Nọ́ńbà 16:1-50
16 Kórà+ ọmọ Ísárì,+ ọmọ Kóhátì,+ ọmọ Léfì+ wá gbìmọ̀ pẹ̀lú Dátánì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù+ pẹ̀lú Ónì ọmọ Péléétì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì.+
2 Wọ́n dìtẹ̀ Mósè, àwọn àti igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìjòyè àpéjọ náà, àwọn tí a yàn nínú ìjọ, àwọn ọkùnrin tó lókìkí.
3 Wọ́n kóra jọ láti ta ko+ Mósè àti Áárónì, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín! Gbogbo àpéjọ yìí jẹ́ mímọ́,+ gbogbo wọn pátá, Jèhófà sì wà láàárín wọn.+ Kí ló dé tí ẹ fi ń gbé ara yín ga lórí ìjọ Jèhófà?”
4 Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ojú ẹsẹ̀ ló dojú bolẹ̀.
5 Ó sì sọ fún Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì í lẹ́yìn pé: “Tó bá di àárọ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ tirẹ̀+ àti ẹni tó jẹ́ mímọ́ àti ẹni tó gbọ́dọ̀ máa sún mọ́ ọn,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì yàn+ ló máa sún mọ́ ọn.
6 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Kí ìwọ Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn+ mú ìkóná,+
7 kí ẹ fi iná sí i, kí ẹ sì fi tùràrí sí i níwájú Jèhófà lọ́la, ẹni tí Jèhófà bá sì yàn,+ òun ni ẹni mímọ́. “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọmọ Léfì!”+
8 Mósè wá sọ fún Kórà pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Léfì.
9 Ṣé ohun kékeré lẹ rò pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe fún yín, bó ṣe yà yín sọ́tọ̀ nínú àpéjọ Ísírẹ́lì,+ tó ń jẹ́ kí ẹ máa wá síwájú òun láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, kí ẹ sì máa dúró níwájú àpéjọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún wọn,+
10 tó sì mú kí ìwọ àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ, àwọn ọmọ Léfì, sún mọ́ òun? Ṣé ó tún wá yẹ kí ẹ máa wá ọ̀nà láti gba iṣẹ́ àlùfáà?+
11 Torí náà, ṣe ni ìwọ àti gbogbo àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ tí ẹ kóra yín jọ ń bá Jèhófà jà. Kí wá ni ti Áárónì, tí ẹ fi ń kùn sí i?”+
12 Lẹ́yìn náà, Mósè ránṣẹ́ pe Dátánì àti Ábírámù,+ àwọn ọmọ Élíábù, àmọ́ wọ́n sọ pé: “A ò ní wá!
13 Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe, bí o ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, kí o lè wá pa wá sínú aginjù?+ Ṣé o tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di ọba* lé wa lórí ni?
14 Títí di báyìí, o ò tíì mú wa dé ilẹ̀ kankan tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ bẹ́ẹ̀ lo ò fún wa ní ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà kankan láti jogún. Ṣé o fẹ́ yọ ojú àwọn èèyàn yẹn ni? A ò ní wá!”
15 Inú bí Mósè gan-an, ó sì sọ fún Jèhófà pé: “Má bojú wo ọrẹ ọkà wọn. Mi ò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan lọ́wọ́ wọn, mi ò sì ṣe ìkankan nínú wọn léṣe.”+
16 Mósè wá sọ fún Kórà pé: “Kí ìwọ àti gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn wá síwájú Jèhófà lọ́la, ìwọ, àwọn àti Áárónì.
17 Kí kálukú mú ìkóná rẹ̀, kó fi tùràrí sí i, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan mú ìkóná rẹ̀ wá síwájú Jèhófà, kó jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250) ìkóná. Kí ìwọ àti Áárónì náà wà níbẹ̀, kí kálukú mú ìkóná rẹ̀ dání.”
18 Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn mú ìkóná rẹ̀, wọ́n sì fi iná àti tùràrí sí i, wọ́n dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú Mósè àti Áárónì.
19 Nígbà tí Kórà kó àwọn tó ń tì í lẹ́yìn,+ tí wọ́n jọ ń ta kò wọ́n jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà fara han gbogbo àpéjọ+ náà.
20 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé:
21 “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn yìí, kí n lè pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”+
22 Ni wọ́n bá wólẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run tó ni ẹ̀mí gbogbo èèyàn,*+ ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan ṣoṣo máa wá mú kí o bínú sí gbogbo àpéjọ+ yìí?”
23 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:
24 “Sọ fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ẹ kúrò nítòsí àgọ́ Kórà, Dátánì àti Ábírámù!’”+
25 Ni Mósè bá gbéra, ó lọ bá Dátánì àti Ábírámù, àwọn àgbààgbà+ Ísírẹ́lì sì tẹ̀ lé e.
26 Ó sọ fún àpéjọ náà pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kúrò nítòsí àgọ́ àwọn ọkùnrin burúkú yìí, ẹ má sì fara kan ohunkóhun tó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má bàa pa run nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
27 Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n kúrò nítòsí àgọ́ Kórà, Dátánì àti Ábírámù ní gbogbo àyíká wọn. Dátánì àti Ábírámù sì jáde wá, wọ́n dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn, títí kan àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
28 Mósè wá sọ pé: “Èyí á jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ló rán mi ní gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, kì í ṣe ohun tó kàn wù mí:*
29 Tó bá jẹ́ pé bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú làwọn èèyàn yìí máa kú, tó bá sì jẹ́ irú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbo aráyé ń jẹ làwọn náà máa jẹ, a jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ló rán mi.+
30 Àmọ́ bí Jèhófà bá ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí wọn, tí ilẹ̀ lanu,* tó sì gbé àwọn àti gbogbo ohun tó jẹ́ tiwọn mì, tí wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* láàyè, ẹ ó mọ̀ dájú pé àwọn ọkùnrin yìí ti hùwà àfojúdi sí Jèhófà.”
31 Bó ṣe sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé là sí méjì.+
32 Ilẹ̀ sì lanu,* ó gbé wọn mì pẹ̀lú agbo ilé wọn àti gbogbo àwọn èèyàn Kórà+ pẹ̀lú gbogbo ẹrù wọn.
33 Bí àwọn àti gbogbo èèyàn wọn ṣe lọ sínú Isà Òkú* láàyè nìyẹn, ilẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì pa run láàárín ìjọ+ náà.
34 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó yí wọn ká sì sá lọ nígbà tí wọ́n ń kígbe, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà wá kí ilẹ̀ má lọ gbé àwa náà mì!”
35 Iná sì wá látọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó jó igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin tó ń sun tùràrí+ run.
36 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:
37 “Sọ fún Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì pé kí ó kó àwọn ìkóná+ náà kúrò nínú iná, torí wọ́n jẹ́ mímọ́. Tún sọ fún un pé kó tú iná náà ká dáadáa.
38 Kí ẹ fi ìkóná àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ tí wọ́n sì fi ẹ̀mí ara wọn dí i ṣe àwọn irin pẹlẹbẹ tí ẹ máa fi bo pẹpẹ,+ torí iwájú Jèhófà ni wọ́n mú un wá, ó sì ti di mímọ́. Kó máa jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+
39 Àlùfáà Élíásárì wá kó àwọn ìkóná tí wọ́n fi bàbà ṣe, èyí tí àwọn tó jóná náà mú wá, ó sì fi wọ́n rọ ohun tí wọ́n á fi máa bo pẹpẹ,
40 bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ fún un. Yóò máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹnikẹ́ni tí kò tọ́ sí,* tí kì í ṣe ọmọ Áárónì kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti sun tùràrí níwájú Jèhófà+ àti pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ dà bíi Kórà àti àwọn tó ń tì í lẹ́yìn.+
41 Ní ọjọ́ kejì, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì+ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì ti pa àwọn èèyàn Jèhófà.”
42 Nígbà tí àwọn èèyàn náà kóra jọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí Mósè àti Áárónì, wọ́n wá yíjú sí àgọ́ ìpàdé, wò ó! ìkùukùu* bo àgọ́ náà, ògo Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn.+
43 Mósè àti Áárónì wá lọ síwájú àgọ́ ìpàdé,+
44 Jèhófà sì sọ fún Mósè pé:
45 “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ kúrò láàárín àpéjọ yìí, kí n lè pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”+ Ni wọ́n bá wólẹ̀.+
46 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Mú ìkóná, kí o fi iná sí i látorí pẹpẹ,+ kí o fi tùràrí sí i, kí o wá yára lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ torí pé Jèhófà ti bínú sí wọn gan-an. Àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀!”
47 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì mú un, bí Mósè ṣe sọ, ó sì sáré lọ sáàárín ìjọ náà, wò ó! àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lù wọ́n. Ó wá fi tùràrí sí ìkóná náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ètùtù fún àwọn èèyàn náà.
48 Ó dúró síbẹ̀, láàárín àwọn òkú àtàwọn alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì wá dáwọ́ dúró.
49 Iye àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà pa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ọgọ́rùn-ún méje (14,700), yàtọ̀ sí àwọn tó kú torí ọ̀rọ̀ Kórà.
50 Nígbà tí Áárónì fi máa pa dà sọ́dọ̀ Mósè ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àjàkálẹ̀ àrùn náà ti dáwọ́ dúró.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “máa jẹ gàba.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí gbogbo ẹran ara.”
^ Tàbí “èrò ara mi.”
^ Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “àjèjì kankan.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”