Míkà 2:1-13
2 “Àwọn tó ń gbìmọ̀ ìkà gbé,Tí wọ́n ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn!
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n gbèrò,Torí pé agbára wọn ká a.+
2 Oko olóko wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n sì gbà á;+Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gba ilé onílé;Wọ́n fi jìbìtì gba ilé mọ́ onílé lọ́wọ́,+Wọ́n gba ogún lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.
3 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Mò ń gbèrò àjálù kan sí ìdílé yìí,+ ẹ kò sì ní yè bọ́.*+
Ẹ kò ní lè gbéra ga mọ́,+ torí àkókò àjálù ló máa jẹ́.+
4 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa pa òwe fún yín,Wọn á sì dárò lórí yín.+
Wọ́n á sọ pé: “Ó ti pa wá run pátápátá!+
Ó ti gba ìpín àwọn èèyàn wa. Ó sì ti fún àwọn ẹlòmíì!+
Ó ti fún àwọn aláìṣòótọ́ ní ilẹ̀ wa.”
5 Torí náà, kò ní sí ẹnì kankan tó máa bá yín ta okùn,Láti fi pín ilẹ̀ nínú ìjọ Jèhófà.
6 Wọ́n ń pàrọwà fún wọn pé: “Ẹ má wàásù mọ́!
Kò yẹ kí wọ́n máa wàásù nípa àwọn nǹkan yìí;Ojú kò ní tì wá!”
7 Ilé Jékọ́bù, ṣé ohun tí àwọn èèyàn ń sọ ni pé:
“Àbí Jèhófà* kò ní sùúrù mọ́ ni?
Ṣé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nìyí?”
Àbí, ṣé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn olódodo láǹfààní ni?
8 Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn mi ti sọ ara wọn di ọ̀tá.
Ẹ bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tó gbayì àti ẹ̀wù* lọ́rùn àwọn èèyàn ní gbangba,Lọ́rùn àwọn tó ń kọjá lọ tí ọkàn wọn sì balẹ̀ bí ẹni tó ń ti ogun bọ̀.
9 Ẹ lé àwọn obìnrin àwọn èèyàn mi kúrò nínú ilé tí wọ́n fẹ́ràn;Ògo tí mo fún àwọn ọmọ wọn lẹ gbà lọ́wọ́ wọn títí láé.
10 Ẹ dìde, kí ẹ máa lọ, torí ibí kì í ṣe ibi ìsinmi.
Torí ìwà àìmọ́ yín,+ ẹ máa pa run, ìparun pátápátá.+
11 Bí èèyàn kan bá wà tó ń lépa asán, tó ń tanni jẹ, tó sì ń parọ́ pé:
“Màá wàásù fún yín nípa wáìnì àti ọtí,”
Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan-an ni oníwàásù táwọn èèyàn yìí fẹ́!+
12 Ẹ̀yin ilé Jékọ́bù, èmi yóò kó gbogbo yín jọ;Ó dájú pé màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì jọ.+
Màá mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, bí àgùntàn ní ilé ẹran,Bí agbo ẹran ní pápá ìjẹko wọn;+Ariwo àwọn èèyàn máa gba ibẹ̀ kan.’+
13 Ẹni tó ń la ọ̀nà yóò lọ ṣáájú wọn;Wọ́n á la ọ̀nà, wọ́n á gba ẹnubodè kọjá, wọ́n á sì gba ibẹ̀ jáde.+
Ọba wọn yóò ṣáájú wọn,Jèhófà yóò sì ṣe olórí wọn.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ẹ kò sì ní lè yọ ọrùn yín.”
^ Ní Héb., “Àbí ẹ̀mí Jèhófà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kúrò lára ẹ̀wù.”