Àkọsílẹ̀ Lúùkù 22:1-71

  • Àwọn àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù (1-6)

  • Wọ́n múra Ìrékọjá tó gbẹ̀yìn sílẹ̀ (7-13)

  • Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ (14-20)

  • “Èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì” (21-23)

  • Wọ́n bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tó tóbi jù (24-27)

  • Jésù bá wọn dá májẹ̀mú ìjọba (28-30)

  • Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (31-34)

  • Ìdí tó fi yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀; idà méjì (35-38)

  • Àdúrà Jésù lórí Òkè Ólífì (39-46)

  • Wọ́n mú Jésù (47-53)

  • Pétérù sẹ́ Jésù (54-62)

  • Wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ (63-65)

  • Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (66-71)

22  Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, tí wọ́n ń pè ní Ìrékọjá,+ ti ń sún mọ́lé.+  Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń wá ọ̀nà tó máa dáa gan-an láti rẹ́yìn rẹ̀,+ torí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn.+  Sátánì wá wọnú Júdásì, tí wọ́n ń pè ní Ìsìkáríọ́tù, tó wà lára àwọn Méjìlá náà,+  ó sì lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa fà á lé wọn lọ́wọ́.+  Èyí múnú wọn dùn gan-an, wọ́n sì gbà láti fún un ní owó fàdákà.+  Torí náà, ó gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́ níbi tí kò sí èrò.  Nígbà tó di ọjọ́ àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹran Ìrékọjá rúbọ,+  Jésù rán Pétérù àti Jòhánù lọ, ó ní: “Ẹ lọ pèsè Ìrékọjá sílẹ̀ fún wa ká lè jẹ ẹ́.”+  Wọ́n sọ fún un pé: “Ibo lo fẹ́ ká pèsè rẹ̀ sí?” 10  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Tí ẹ bá ti wọnú ìlú náà, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tó bá wọ̀.+ 11  Kí ẹ sì sọ fún ẹni tó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ ní ká bi ọ́ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ 12  Ọkùnrin yẹn sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀.” 13  Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá. 14  Nígbà tí wákàtí náà wá tó, ó jókòó* sídìí tábìlì pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì.+ 15  Ó sọ fún wọn pé: “Ó wù mí gan-an pé kí n jẹ Ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà; 16  torí mò ń sọ fún yín pé, mi ò ní jẹ ẹ́ mọ́ títí a fi máa mú un ṣẹ nínú Ìjọba Ọlọ́run.” 17  Ó wá gba ife kan, ó dúpẹ́, ó sì sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ gbé e yí ká láàárín ara yín, 18  torí mò ń sọ fún yín, láti ìsinsìnyí lọ, mi ò tún ní mu àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́ títí Ìjọba Ọlọ́run fi máa dé.” 19  Bákan náà, ó mú búrẹ́dì,+ ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fún wọn, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ara mi,+ tí a máa fúnni nítorí yín.+ Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 20  Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá,*+ tí a máa dà jáde nítorí yín.+ 21  “Àmọ́ ẹ wò ó! ọwọ́ èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì.+ 22  Torí, ní tòótọ́, Ọmọ èèyàn ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ bí a ṣe pinnu rẹ̀; + síbẹ̀, ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi í léni lọ́wọ́ gbé!”+ 23  Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ láàárín ara wọn nípa ẹni tó máa ṣe èyí nínú wọn lóòótọ́.+ 24  Àmọ́, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tí wọ́n kà sí ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 25  Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, wọ́n sì máa ń pe àwọn tó ní àṣẹ lórí wọn ní Olóore.+ 26  Àmọ́ kò yẹ kí ẹ̀yin ṣe bẹ́ẹ̀.+ Kí ẹni tó tóbi jù láàárín yín dà bí ẹni tó kéré jù,+ kí ẹni tó jẹ́ aṣáájú sì dà bí ẹni tó ń ṣe ìránṣẹ́. 27  Torí ta ló tóbi jù, ṣé ẹni tó ń jẹun* ni àbí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá?* Ṣebí ẹni tó ń jẹun* ni? Àmọ́ mo wà láàárín yín bí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá.*+ 28  “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí+ nígbà àdánwò;+ 29  mo sì bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú,+ 30  kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ní tábìlì mi nínú Ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+ 31  “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì ti béèrè pé òun fẹ́ gba gbogbo yín, kó lè kù yín bí àlìkámà.*+ 32  Àmọ́ mo ti bá yín bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa yẹ̀; + ní ti ìwọ, gbàrà tí o bá pa dà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”+ 33  Ó wá sọ fún un pé: “Olúwa, mo ṣe tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n, kí n sì bá ọ kú.”+ 34  Àmọ́ ó sọ pé: “Mò ń sọ fún ọ, Pétérù, àkùkọ ò ní kọ lónìí tí wàá fi sẹ́ lẹ́ẹ̀mẹta pé o ò mọ̀ mí.”+ 35  Ó tún sọ fún wọn pé: “Nígbà tí mo ní kí ẹ lọ láìgbé àpò owó, àpò oúnjẹ àti bàtà,+ ẹ ò ṣaláìní nǹkan kan, àbí ẹ ṣaláìní?” Wọ́n dáhùn pé: “Rárá!” 36  Ó wá sọ fún wọn pé: “Àmọ́ ní báyìí, kí ẹni tó ní àpò owó gbé e, bẹ́ẹ̀ náà ni àpò oúnjẹ, kí ẹni tí kò bá ní idà ta aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, kó sì ra ọ̀kan. 37  Torí mò ń sọ fún yín pé ohun tó wà ní àkọsílẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe sí mi délẹ̀délẹ̀, pé, ‘A kà á mọ́ àwọn arúfin.’+ Torí èyí ń ṣẹ sí mi lára.”+ 38  Wọ́n wá sọ pé: “Olúwa, wò ó! idà méjì nìyí.” Ó sọ fún wọn pé: “Ó ti tó.” 39  Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Òkè Ólífì bó ṣe máa ń ṣe, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sì tẹ̀ lé e.+ 40  Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”+ 41  Ó wá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sí ìwọ̀n ibi tí òkúta lè dé tí wọ́n bá jù ú látọ̀dọ̀ wọn, ó kúnlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, 42  ó ní: “Baba, tí o bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Àmọ́, ìfẹ́ rẹ ni kó ṣẹ, kì í ṣe tèmi.”+ 43  Áńgẹ́lì kan wá fara hàn án láti ọ̀run, ó sì fún un lókun.+ 44  Àmọ́ ìdààmú bá a gan-an débi pé ṣe ló túbọ̀ ń gbàdúrà taratara;+ òógùn rẹ̀ sì dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀. 45  Nígbà tó dìde níbi tó ti ń gbàdúrà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń tòògbé, ẹ̀dùn ọkàn ti mú kó rẹ̀ wọ́n gan-an.+ 46  Ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sùn? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.”+ 47  Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! àwọn èrò dé, ọkùnrin tí wọ́n ń pè ní Júdásì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà, ló ṣáájú wọn, ó sì sún mọ́ Jésù kó lè fẹnu kò ó lẹ́nu.+ 48  Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Júdásì, ṣé o fẹ́ fi ẹnu ko Ọmọ èèyàn lẹ́nu kí o lè dalẹ̀ rẹ̀ ni?” 49  Nígbà tí àwọn tó yí i ká rí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa, ṣé ká fi idà bá wọn jà?” 50  Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ 51  Àmọ́ Jésù fèsì pé: “Ó tó.” Ló bá fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn. 52  Jésù wá sọ fún àwọn olórí àlùfáà, àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n wá a wá síbẹ̀ pé: “Ṣé olè lẹ fẹ́ wá mú ni, tí ẹ fi kó idà àti kùmọ̀ dání?+ 53  Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì lójoojúmọ́,+ ẹ ò fọwọ́ kàn mí.+ Àmọ́ wákàtí yín àti ti àṣẹ òkùnkùn nìyí.”+ 54  Wọ́n wá fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì mú un lọ,+ wọ́n mú un wá sínú ilé àlùfáà àgbà; àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé wọn ní òkèèrè.+ 55  Nígbà tí wọ́n dáná láàárín àgbàlá, tí wọ́n sì jọ jókòó, Pétérù jókòó láàárín wọn.+ 56  Àmọ́ ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tó jókòó síbi iná náà, ó wò ó dáadáa, ó sì sọ pé: “Ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.” 57  Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Ìwọ obìnrin yìí, mi ò mọ̀ ọ́n.” 58  Nígbà tó ṣe díẹ̀, ẹlòmíì rí i, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà lára wọn.” Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó ọkùnrin yìí, mi ò sí lára wọn.+ 59  Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, ọkùnrin míì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé: “Ó dájú pé ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni!” 60  Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin yìí, mi ò mọ ohun tó ò ń sọ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ kọ. 61  Ni Olúwa bá yíjú pa dà, ó sì wo Pétérù tààràtà, Pétérù wá rántí ohun tí Olúwa sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 62  Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi. 63  Àwọn ọkùnrin tó mú Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń lù ú;+ 64  lẹ́yìn tí wọ́n sì fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n ń bi í pé: “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta lẹni tó gbá ọ?” 65  Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ òdì míì sí i. 66  Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kóra jọ,+ wọ́n sì mú un lọ sínú gbọ̀ngàn Sàhẹ́ndìrìn wọn, wọ́n sọ pé: 67  “Sọ fún wa, tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà.”+ Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ sọ fún yín, ẹ ò ní gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ rárá. 68  Bákan náà, tí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ ò ní dáhùn. 69  Àmọ́ láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ èèyàn+ máa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”+ 70  Ni gbogbo wọn bá sọ pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ pé èmi ni.” 71  Wọ́n sọ pé: “Kí la tún nílò ẹ̀rí fún? Torí a ti fetí ara wa gbọ́ ọ lẹ́nu òun fúnra rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “tí a dá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mi.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́.”
Tàbí “tó jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “ṣe ìránṣẹ́.”
Tàbí “tó jókòó nídìí tábìlì.”
Tàbí “wíìtì.”