Léfítíkù 21:1-24

  • Kí àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ kí wọ́n má sì di ẹlẹ́gbin (1-9)

  • Àlùfáà àgbà ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ (10-15)

  • Àwọn àlùfáà ò gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan lára (16-24)

21  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+  Àmọ́ ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí ẹni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn, ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀,  ó sì lè fi arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó bá jẹ́ wúńdíá tó wà nítòsí rẹ̀, tí kò sì tíì lọ́kọ.  Kò gbọ́dọ̀ fi obìnrin tó fẹ́ ọkọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin tàbí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.  Kí wọ́n má ṣe fá orí wọn,+ kí wọ́n má sì fá eteetí irùngbọ̀n wọn tàbí kí wọ́n fi nǹkan ya ara wọn.+  Kí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn,+ kí wọ́n má sì sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di aláìmọ́,+ torí àwọn ló ń mú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá, oúnjẹ* Ọlọ́run wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+  Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó,+ obìnrin tí wọ́n ti bá sùn tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀,+ torí àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀.  Kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ torí òun ló ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá. Kó jẹ́ mímọ́ sí ọ, torí èmi Jèhófà, tó ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+  “‘Tí ọmọbìnrin àlùfáà bá ṣe aṣẹ́wó, tó tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bàbá rẹ̀ ló sọ di aláìmọ́. Kí ẹ fi iná sun+ ọmọbìnrin náà. 10  “‘Ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n da òróró àfiyanni+ sí lórí, tí wọ́n sì ti fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́* kó lè wọ aṣọ àlùfáà,+ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ̀ sílẹ̀ láìtọ́jú tàbí kó ya aṣọ rẹ̀.+ 11  Kó má ṣe sún mọ́ òkú ẹnikẹ́ni;*+ tó bá tiẹ̀ jẹ́ bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀, kò gbọ́dọ̀ fi wọ́n sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 12  Kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ibi mímọ́, kò sì gbọ́dọ̀ sọ ibi mímọ́ Ọlọ́run rẹ̀ di aláìmọ́,+ torí àmì ìyàsímímọ́, òróró àfiyanni ti Ọlọ́run rẹ̀,+ wà lórí rẹ̀. Èmi ni Jèhófà. 13  “‘Obìnrin tó jẹ́ wúńdíá+ ni kó fi ṣe aya. 14  Kó má ṣe fẹ́ opó, obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n ti bá sùn tàbí aṣẹ́wó; àmọ́ kó mú wúńdíá látinú àwọn èèyàn rẹ̀, kó fi ṣe aya. 15  Kó má sọ ọmọ* rẹ̀ di aláìmọ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ọ́ di mímọ́.’” 16  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 17  “Sọ fún Áárónì pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí tó bá ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá. 18  Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní àbùkù lára, kó má ṣe sún mọ́ tòsí: ọkùnrin tó fọ́jú tàbí tó yarọ tàbí tí ojú rẹ̀ ní àbùkù* tàbí tí apá tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn jù, 19  tàbí ọkùnrin tí egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ tàbí egungun ọwọ́ rẹ̀ kán, 20  abuké tàbí aràrá* tàbí ọkùnrin tí ojú ń dùn tàbí tó ní ifo tàbí làpálàpá tàbí tí nǹkan ṣe kórópọ̀n rẹ̀.+ 21  Ọkùnrin èyíkéyìí tó ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* àlùfáà Áárónì ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá. Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá torí ó ní àbùkù lára. 22  Ó lè jẹ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀, látinú àwọn ohun mímọ́ jù lọ+ àti àwọn ohun mímọ́.+ 23  Àmọ́, kó má ṣe sún mọ́ aṣọ ìdábùú,+ kó má sì sún mọ́ pẹpẹ,+ torí ó ní àbùkù lára; kó má sì sọ ibi mímọ́+ mi di aláìmọ́, torí èmi ni Jèhófà tó ń sọ wọ́n di mímọ́.’”+ 24  Mósè sì bá Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “búrẹ́dì,” ó ń tọ́ka sí àwọn ẹbọ.
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí tó ti kú.” Ní ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “òkú.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “tàbí tí imú rẹ̀ là.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó rù kan eegun.”
Ní Héb., “èso.”