Léfítíkù 23:1-44

  • Àwọn ọjọ́ mímọ́ àti àwọn àjọyọ̀ (1-44)

    • Sábáàtì (3)

    • Ìrékọjá (4, 5)

    • Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú (6-8)

    • Fífi àwọn àkọ́so ṣe ọrẹ (9-14)

    • Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (15-21)

    • Kíkórè bó ṣe tọ́ (22)

    • Àjọyọ̀ Ìró Kàkàkí (23-25)

    • Ọjọ́ Ètùtù (26-32)

    • Àjọyọ̀ Àtíbàbà (33-43)

23  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ tó jẹ́ ti Jèhófà tí ẹ máa kéde+ jẹ́ àpéjọ mímọ́. Èyí ni àwọn àjọyọ̀ mi àtìgbàdégbà:  “‘Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá,+ kó jẹ́ àpéjọ mímọ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Sábáàtì ni kó jẹ́ sí Jèhófà níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.+  “‘Èyí ni àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà tó jẹ́ ti Jèhófà, àwọn àpéjọ mímọ́ tí ẹ máa kéde ní àwọn àkókò tí mo yàn fún wọn:  Ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní+ ni kí ẹ ṣe Ìrékọjá+ fún Jèhófà.  “‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí ni Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ fún Jèhófà. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+  Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ agbára kankan.  Àmọ́ kí ẹ ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ keje, àpéjọ mímọ́ máa wà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.’”  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 10  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí màá fún yín, tí ẹ sì ti kórè oko rẹ̀, kí ẹ mú ìtí àkọ́so+ ìkórè yín wá fún àlùfáà.+ 11  Yóò sì fi ìtí náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà kí ẹ lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé sábáàtì ni kí àlùfáà fì í. 12  Ní ọjọ́ tí ẹ bá wá fi ìtí náà, kí ẹ fi ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ, kí ẹ fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà. 13  Ọrẹ ọkà rẹ̀ máa jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró, kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó máa mú òórùn dídùn* jáde. Ọrẹ ohun mímu rẹ̀ máa jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.* 14  Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ búrẹ́dì kankan, ọkà tí wọ́n yan tàbí ọkà tuntun títí di ọjọ́ yìí, títí ẹ ó fi mú ọrẹ Ọlọ́run yín wá. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 15  “‘Kí ẹ ka sábáàtì méje láti ọjọ́ tó tẹ̀ lé Sábáàtì, láti ọjọ́ tí ẹ mú ìtí ọrẹ fífì+ náà wá. Kí ọjọ́ àwọn ọ̀sẹ̀ náà pé. 16  Kí ẹ ka àádọ́ta (50) ọjọ́+ títí dé ọjọ́ tó tẹ̀ lé Sábáàtì keje, kí ẹ wá mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Jèhófà.+ 17  Kí ẹ mú ìṣù búrẹ́dì méjì wá láti ibi tí ẹ̀ ń gbé kí ẹ fi ṣe ọrẹ fífì. Ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* ni kí ẹ fi ṣe é. Kí ẹ fi ìwúkàrà sí i,+ kí ẹ sì yan án, kí ẹ fi ṣe àkọ́pọ́n èso fún Jèhófà.+ 18  Kí ẹ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá àti ọmọ akọ màlúù kan àti àgbò+ méjì, kí ẹ mú wọn wá pẹ̀lú àwọn búrẹ́dì náà. Kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Jèhófà pẹ̀lú ọrẹ ọkà wọn àti ọrẹ ohun mímu wọn, kó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà tó ń mú òórùn dídùn* jáde. 19  Kí ẹ fi ọmọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ kí ẹ sì fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ 20  Kí àlùfáà fì wọ́n síwá-sẹ́yìn pẹ̀lú àwọn búrẹ́dì tí ẹ fi ṣe àkọ́pọ́n èso, kó fi ṣe ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì náà. Kí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ sí Jèhófà fún àlùfáà náà.+ 21  Ní ọjọ́ yìí, kí ẹ kéde+ àpéjọ mímọ́ fún ara yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé. 22  “‘Tí ẹ bá kórè oko yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí oko yín tán, ẹ má sì ṣa ohun tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí ẹ kórè.+ Kí ẹ fi í sílẹ̀ fún àwọn aláìní*+ àti àjèjì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’” 23  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 24  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ kankan, kí ẹ fi ìró kàkàkí+ kéde rẹ̀ láti máa rántí, yóò jẹ́ àpéjọ mímọ́. 25  Ẹ má ṣiṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.’” 26  Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 27  “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni Ọjọ́ Ètùtù.+ Kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 28  Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ yìí gangan, torí ó jẹ́ ọjọ́ ètùtù tí wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín. 29  Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni* tí kò bá pọ́n ara rẹ̀ lójú* ní ọjọ́ yìí, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 30  Ẹnikẹ́ni* tó bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, ṣe ni màá pa á run kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 31  Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 32  Sábáàtì ló jẹ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú+ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù. Láti ìrọ̀lẹ́ dé ìrọ̀lẹ́ ni kí ẹ máa pa sábáàtì yín mọ́.” 33  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 34  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje yìí ni Àjọyọ̀ Àtíbàbà fún Jèhófà, ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é.+ 35  Àpéjọ mímọ́ yóò wà ní ọjọ́ kìíní, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 36  Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Àpéjọ ọlọ́wọ̀ ni. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 37  “‘Èyí ni àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ tó jẹ́ ti Jèhófà tí ẹ máa kéde pé wọ́n jẹ́ àpéjọ mímọ́,+ láti máa fi mú ọrẹ àfinásun wá fún Jèhófà: ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà+ tó jẹ́ ti ẹbọ àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ gẹ́gẹ́ bí ètò ojoojúmọ́. 38  Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àfikún sí ohun tí ẹ fi rúbọ ní àwọn sábáàtì Jèhófà+ àti àwọn ẹ̀bùn yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́+ àti àwọn ọrẹ àtinúwá yín,+ tí ẹ máa fún Jèhófà. 39  Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, tí ẹ bá ti kórè èso ilẹ̀ náà, kí ẹ fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà. Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ rárá. Ní ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ rárá.+ 40  Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ mú èso àwọn igi ńláńlá, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ,+ àwọn ẹ̀ka igi eléwé púpọ̀ àti àwọn igi pọ́pílà tó wà ní àfonífojì, kí ẹ sì yọ̀+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.+ 41  Ọjọ́ méje ni kí ẹ máa fi ṣe àjọyọ̀ náà fún Jèhófà lọ́dọọdún.+ Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni. Oṣù keje ni kí ẹ máa ṣe é. 42  Inú àtíbàbà ni kí ẹ gbé fún ọjọ́ méje.+ Kí gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì gbé inú àtíbàbà, 43  kí àwọn ìran yín tó ń bọ̀ lè mọ̀+ pé inú àtíbàbà ni mo mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nígbà tí mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’” 44  Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà ti Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà jẹ́ Lítà 4.4. Wo Àfikún B14.
Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà jẹ́ Lítà 4.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”
Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
Tàbí kó jẹ́, “tí kò bá gbààwẹ̀.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “Ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “ọkàn yín.”