Léfítíkù 4:1-35

  • Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ (1-35)

4  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnì* kan bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tó ṣe èyíkéyìí nínú ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe:  “‘Tí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tó sì mú kí àwọn èèyàn jẹ̀bi, kó mú akọ ọmọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+  Kó mú akọ màlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ níwájú Jèhófà, kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí akọ màlúù náà, kó sì pa á níwájú Jèhófà.+  Kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ náà wá mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, kó sì gbé e wá sínú àgọ́ ìpàdé;  kí àlùfáà náà ki ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà,+ kó sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje+ níwájú Jèhófà, síwájú aṣọ ìdábùú ibi mímọ́.  Kí àlùfáà náà tún fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àwọn ìwo pẹpẹ tùràrí onílọ́fínńdà,+ tó wà níwájú Jèhófà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun,+ tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  “‘Lẹ́yìn náà, kó yọ gbogbo ọ̀rá tó wà lára akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, títí kan ọ̀rá tó bo ìfun àti ọ̀rá tó yí ìfun ká  àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ rẹ̀. 10  Ohun kan náà tó yọ lára akọ màlúù ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ ni kó yọ. Kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. 11  “‘Àmọ́ ní ti awọ akọ màlúù náà àti gbogbo ẹran rẹ̀ pẹ̀lú orí, ẹsẹ̀, ìfun àti ìgbẹ́+ rẹ̀, 12  gbogbo ohun tó kù lára akọ màlúù náà, kí ó kó o lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tó mọ́, tí wọ́n ń da eérú* sí, kó sì sun ún lórí igi nínú iná.+ Ibi tí wọ́n ń da eérú sí ni kó ti sun ún. 13  “‘Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tí wọ́n sì jẹ̀bi, àmọ́ tí gbogbo ìjọ ò mọ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí wọ́n má ṣe,+ 14  tí wọ́n bá wá mọ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀, kí ìjọ mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì mú un wá síwájú àgọ́ ìpàdé. 15  Kí àwọn àgbààgbà àpéjọ náà gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, kí wọ́n sì pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà. 16  “‘Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé. 17  Kí àlùfáà náà ki ìka rẹ̀ bọnú ẹ̀jẹ̀ náà, kó sì wọ́n lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀méje níwájú Jèhófà, síwájú aṣọ ìdábùú.+ 18  Kó wá fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn ìwo pẹpẹ+ tó wà níwájú Jèhófà, èyí tó wà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun, tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 19  Kó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 20  Ohun tó ṣe sí akọ màlúù kejì tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni kó ṣe sí akọ màlúù náà. Bó ṣe máa ṣe é nìyẹn, kí àlùfáà ṣe ètùtù fún wọn,+ wọ́n á sì rí ìdáríjì. 21  Kó mú akọ màlúù náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó sì sun ún, bó ṣe sun akọ màlúù àkọ́kọ́.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọ+ ni. 22  “‘Tí ìjòyè+ kan bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tó ṣe ọ̀kan nínú gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe, tí ìjòyè náà sì jẹ̀bi, 23  tàbí tó wá mọ̀ pé òun ti ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ náà, kó mú akọ ọmọ ewúrẹ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá láti fi ṣe ọrẹ. 24  Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ọmọ ewúrẹ́ náà, kó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú Jèhófà.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 25  Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó fi sára àwọn ìwo+ pẹpẹ ẹbọ sísun, kó sì da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun.+ 26  Kó mú kí gbogbo ọ̀rá rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọ̀rá ẹbọ ìrẹ́pọ̀;+ àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò sì rí ìdáríjì. 27  “‘Tí ẹnì* kankan nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tó ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe,+ tí ẹni náà sì jẹ̀bi, 28  tàbí tó wá mọ̀ pé òun ti ṣẹ̀, kó mú abo ọmọ ewúrẹ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá láti fi rú ẹbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. 29  Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì pa á ní ibì kan náà tó ti pa ẹran ẹbọ sísun.+ 30  Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kó fi sára àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 31  Kó yọ gbogbo ọ̀rá+ rẹ̀, bó ṣe yọ ọ̀rá kúrò lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà; kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un, yóò sì rí ìdáríjì. 32  “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ àgùntàn ló fẹ́ mú wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, abo ọ̀dọ́ àgùntàn tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá. 33  Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó sì pa á bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun.+ 34  Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó fi sára àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun,+ kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 35  Kó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń yọ ọ̀rá ọmọ àgbò tí wọ́n fi ṣe ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”