Jóòbù 36:1-33
36 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:
2 “Ní sùúrù fún mi díẹ̀ sí i kí n lè ṣàlàyé,Torí mo ṣì ní ohun tí mo fẹ́ gbẹnu sọ fún Ọlọ́run.
3 Màá sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ohun ti mo mọ̀,Màá sì ka Aṣẹ̀dá mi sí olódodo.+
4 Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe irọ́;Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé+ nìyí níwájú rẹ.
5 Lóòótọ́, Ọlọ́run lágbára,+ kì í sì í kọ ẹnì kankan sílẹ̀;Agbára òye* rẹ̀ pọ̀ gan-an.
6 Kò ní dá ẹ̀mí àwọn ẹni burúkú sí,+Àmọ́ ó ń dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ bó ṣe tọ́.+
7 Kì í gbé ojú rẹ̀ kúrò lára àwọn olódodo;+Ó ń fi wọ́n sórí ìtẹ́ pẹ̀lú àwọn ọba,*+ ó sì gbé wọn ga títí láé.
8 Àmọ́ tí a bá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,Tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9 Ó ń fi ohun tí wọ́n ṣe hàn wọ́n,Ẹ̀ṣẹ̀ tí ìgbéraga mú kí wọ́n dá.
10 Ó ń ṣí etí wọn kí wọ́n lè gba ìtọ́sọ́nà,Ó sì ń sọ fún wọn pé kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú.+
11 Tí wọ́n bá ṣègbọràn tí wọ́n sì sìn ín,Nǹkan á máa lọ dáadáa fún wọn jálẹ̀ ọjọ́ ayé wọn,
Àwọn ọdún wọn á sì dùn.+
12 Àmọ́ tí wọn ò bá ṣègbọràn, idà* máa pa wọ́n run,+Wọ́n sì máa kú láìní ìmọ̀.
13 Àwọn tí kò mọ Ọlọ́run* nínú ọkàn wọn máa ń di ìbínú sínú.
Wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́ kódà nígbà tó bá dè wọ́n.
14 Wọ́n kú* ní kékeré,+Ọ̀dọ̀ àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti lo ìgbésí ayé wọn.*+
15 Àmọ́ Ọlọ́run* máa ń gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀;Ó ń ṣí etí wọn nígbà tí wọ́n ń ni wọ́n lára.
16 Ó ń fà ọ́ kúrò ní bèbè ìdààmú+Wá sí ibi tó fẹ̀, tí kò sí ìdílọ́wọ́,+Tí oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ ti wà lórí tábìlì rẹ láti tù ọ́ nínú.+
17 Ìdájọ́ tó máa dé sórí ẹni burúkú máa wá tẹ́ ọ lọ́rùn,+Nígbà tí a bá ṣèdájọ́ tí òdodo sì lékè.
18 Àmọ́ rí i pé ìbínú ò sún ọ ṣe ìkà,*+Má sì jẹ́ kí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gọbọi ṣì ọ́ lọ́nà.
19 Ṣé igbe tí ò ń ké fún ìrànlọ́wọ́,Tàbí gbogbo bí o ṣe ń sapá gidigidi lè gbà ọ́ lọ́wọ́ wàhálà?+
20 Má ṣe retí òru,Tí àwọn èèyàn kì í sí ní àyè wọn.
21 Ṣọ́ra kí o má lọ hùwà àìtọ́,Kí o wá yan èyí dípò ìyà.+
22 Wò ó! A gbé Ọlọ́run ga nínú agbára rẹ̀;Olùkọ́ wo ló dà bí rẹ̀?
23 Ta ló ń darí ọ̀nà rẹ̀,*+Tàbí tó lè sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe ò dáa’?+
24 Rántí gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,+Èyí tí àwọn èèyàn fi kọrin.+
25 Gbogbo aráyé ti rí i,Ẹni kíkú ń wò ó láti ọ̀ọ́kán.
26 Àní, Ọlọ́run tóbi ju bí a ṣe lè mọ̀;+Iye àwọn ọdún rẹ̀ kọjá òye wa.*+
27 Ó ń fa àwọn ẹ̀kán omi sókè;+Omi inú àwọsánmà* rẹ̀ ń di òjò;
28 Àwọsánmà* wá rọ òjò;+Ó rọ̀ sórí aráyé.
29 Ṣé ẹnikẹ́ni lè lóye àwọn ìpele ìkùukùu,*Ààrá tó ń sán láti àgọ́* rẹ̀?+
30 Wo bó ṣe na mànàmáná*+ rẹ̀ sórí rẹ̀,Tó sì bo ìsàlẹ̀* òkun mọ́lẹ̀.
31 Ó ń fi èyí bójú tó* àwọn èèyàn;Ó ń fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ.+
32 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ bo mànàmáná,Ó sì dojú rẹ̀ kọ ohun tó fojú sùn.+
33 Ààrá rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀,Ẹran ọ̀sìn pàápàá ń sọ ẹni* tó ń bọ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Ó ń fi àwọn ọba jẹ.”
^ Tàbí “ohun ìjà (ohun ọṣẹ́).”
^ Tàbí “Àwọn apẹ̀yìndà.”
^ Tàbí “Ọkàn wọn kú.”
^ Tàbí kó jẹ́, “parí ayé wọn.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Tàbí “pàtẹ́wọ́ ìkà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ti yẹ ọ̀nà rẹ̀ wò; ti pè é kó wá jíhìn.”
^ Tàbí “Àwámáridìí ni iye àwọn ọdún rẹ̀.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”
^ Tàbí “Ìkùukùu.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Ní Héb., “àtíbàbà.”
^ Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀.”
^ Ní Héb., “gbòǹgbò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “gbèjà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ohun.”