Àkọsílẹ̀ Lúùkù 20:1-47
20 Lọ́jọ́ kan, bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì, tó sì ń kéde ìhìn rere, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà wá,
2 wọ́n sì bi í pé: “Sọ fún wa, àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí?”+
3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn:
4 Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?”
5 Wọ́n jọ rò ó láàárín ara wọn, wọ́n ní: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’
6 Àmọ́ tí a bá sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn,’ gbogbo èèyàn ló máa sọ wá lókùúta, torí ó dá wọn lójú pé wòlíì ni Jòhánù.”+
7 Nítorí náà, wọ́n fèsì pé àwọn ò mọ orísun rẹ̀.
8 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”
9 Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àpèjúwe yìí fún àwọn èèyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà,+ ó gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fúngbà díẹ̀.+
10 Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà, kí wọ́n lè fún un lára èso ọgbà àjàrà náà. Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo.+
11 Àmọ́ ó tún rán ẹrú míì. Wọ́n lu ìyẹn náà, wọ́n dójú tì í,* wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo.
12 Ó tún rán ẹnì kẹta; wọ́n ṣe ẹni yìí náà léṣe, wọ́n sì jù ú síta.
13 Ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá sọ pé, ‘Kí ni kí n ṣe? Màá rán ọmọ mi ọ̀wọ́n.+ Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún un.’
14 Nígbà tí àwọn tó ń dáko náà tajú kán rí i, wọ́n rò ó láàárín ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ ká pa á, kí ogún náà lè di tiwa.’
15 Torí náà, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa wá ṣe sí wọn?
16 Ó máa wá, ó máa pa àwọn tó ń dáko yìí, á sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì.”
Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Kí ìyẹn má ṣẹlẹ̀ láé!”
17 Àmọ́ ó wò wọ́n tààràtà, ó sì sọ pé: “Kí wá ni èyí túmọ̀ sí, ohun tí a kọ pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé’?*+
18 Gbogbo ẹni tó bá kọ lu òkúta yẹn máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”
19 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn olórí àlùfáà wá ń wá bí ọwọ́ wọn ṣe máa tẹ̀ ẹ́ ní wákàtí yẹn gangan, àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń fi àpèjúwe yìí bá wí.+
20 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣọ́ ọ dáadáa, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n háyà ní bòókẹ́lẹ́ jáde pé kí wọ́n díbọ́n pé àwọn jẹ́ olódodo, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un,+ kí wọ́n lè fà á lé ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà.
21 Wọ́n bi í pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé o máa ń sọ̀rọ̀, o sì máa ń kọ́ni lọ́nà tó tọ́, o kì í ṣe ojúsàájú rárá, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́:
22 Ṣé ó bófin mu* fún wa láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?”
23 Àmọ́ ó rí i pé alárèékérekè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé:
24 “Ẹ fi owó dínárì* kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ta ló wà níbẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì.”
25 Ó sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+
26 Wọn ò wá lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un níwájú àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì dákẹ́.
27 Àmọ́ àwọn kan lára àwọn Sadusí, àwọn tó sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+
28 “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé, ‘Tí arákùnrin ọkùnrin kan bá kú, tó fi ìyàwó sílẹ̀, àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’+
29 Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ ó kú láìbímọ.
30 Bákan náà ni ẹnì kejì
31 àti ẹnì kẹta náà fẹ́ ẹ. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn méjèèje; wọ́n kú láìfi ọmọ kankan sílẹ̀.
32 Níkẹyìn, obìnrin náà kú.
33 Tó bá wá dìgbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.”
34 Jésù sọ fún wọn pé: “Àwọn ọmọ ètò àwọn nǹkan yìí* máa ń gbéyàwó, a sì máa ń fà wọ́n fún ọkọ,
35 àmọ́ àwọn tí a ti kà yẹ pé kí wọ́n jèrè ètò àwọn nǹkan yẹn àti àjíǹde òkú kì í gbéyàwó, a kì í sì í fà wọ́n fún ọkọ.+
36 Kódà, wọn ò lè kú mọ́, torí wọ́n dà bí àwọn áńgẹ́lì, ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n ní ti pé wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ àjíǹde.
37 Àmọ́ tó bá kan àjíǹde àwọn òkú, Mósè pàápàá jẹ́ ká mọ̀ nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, nígbà tó pe Jèhófà* ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’+
38 Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè, torí lójú rẹ̀,* gbogbo wọn wà láàyè.”+
39 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin wá dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, ohun tí o sọ dáa.”
40 Torí wọn ò ní ìgboyà láti bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.
41 Ó wá bi wọ́n pé: “Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé ọmọ Dáfídì ni Kristi?+
42 Torí Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”’+
44 Torí náà, Dáfídì pè é ní Olúwa; báwo ló ṣe wá jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45 Bí gbogbo èèyàn ṣe ń fetí sílẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé:
46 “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa rìn kiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà, wọ́n fẹ́ ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́,+
47 wọ́n ń jẹ ilé* àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà tó gùn láti ṣe ojú ayé.* Ìdájọ́ tó le* gan-an ni àwọn yìí máa gbà.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.”
^ Ní Grk., “olórí igun.”
^ Tàbí “tọ́.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “lójú ìwòye rẹ̀.”
^ Tàbí “tó dáa jù.”
^ Tàbí “ohun ìní.”
^ Tàbí “láti ṣe bojúbojú.”
^ Tàbí “wúwo.”