Nọ́ńbà 4:1-49

  • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì (1-20)

  • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì (21-28)

  • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Mérárì (29-33)

  • Àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (34-49)

4  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé:  “Ẹ ka àwọn ọmọ Kóhátì+ lára àwọn ọmọ Léfì, ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn,  gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30)+ ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún,+ tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+  “Èyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni:  Tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n tú aṣọ ìdábùú+ kúrò, kí wọ́n sì fi bo àpótí+ Ẹ̀rí.  Kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n na aṣọ tó jẹ́ kìkì àwọ̀ búlúù sórí rẹ̀, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́.  “Kí wọ́n tún na aṣọ aláwọ̀ búlúù bo tábìlì búrẹ́dì àfihàn,+ kí wọ́n sì kó àwọn àwo ìjẹun sórí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ife, àwọn abọ́ àti àwọn ṣágo ọrẹ ohun mímu;+ kí búrẹ́dì+ ọrẹ máa wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.  Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò sórí wọn, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́.  Kí wọ́n wá mú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n sì fi bo ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n fi ń tan iná,+ pẹ̀lú àwọn fìtílà rẹ̀, àwọn ìpaná* rẹ̀, àwọn ìkóná rẹ̀+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ tí wọ́n ń fi òróró sí láti máa fi tàn án. 10  Kí wọ́n fi awọ séálì wé e pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e. 11  Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ búlúù sórí pẹpẹ wúrà,+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e  + bọ̀ ọ́. 12  Kí wọ́n wá kó gbogbo ohun èlò+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, èyí tí wọ́n máa ń lò déédéé nínú ibi mímọ́, kí wọ́n kó o sínú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e. 13  “Kí wọ́n kó eérú* kúrò nínú pẹpẹ,+ kí wọ́n sì na aṣọ tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ pọ́pù ṣe sórí rẹ̀. 14  Kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ náà sórí rẹ̀: àwọn ìkóná, àwọn àmúga, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́, gbogbo ohun èlò pẹpẹ;+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá+ tí wọ́n á fi gbé e bọ̀ ọ́. 15  “Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti bo ibi mímọ́+ náà tán àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ náà nígbà tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra. Kí àwọn ọmọ Kóhátì wá wọlé wá gbé e,+ àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ fara kan ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú.+ Ojúṣe* àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé nìyí. 16  “Élíásárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ló ń bójú tó òróró tí wọ́n fi ń tan iná,+ tùràrí onílọ́fínńdà,+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo àti òróró àfiyanni.+ Òun ló ń bójú tó gbogbo àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, títí kan ibi mímọ́ àti àwọn ohun èlò rẹ̀.” 17  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè àti Áárónì lọ pé: 18  “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì+ pa run láàárín àwọn ọmọ Léfì. 19  Ohun tí ẹ máa ṣe fún wọn nìyí kí wọ́n lè máa wà láàyè, kí wọ́n má sì kú torí pé wọ́n sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n yan iṣẹ́ kálukú àti ohun tó máa gbé fún un. 20  Wọn ò gbọ́dọ̀ wọlé wá wo àwọn ohun mímọ́, ì báà jẹ́ fírí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú.”+ 21  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 22  “Ka àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn àti ní ìdílé-ìdílé. 23  Kí o forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 24  Iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ nìyí: 25  Kí wọ́n máa gbé aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé, ìbòrí rẹ̀ àti ìbòrí tí wọ́n fi awọ séálì ṣe tó wà lókè rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ 26  àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá+ tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nìyí. 27  Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó gbogbo iṣẹ́ àti ẹrù àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì;+ kí ẹ yan gbogbo ẹrù yìí fún wọn pé kó jẹ́ ojúṣe wọn. 28  Èyí ni iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé,+ Ítámárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ni yóò sì máa darí iṣẹ́ wọn. 29  “Ní ti àwọn ọmọ Mérárì,+ kí o forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn. 30  Kí o forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 31  Àwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé nìyí: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀, àwọn òpó+ rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + rẹ̀; 32  àwọn òpó+ àgbàlá tó yí i ká, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + wọn, àwọn èèkàn+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọn àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí. Kí ẹ fi orúkọ yan ohun tí kálúku wọn á máa gbé. 33  Bí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ á ṣe máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé nìyí, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ máa darí wọn.” 34  Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà wá forúkọ àwọn ọmọ Kóhátì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 35  gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 36  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (2,750).+ 37  Èyí ni àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 38  Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 39  gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 40  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (2,630).+ 41  Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì sílẹ̀ nìyí, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà+ ṣe pa á láṣẹ. 42  Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 43  gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 44  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé igba (3,200).+ 45  Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ nìyí, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 46  Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì forúkọ gbogbo àwọn ọmọ Léfì yìí sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn; 47  wọ́n jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo wọn ni a yàn láti máa ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì máa gbé àwọn ẹrù tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé.+ 48  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ọgọ́rin (8,580).+ 49  Wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè, ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú àti ẹrù rẹ̀; wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ibùdó.”
Tàbí “ẹ̀mú.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Ní Héb., “ibùdó.”
Ní Héb., “Ẹrù.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”