Àkọsílẹ̀ Mátíù 4:1-25
4 Ẹ̀mí wá darí Jésù lọ sínú aginjù kí Èṣù+ lè dán an wò.+
2 Lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á.
3 Adánniwò náà+ wá bá a, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.”
4 Àmọ́ ó dáhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà* jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.’”+
5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí ìlú mímọ́,+ ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì,+
6 ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ’ àti pé ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+
7 Jésù sọ fún un pé: “A tún ti kọ ọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+
8 Èṣù tún mú un lọ sí òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.+
9 Ó sọ fún un pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”
10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
11 Èṣù wá fi í sílẹ̀,+ sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún un.+
12 Nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti mú Jòhánù,+ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Gálílì.+
13 Bákan náà, lẹ́yìn tó kúrò ní Násárẹ́tì, ó wá lọ ń gbé ní Kápánáúmù + lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní agbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì,
14 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé:
15 “Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní òdìkejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè!
16 Àwọn èèyàn tó jókòó sínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, ní ti àwọn tó jókòó sí agbègbè òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀+ tàn sórí wọn.”+
17 Àtìgbà yẹn lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, tó sì ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+
18 Bó ṣe ń rìn lọ létí Òkun Gálílì, ó rí àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n ń ju àwọ̀n sínú òkun, torí apẹja ni wọ́n.+
19 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.”+
20 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+
21 Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó rí àwọn méjì míì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀.+ Inú ọkọ̀ ojú omi ni wọ́n wà pẹ̀lú Sébédè bàbá wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, ó sì pè wọ́n.+
22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà àti bàbá wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e.
23 Ó lọ káàkiri gbogbo Gálílì,+ ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn,+ ó sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn láàárín àwọn èèyàn.+
24 Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Síríà, wọ́n sì gbé gbogbo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe, tí wọ́n sì ń joró wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ àwọn tó ní wárápá + àti àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn.
25 Torí náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tẹ̀ lé e láti Gálílì, Dekapólì,* Jerúsálẹ́mù, Jùdíà àti láti òdìkejì Jọ́dánì.