹkan run tó sì ń run nǹkan,*+Tó ń run gbòǹgbò èso mi látòkè délẹ̀ pàápàá.*
13 Tí mi ò bá ka ẹ̀tọ́ àwọn ìránṣẹ́kùnrin tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mí,*
14 Kí ni mo lè ṣe tí Ọlọ́run bá kò mí lójú?
Kí ni mo lè sọ tó bá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+
15 Ṣebí Ẹni tó dá mi nínú ilé ọlẹ̀ ló dá àwọn náà?+
Ǹjẹ́ kì í ṣe Ẹnì kan náà ló mọ wá kí wọ́n tó bí wa?*+
16 Tí mo bá kọ̀ láti fún àwọn aláìní ní ohun tí wọ́n fẹ́,+Tàbí tí mo mú kí opó ba ojú jẹ́;*+
17 Tí mo bá dá jẹ oúnjẹ mi,Tí mi ò fún àwọn ọmọ aláìlóbìí+ nínú rẹ̀;
18 (Torí láti ìgbà ọ̀dọ́ mi ni ọmọ aláìlóbìí* ti wà lọ́dọ̀ mi bí ẹni pé èmi ni bàbá rẹ̀,Mo sì ń tọ́jú opó* láti kékeré.*)
19 Tí mo bá rí ẹnikẹ́ni tó ń ṣègbé torí kò ní aṣọ,Tàbí aláìní tí kò ní ohun tó máa fi bora;+
20 Tí kò* bá súre fún mi,+Bó ṣe ń fi irun àgùntàn mi mú kí ara rẹ̀ móoru;
21 Tí mo bá fi ẹ̀ṣẹ́ mi halẹ̀ mọ́ ọmọ aláìlóbìí,+Nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnubodè ìlú;*+
22 Kí apá* mi yẹ̀ kúrò ní èjìká mi,Kí apá mi sì kán ní ìgúnpá.*
23 Torí ẹ̀rù àjálù látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bà mí,Mi ò sì lè dúró níwájú iyì rẹ̀.
24 Tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé wúrà,Àbí tí mo sọ fún wúrà tó dáa pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi!’+
25 Tó bá jẹ́ ọrọ̀ rẹpẹtẹ+ tí mo ní ló ń fún mi láyọ̀,Torí mo ti kó ọ̀pọ̀ ohun ìní jọ;+
26 Tí mo bá rí i tí oòrùn ń ràn,*Tàbí tí òṣùpá ń lọ nínú iyì rẹ̀;+
27 Tí ọkàn mi wá ń dọ́gbọ́n fà sí wọn,Tí mo sì fẹnu ko ọwọ́ mi láti jọ́sìn wọn;+
28 Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà ni,Torí màá ti fìyẹn sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lókè.
29 Ṣé inú mi ti dùn rí torí pé ọ̀tá mi pa run,+Tàbí kí n fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun burúkú ṣẹlẹ̀ sí i?
30 Mi ò jẹ́ kí ẹnu mi mú kí n dẹ́ṣẹ̀ rí,Pé kí n búra pé kí ẹ̀mí* rẹ̀ bọ́.+
31 Ṣebí àwọn èèyàn tó wà ní àgọ́ mi ti sọ pé,‘Ǹjẹ́ a lè rí ẹnikẹ́ni tí kò tíì jẹ oúnjẹ* rẹ̀ ní àjẹtẹ́rùn?’+
32 Kò sí àlejò* tó sun ìta mọ́jú;+Mo ṣí ilẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún arìnrìn-àjò.
33 Ṣé mo ti gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ rí bíi ti àwọn èèyàn yòókù,+Pé kí n fi àṣìṣe mi pa mọ́ sínú àpò aṣọ mi?
34 Ṣé mo bẹ̀rù ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa ṣe,Àbí jìnnìjìnnì bá mi nítorí bí àwọn ìdílé yòókù ṣe ń pẹ̀gàn mi,Tí mo wá dákẹ́, tí ẹ̀rù sì bà mí láti jáde?
35 Ká ní ẹnì kan lè fetí sí mi ni!+
Ǹ bá buwọ́ lùwé sí ohun tí mo sọ.*
Kí Olódùmarè dá mi lóhùn!+
Ká ní ẹni tó fẹ̀sùn kàn mí ti kọ ẹ̀sùn náà sínú ìwé ni!
36 Màá gbé e lé èjìká mi,Màá sì dè é mọ́ orí mi bí adé.
37 Màá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé fún un;Màá fìgboyà lọ bá a, bí ìjòyè ti ń ṣe.
38 Tí ilẹ̀ mi bá ké jáde sí mi,Tí àwọn poro rẹ̀ sì jọ ń sunkún;
39 Tí mo bá ti jẹ èso rẹ̀ láìsan owó,+Tàbí tí mo mú kí àwọn* tó ni ín máa dààmú;+
40 Kí ẹ̀gún hù jáde fún mi dípò àlìkámà*Àti èpò tó ń rùn dípò ọkà bálì.”
Ibí ni ọ̀rọ̀ Jóòbù parí sí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn.”
^ Tàbí “àwọn àtọmọdọ́mọ mi.”
^ Ní Héb., “kúnlẹ̀ sórí rẹ̀.”
^ Ní Héb., “iná ajẹnirun.”
^ Tàbí “fa gbòǹgbò èso mi pàápàá tu.”
^ Tàbí “pè mí lẹ́jọ́.”
^ Ní Héb., “nínú ilé ọlẹ̀.”
^ Ní Héb., “kí ojú opó kọṣẹ́.”
^ Ní Héb., “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá mi.”
^ Ní Héb., “rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ó.”
^ Ní Héb., “Tí abẹ́nú rẹ̀ kò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tí mo rí i pé wọ́n tì mí lẹ́yìn ní ẹnubodè ìlú.”
^ Tàbí “ibi palaba èjìká.”
^ Tàbí “kúrò ní ojúhò rẹ̀; kúrò ní egungun òkè rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀ ń tàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ẹran.”
^ Tàbí “àjèjì.”
^ Tàbí “Ìbuwọ́lùwé mi rèé.”
^ Tàbí “ọkàn àwọn.”
^ Tàbí “wíìtì.”